1
2Jésù sì pe ọmọ kékeré kan sí ọ̀dọ̀ ara rẹ̀. Ó sì mú un dúró láàrin wọn.
3
4Nítorí náà, ẹni tí ó bá rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọmọdé yìí, ni yóò pọ̀ jùlọ ní ìjọba ọ̀run.
5
6
7“Ègbé ni fún ayé nítorí gbogbo ohun ìkọ̀sẹ̀ rẹ̀! Ohun ìkọ̀sẹ̀ kò le ṣe kó má wà, ṣùgbọ́n ègbé ni fún ọkùnrin náà nípaṣẹ̀ ẹni tí ìkọ̀sẹ̀ náà ti wá!
8
9Bí ojú rẹ yóò bá sì mú kí o dẹ́sẹ̀, yọ ọ́ kúrò kí ó sì sọ ọ́ nù. Ó kúkú sàn fún ọ láti wọ ìjọba ọ̀run pẹ̀lú ojú kan, ju pé kí o ní ojú méjì, kí a sì jù ọ́ sí iná ọ̀run àpádì.
10
11Nítorí náà, Ọmọ ènìyàn wá láti gba àwọn tí ó nù là.
12
13Ǹjẹ́ bí òun bá sì wá á rí i, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ǹjẹ́ ẹ̀yin kò mọ̀ pé inú rẹ̀ yóò dùn nítorí rẹ̀ ju àwọn mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún tí kò nù lọ?
14Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ni kì í ṣe ìfẹ́ Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run, pé ọ̀kan nínú àwọn kékeré wọ̀nyí kí ó ṣègbé.
15
16Ṣùgbọ́n bí òun kò bá tẹ́tí sí ọ, nígbà náà mú ẹnìkan tàbí ẹni méjì pẹ̀lú rẹ, kí ẹ sì tún padà sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i, kí ọ̀rọ̀ náà bá le fi ìdí múlẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́rìí méjì tàbí mẹ́ta náà.
17Bí òun bá sì tún kọ̀ láti tẹ́tí sí wọn, nígbà náà sọ fún ìjọ ènìyàn Ọlọ́run. Bí o bá kọ̀ láti gbọ́ ti ìjọ ènìyàn Ọlọ́run, jẹ́ kí ó dàbí kèfèrí sí ọ tàbí agbowó-òde.
18
19
20Nítorí níbi ti ènìyàn méjì tàbí mẹ́ta bá kó ara jọ ni orúkọ mi, èmi yóò wà láàrin wọn níbẹ̀.”
21
22Jésù dáhùn pé, “Mo wí fún ọ, kì í se ìgbà méje, ṣùgbọ́n ní ìgbà àádọ́rin méje;
23
24Bí ó ti ń ṣe èyí, a mú ajigbésè kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀ tí ó jẹ ẹ́ ní ẹgbàáárún (10,000) talẹ́ńtì.
25
26
27Nígbà náà, ni olúwa ọmọ-ọ̀dọ̀ náà sì ṣàánú fún un. Ó tú u sílẹ̀, ó sì fi gbésè náà jì í.
28“Ṣùgbọ́n bí ọmọ-ọ̀dọ̀ náà ti jáde lọ, ó rí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ ẹgbẹ́ rẹ̀ tí ó jẹ ẹ́ ní ọgọ́rùn-ún dínárì, ó gbé ọwọ́ lé e, ó fún un ní ọrùn, ó wí pé ‘san gbéṣè tí o jẹ mí lójú ẹṣẹ̀.’
29“Arákùnrin náà sì wólẹ̀ lórí eékún níwájú rẹ̀, ò ń bẹ̀ ẹ́ pé, ‘Mú sùúrù fún mi, èmi yóò sì san án fún ọ.’
30“Ṣùgbọ́n òun kọ̀ fún un. Ó pàṣẹ kí a mú ọkùnrin náà, kí a sì jù ú sínú túbú títí tí yóò fi san gbésè náà tán pátápátá.
31Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ ẹlẹ́gbẹ́ rẹ̀ rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, inú bí wọn gidigidi, wọ́n lọ láti lọ sọ fún olúwa wọn, gbogbo ohun tí ó sẹlẹ̀.
32“Nígbà tí olúwa rẹ̀ pè Ọmọ-ọ̀dọ̀ náà wọlé, ó wí fún un pé, ‘Ìwọ Ọmọ-ọ̀dọ̀ búburú, níhìn-ín ni mo ti dárí gbogbo gbésè rẹ jì ọ́ nítorí tí ìwọ bẹ̀ mi;.
33Kò ha ṣe ẹ̀tọ́ fún ọ láti ṣàánú fún àwọn ẹlòmíràn, gẹ́gẹ́ bí èmi náà ti ṣáànú fún ọ?’
34Ní ibínú, olówó rẹ̀ fi í lé àwọn onítúbú lọ́wọ́ láti fi ìyà jẹ ẹ́, títí tí yóò fi san gbogbo gbésè èyí ti ó jẹ ẹ́.
35