1
2
3Nígbà tí ọba Hẹ́rọ́dù sì gbọ́ èyí, ìdáàmú bá a àti gbogbo àwọn ara Jerúsálémù pẹ̀lú rẹ̀
4Nígbà tí ó sì pe àwọn olórí àlùfàá àti àwọn olùkọ́ òfin jọ, ó bi wọ́n léèrè níbi ti a ó gbé bí Kírísítì?
5
6
7Nígbà náà ni Hérọ́dù ọba pe àwọn amòye náà sí ìkọ̀kọ̀, ó sì wádìí ni ọwọ́ wọn, àkókò náà gan-an tí wọ́n kọ́kọ́ rí ìràwọ̀.
8Ó sì rán wọn lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, ó sì wí pé, “Ẹ lọ ṣe ìwádìí fínnífínní ní ti ọmọ náà tí a bí. Lẹ́yìn tí ẹ bá sì rí i, ẹ padà wá sọ fún mi, kí èmi náà le lọ foríbalẹ̀ fún un.”
9Nígbà tí wọ́n sì gbọ́ ọ̀rọ̀ ọba, wọ́n mú ọ̀nà wọn pọ̀n, sì wò ó, ìràwọ̀ tí wọ́n ti rí láti ìhà ìlà-oòrùn wá, ó ṣáájú wọn, títítí ó fi dúró lókè ibi tí ọmọ náà gbé wà.
10Nígbà tí wọ́n sì rí ìràwọ̀ náà, ayọ̀ kún ọkàn wọn.
11
12
13Nígbà tí wọn ti lọ, ańgẹ́lì Olúwa fara hàn Jósẹ́fù ní ojú àlá pé, “Dìde, gbé ọmọ-ọwọ́ náà àti ìyá rẹ̀, kí ó sì sá lọ sí Éjíbítì. Dúró níbẹ̀ títítí èmi yóò fi sọ fún ọ, nítorí Hẹ́rọ̀dù yóò wá ọ̀nà láti pa ọmọ-ọwọ́ náà.”
14Nígbà náà ni ó sì dìde, ó mú ọmọ-ọwọ́ náà àti ìyá rẹ̀ ní òru, ó sì lọ sí Éjíbítì,
15
16Nígbà tí Hẹ́rọ̀dù rí í pé àwọn amòye náà ti tan òun jẹ, ó bínú gidigidi, ó sì pàṣẹ kí a pa gbogbo àwọn ọmọkùnrin tí ó wà ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù àti ní ẹkùn rẹ̀ láti àwọn ọmọ ọdún méjì sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bi àkókò tí ó ti fi ẹ̀sọ̀ ẹ̀sọ̀ béèrè lọ́wọ́ àwọn amòye náà.
17Nígbà náà ni èyí tí a ti sọ tẹ́lẹ̀ láti ẹnu wòlíì Jeriemáyà wá sẹ pé:
18
19
20Ó sì wí fún un pé, “Dìde gbé ọmọ-ọwọ́ náà àti ìyá rẹ̀ padà sí ilẹ̀ Ísírẹ́lì, nítorí àwọn tí ń wá ọmọ-ọwọ́ náà láti pa ti kú.”
21Nítorí náà, Ó sì dìde, ó gbé ọmọ-ọwọ́ náà àti ìyá rẹ̀ ó sì wá sí ilẹ̀ Ísírẹ́lì.
22Ṣùgbọ́n nígbà tí ó gbọ́ pé Ákílọ́sì ni ó ń jọba ní Jùdíà ní ipò Hẹ́rọ́dù baba rẹ̀, ó bẹ̀rù láti lọ sí ì bẹ̀. Nítorí tí Ọlọ́run ti kìlọ̀ fún un ní ojú àlá, ó yí padà, ó sì gba ẹkùn Gálílì lọ,
23