1
2Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn péjọ sọ́dọ̀ rẹ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi bọ́ sínú ọkọ̀-ojú omi, ó jókòó, gbogbo ènìyàn sì dúró létí òkun.
3Nígbà náà ni ó fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ òwe bá wọn sọ̀rọ̀, wí pé: “Àgbẹ̀ kan jáde lọ gbin irúgbìn sínú oko rẹ̀.
4Bí ó sì ti gbin irúgbìn náà, díẹ̀ bọ́ sí ẹ̀bá ọ̀nà, àwọn ẹyẹ sì wá, wọ́n sì jẹ ẹ́.
5Díẹ̀ bọ́ sórí ilẹ̀ orí àpáta, níbi ti kò sí erùpẹ̀ púpọ̀. Àwọn irúgbìn náà sì dàgbà sókè kíákíá, nítorí erùpẹ̀ kò pọ̀ lórí wọn.
6Ṣùgbọ́n nígbà tí òòrùn gòkè, oòrùn gbígbóná jó wọn, gbogbo wọ sì rọ, wọ́n kú nítorí wọn kò ni gbòǹgbò.
7Àwọn irúgbìn mìíràn bọ́ sí àárin ẹ̀gún, ẹ̀gún sì dàgbà, ó sì fún wọn pa.
8Ṣùgbọ́n díẹ̀ tó bọ́ sórí ilẹ̀ rere, ó sì so èso, òmíràn ọgọ́rọ̀ọ̀rún, òmiràn ọgọ́tọ̀ọ̀ta, òmíràn ọgbọọgbọ̀n, ni ìlọ́po èyí ó ti gbìn.
9Ẹni tí ó bá létí, kí ó gbọ́.”
10
11Ó sì da wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin ni a ti fi fún láti mọ ohun ìjìnlẹ̀ ìjọba Ọlọ́run, ṣùgbọ́n kì í ṣe fún wọn.
12
13Ìdí nì yìí tí mo fi ń fi òwe bá wọn sọ̀rọ̀:
14
15
16
17Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ọ̀pọ̀ àwọn wòlíì àti ènìyàn Ọlọ́run ti fẹ́ rí ohun tí ẹ̀yin ti rí, ki wọ́n sì gbọ́ ohun tí ẹ ti gbọ́, ṣùgbọ́n kò ṣe é ṣe fún wọn.
18
19Nigbà tí ẹnikẹ́ni bá gbọ́ ọ̀rọ̀ nípa ìjọba ọ̀run ṣùgbọ́n tí kò yé e, lẹ́yìn náà èṣù á wá, a sì gba èyí tí a fún sí ọkàn rẹ̀ kúrò. Èyí ni irúgbìn ti a fún sí ẹ̀bá ọ̀nà.
20Ẹni tí ó sì gba irúgbìn tí ó bọ́ sí ilẹ̀ orí àpáta, ni ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, lọ́gán, ó sì fi ayọ̀ gba ọ̀rọ̀ náà.
21Ṣùgbọ́n nítorí kò ní gbòǹgbò, ó wà fún ìgbà díẹ̀; nígbà tí wàhálà àti inúnibíni bá dìde nítorí ọ̀rọ̀ náà ní ojú kan náà yóò sì kọsẹ̀.
22
23Ṣùgbọ́n ẹni tí ó gba irúgbìn tí ó bọ́ sí orí ilẹ̀ rere ni ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, tí ó sì yé e; òun sì so èṣo òmíràn ọgọ́rọ̀ọ̀rùn, òmíràn ọgọ́tọ̀ọ̀ta, òmíràn ọgbọọgbọ̀n.”
24
25Ṣùgbọ́n ní òru ọjọ́ kan, nígbà tí ó sùn, ọ̀ta rẹ̀ wá sí oko náà ó sì gbin èpò sáàrin àlìkámà, ó sì bá tirẹ̀ lọ.
26Nígbà tí àlíkámà náà bẹ̀rẹ̀ sí dàgbà, tí ó sì so èso, nígbà náà ni èpò náà fi ara hàn.
27“Àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ àgbẹ̀ náà wá, wọ́n sọ fún un pé, ‘Ọ̀gá, irúgbìn rere kọ́ ni ìwọ ha gbìn sí oko rẹ nì? Báwo ni èpò ṣe wà níbẹ̀ nígbà náà?’
28“Ó sọ fún wọn pé, ‘Ọ̀tá ni ó ṣe èyí.’
29“Ó dá wọn lóhùn pé, ‘Rárá, nítorí bí ẹ̀yin bá ń tu èpò kúrò, ẹ ó tu àlìkámà dànù pẹ̀lú rẹ̀.
30Ẹ jẹ́ kí àwọn méjèèjì máa dàgbà pọ̀, títí di àsìkò ìkórè. Èmi yóò sọ fún àwọn olùkórè náà láti kọ́kọ́ ṣa àwọn èpò kúrò kí wọ́n sì dì wọ́n ní ìtí, kí a sì sun wọn, kí wọ́n sì kó àlìkámà sínú àká mi.’ ”
31
32Bí ó tilẹ̀ jẹ́ èso tí ó kéré púpọ̀ láàrin èṣo rẹ̀, ṣíbẹ̀ ó wá di ohun ọ̀gbìn tí ó tóbi jọjọ. Ó sì wá di igi tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì wá, wọ́n sì fi ẹ̀ka rẹ ṣe ìbùgbé.”
33
34
35
36Lẹ́yìn náà ó sì fi ọ̀pọ̀ ènìyàn sílẹ̀ lóde, ó wọ ilé lọ. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, wọn wí pé, “Ṣàlàyé òwe èpò inú oko fún wa”.
37Ó sì dá wọn lóhùn pé, “Ọmọ ènìyàn ni ẹni tí ó ń fúnrúgbìn rere.
38
39ọ̀tá tí ó gbin àwọn èpò sáàrin àlìkámà ni èṣù. Ìkórè ni òpin ayé, àwọn olùkórè sì ní àwọn ańgẹ́lì.
40“Gẹ́gẹ́ bí a ti kó èpò jọ, tí a sì sun ún nínú iná, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni yóò rí ní ìgbẹ̀yìn ayé.
41
42
43Nígbà náà ni àwọn olódodo yóò máa ràn bí òòrùn ní ìjọba Baba wọn. Ẹni tí ó bá létí, jẹ́ kí ó gbọ́.
44“Ìjọba ọ̀run sì dàbí ìṣúra kan tí a fi pamọ́ sínú oko. Nígbà tí ọkùnrin kan rí i ó tún fi í pamọ́. Nítorí ayọ̀ rẹ̀, ó ta gbogbo ohun ìní rẹ̀, ó ra oko náà.
45“Bákan náà ni ìjọba ọ̀run dàbí oníṣòwò kan tí ó ń wá òkúta olówó iyebíye láti rà.
46Nígbà tí ó rí ọ̀kan tí ó ni iye lórí, ó lọ láti ta gbogbo ohun ìní rẹ̀ láti le rà á.
47
48Nígbà tí àwọ̀n náà sì kún, àwọn apẹja fà á sókè sí etí bèbè òkun, wọ́n jókòó, wọ́n sì ṣa àwọn èyí tí ó dára sínú apẹ̀rẹ̀, ṣùgbọ́n wọ́n da àwọn tí kò dára nù.
49Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni yóò rí ní ìgbẹ̀yìn ayé. Àwọn ańgẹ́lì yóò wá láti ya àwọn ènìyàn búburú kúrò lára àwọn olódodo,
50Wọn ó sì ju àwọn ènìyàn búburú sínú iná ìléru náà, ní ibi ti ẹkún àti ìpayínkeke yóò gbé wà.”
51Jésù bí wọn léèrè pé, “Ǹjẹ́ gbogbo nǹkan wọ̀nyí yé yín.”
52Ó wí fún wọn pé, “Nítorí náà ni olúkúlùkù olùkọ́ òfin tí a ti kọ́ nípa ìjọba ọ̀run ṣe dàbí ọkùnrin kan tí í ṣe baálé ilé, tí ó mú ìṣúra tuntun àti èyí tí ó ti gbó jáde láti inú yàrá ìṣúra rẹ̀.”
53
54
55Kì í há ṣe ọmọ gbẹ́nàgbẹ́nà ni èyí bí? Ìyá rẹ̀ há kọ́ ni à ń pè ní Màríà bí? Arákùnrin rẹ̀ ha kọ́ ni Jémísì, Jósẹ́fù, Símonì àti Júdásì bí?
56Àwọn arábìnrin rẹ̀ gbogbo ha kọ́ ni ó ń bá wa gbé níhìn-ín yìí, nígbà náà níbo ni ọkùnrin yìí ti rí àwọn nǹkan wọ̀nyí?”
57Inú bí wọn sí i.
58Nítorí náà kò se iṣẹ́ ìyanu kankan níbẹ̀, nítorí àìnígbàgbọ́ wọn.