1
2
3
4Jésù dáhùn ó wí pé, “Ẹ padà lọ, ẹ sì sọ fún Jòhánù ohun tí ẹ̀yin gbọ́, àti èyí tí ẹ̀yin rí.
5
6Alábùkún fún ni ẹni tí kò rí ohun ìkọ̀sẹ̀ nípa mi.”
7Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jòhánù ti lọ tán, Jésù bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún ọ̀pọ̀ ènìyàn nípa ti Jòhánù: “Kí ni ẹ̀yin jáde lọ wò ní aginijù? Iféfé tí afẹ́fẹ́ ń mi?
8Bí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, kí ni ẹ̀yin lọ òde lọ í wò? Ọkùnrin tí a wọ̀ ni aṣọ dáradára? Rárá àwọn ti ó wọ aṣọ dáradára wà ní ààfin ọba.
9
10Èyí ni ẹni tí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé:
11Lóòótọ̀ ni mó wí fún yín, nínú àwọn tí a bí nínú obìnrin, kò sí ẹni tí ó tí í dìde tí ó ga ju Jòhánù onítẹ̀bọmi lọ, síbẹ̀ ẹni tí ó kéré jù ní ìjọba ọ̀run ni ó pọ̀ jù ú lọ.
12Láti ìgbà ọjọ́ Jòhánù onítẹ̀bọmi títí di àkókò yìí ni ìjọba ọ̀run ti di àfagbárawọ̀, àwọn alágbára ló ń fi ipá gbà á.
13Nítorí náà gbogbo òfin àti wòlíì ni ó wí tẹ́lẹ̀ kí Jòhánù kí ó tó dé.
14
15
16
17
18Nítorí Jòhánù wá kò bá a yín jẹ bẹ́ẹ̀ ni kò mu, ẹ̀yin sì wí pé, ‘Ó ní ẹ̀mí èṣù.’
19Ọmọ ènìyàn wá bá a yín jẹun, ó sì bá yin mu, wọ́n wí pé, ọ̀jẹun àti ọ̀mùtì; ọ̀rẹ́ àwọn agbowó òde àti àwọn ẹlẹ́sẹ̀, ṣùgbọ́n a dá ọgbọ́n láre nípa ìṣe rẹ̀.”
20
21Ó wí pé, “Ègbé ni fún ìwọ Kórásínì, ègbé ni fún ìwọ Bẹtisáídà! Ìbá ṣe pé a ti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu tí a se nínú yín ní Tírè àti Sídónì, àwọn ènìyàn wọn ìbá ti ronúpìwàdà tipẹ́ nínú aṣọ ọ̀fọ̀ àti eérú.
22Ṣùgbọ́n mo wí fún yín, yóò sàn fún Tírè àti Sídónì ní ọjọ́ ìdájọ́ jù fún yín.
23Àti ìwọ Kápánámù, a ó ha gbé ọ ga sókè ọ̀run?, Rárá a ó rẹ̀ ọ́ sílẹ̀ sí ipò òkú. Nítorí, ìbá ṣe pé a ti ṣe iṣẹ́ ìyanu tí a ṣe nínú rẹ ní Sódómù, òun ìbá wà títí di òní.
24Lóòótọ́ yóò sàn fún ilẹ̀ Sódómù ní ọjọ́ ìdájọ́ jù fún ìwọ lọ.”
25
26Bẹ́ẹ̀ ni, Baba, nítorí ó wù ọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀.
27
28“Ẹ wá sọ́dọ̀ mi gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣiṣẹ́ tí a sì di ẹrù wí wúwo lé lórí, èmi yóò sì fún yín ní ìsinmi.
29
30Nítorí àjàgà mi rọrùn ẹrù mi sì fúyẹ́.”