1
2wọn béèrè pé, “Èé se tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ fi ń ṣe àìgbọ́ràn sí àwọn àṣà àtayébáyé Júù? Nítorí tí wọn kò wẹ ọwọ́ wọn kí wọ́n tó jẹun!”
3Jésù sì dá wọn lóhùn pé, “È é ha ṣe tí ẹ̀yin fi rú òfin Ọlọ́run, nítorí àṣà yín?
4
5Ṣùgbọ́n ẹ̀yin wí pé, ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá wí fún baba tàbí ìyá rẹ̀ pé, “Ẹ̀bun fún Ọlọ́run i ohunkóhun tí ìwọ ìbá fi jèrè lára mi;”
6tí Òun kò sì bọ̀wọ̀ fún baba tàbí ìyá rẹ̀,’ ó bọ́; bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin sọ ofin di asan nípa àṣà yín.
7Ẹ̀yin àgàbàgebè, ní òtítọ́ ni Wòlíì Àìsáyà sọ tẹ́lẹ̀ nípa yín wí pé:
8
9
10Jésù pe ọ̀pọ̀ ènìyàn wá sí ọ̀dọ̀ rẹ, ó wí pé, “Ẹ tẹ́tí, ẹ sì jẹ́ kí nǹkan tí mo sọ yé yín.
11
12Nígbà náà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, wọ́n wí fún un pé, “Ǹjẹ́ ìwọ mọ̀ pé inú bí àwọn Farisí lẹ́yìn tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ tí ó sọ?” yìí
13
14
15Pétérù wí, “Ṣe àlàyé òwe yìí fún wa.”
16Jésù béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Èé ha ṣe tí ìwọ fi jẹ́ aláìmòye síbẹ̀”?
17“Ìwọ kò mọ̀ pé ohunkóhun tí ó gba ẹnu wọlé, yóò gba ti ọ̀nà oúnjẹ lọ, a yóò sì yà á jáde?
18Ṣùgbọ́n ohun tí a ń sọ jáde láti ẹnu, inú ọkàn ni ó ti ń wá, èyí sì ni ó ń sọ ènìyàn di ‘aláìmọ́.’
19
20Àwọn tí a dárúkọ wọ̀nyí ni ó ń sọ ènìyàn di ‘aláìmọ́.’ Ṣùgbọ́n láti jẹun láì wẹ ọwọ́, kò lè sọ ènìyàn di ‘aláìmọ́.’ ”
21
22Obìnrin kan láti Kénánì, tí ó ń gbé ibẹ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Ó ń bẹ̀bẹ̀, ó sì kígbe pé, “Olúwa, ọmọ Dáfídì, ṣàánú fún mi; ọmọbìnrin mi ní ẹ̀mí èṣù ti ń dá a lóró gidigidi.”
23Ṣùgbọ́n Jésù kò fún un ní ìdáhùn, Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì gbà á nìyànjú pé, “lé obìnrin náà lọ, nítorí ó ń kígbe tọ̀ wá lẹ́yìn.”
24
25
26Ó sì dáhùn wí pé, “Kò tọ́ kí a gbé oúnjẹ àwọn ọmọ fún àwọn ajá.”
27Obìnrin náà sì wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, síbẹ̀síbẹ̀ àwọn ajá a máa jẹ èérún tí ó ti orí tábìlì olówó wọn bọ́ sílẹ̀.”
28
29
30Ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn sì tọ̀ ọ́ wá, àti àwọn arọ, afọ́jú, amúkùn-ún, odi àti ọ̀pọ̀ àwọn aláìsàn mìíràn. Wọ́n gbé wọn kalẹ̀ lẹ́sẹ̀ Jésù. Òun sì mú gbogbo wọn lárada.
31Ẹnú ya ọ̀pọ̀ ènìyàn nígbà tí wọ́n rí àwọn odi tó ń sọ̀rọ̀, amúkùn-ún tó di alára pípé, arọ tí ó ń rìn àti àwọn afọ́jú tí ó ríran. Wọ́n sì ń fi ìyìn fún Ọlọ́run Ísírẹ́lì.
32
33Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sì dá a lóhùn pé, “Níbo ni àwa yóò ti rí oúnjẹ ní ihà níhìn-ín yìí láti fi bọ́ ọ̀pọ̀ ènìyàn yìí?”
34Jésù sì béèrè pé, “ìsù Búrẹ́dì mélòó ni ẹ̀yín ní?”
35Jésù sì sọ fún gbogbo ènìyàn kí wọn jókòó lórí ilẹ̀.
36Òun sì mú ìsù àkàrà méje náà àti ẹja náà. Ó sì fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run, ó bù wọ́n sì wẹ́wẹ́, ó sì fi wọ́n fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. Wọ́n sì pín in fún àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn náà.
37Gbogbo wọn jẹ, wọ́n sì yó. Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sì sa èyí tókù, ẹ̀kún agbọ̀n méje ni èyí tó sẹ́kù jẹ́
38Gbogbo wọn sì jẹ́ ẹgbàají: (4000) ọkùnrin láì kan àwọn obìnrin àti ọmọdé.
39Lẹ́yìn náà, Jésù rán àwọn ènìyàn náà lọ sí ilé wọn, ó sì bọ́ sínú ọkọ̀, ó ré kọjá sí Mágádánì.