1
2Òun pinnu láti san dínárì kan fún iṣẹ́ òòjọ́ kan. Lẹ́yìn èyí ó sì rán wọn lọ sínú ọgbà àjàrà rẹ̀.
3“Ní wákàtí kẹta ọjọ́ bí ó ti ń kọjá níwájú ilé ìgbanisíṣẹ́, ó rí díẹ̀ nínú àwọn aláìríṣẹ́ tí wọ́n dúró ní ọjà.
4Ó wí fún wọn pé, ‘Ẹ̀yin pàápàá, ẹ lọ ṣiṣẹ́ nínú ọgbà àjàrà mi, bí ó bá sì di òpin ọjọ́, èmi yóò san iye ti ó bá yẹ fún yín.’
5Wọ́n sì lọ
6Lọ́jọ́ kan náà ní wákàtí kọkànlá ọjọ́, ó tún jáde sí àárin ìlú, ó sì rí àwọn aláìríṣẹ́ mìíràn tí wọ́n dúró. Ó bi wọ́n pé, ‘È é ṣe tí ẹ̀yin kì í ṣiṣẹ́ ní gbogbo ọjọ́?’
7“Wọ́n sì dáhùn pé, ‘Nítorí pé kò sí ẹni tí yóò fún wa ní iṣẹ́ ṣe.’ Ó tún sọ fún wọn pé, ‘Ẹ̀yin náà ẹ jáde lọ ṣiṣẹ́ pẹ̀lú nínú ọgbà àjàrà mi.’
8
9“Nígbà tí àwọn ti a pè ní wákàtí kọkànlá ọjọ́ dé, ẹnì kọ̀ọ̀kan gba owó dínárì kan.
10Nígbà tí àwọn tí a gbà ṣíṣẹ́ lákọ̀ọ́kọ́ fẹ́ gba owó ti wọn, èrò wọn ni pé àwọn yóò gba jù bẹ́ẹ̀ lọ, ṣùgbọ́n ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn gba owó dínárì kan.
11Bí wọ́n ti ń gbà á, wọ́n ń kùn sí onílẹ̀ náà,
12Pé, ‘Wákàtí kan péré ni àwọn tí a gbà kẹ́yìn fi ṣiṣẹ́, ìwọ sì san iye kan náà fún wọn àti àwa náà ti a fi gbogbo ọjọ́ ṣiṣẹ́ nínú oòrùn gan-gan.’
13
14Ó ní, Gba èyí tíí ṣé tìrẹ, ki ó sì máa lọ. Èmi fẹ́ láti fún ẹni ìkẹ̀yìn gẹ́gẹ́ bí mo ti fi fún ọ.
15
16
17
18“Wò ó, àwa ń gòkè lọ sí Jérúsálẹ́mù. Ó sọ fún wọn pé, a ó fi Ọmọ Ènìyàn lé àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin lọ́wọ́, wọn yóò sì dá mi lẹ́bi ikú.
19Wọn yóò sì lé àwọn kèfèrí lọ́wọ́ láti fi ṣe ẹlẹ́yà àti láti nàa án, àti láti kàn mi mọ́ àgbélébùú, ní ọjọ́ kẹta, yóò jí dìde.”
20
21
22
23
24Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mẹ́wàà ìyókù sì gbọ́ èyí, wọ́n bínú sí àwọn arákùnrin méjì yìí.
25
26
27Àti ẹni tí ó bá fẹ́ ṣe olórí nínú yín, ẹ jẹ́ kí ó máa ṣe Ọmọ-ọ̀dọ̀ yin.
28
29
30Àwọn ọkùnrin afọ́jú méjì sì jókòó lẹ́bàá ọ̀nà, nígbà tí wọ́n sí gbọ́ pé Jésù ń kọjá lọ, wọ́n bẹ̀rẹ̀ síí kígbe pé, “Olúwa, Ọmọ Dáfídì, ṣàánú fún wa!”
31Àwọn ènìyàn sí bá wọn wí pé kí wọn dákẹ́, ṣùgbọ́n wọ́n kígbe sóke sí i. “Olúwa, ọmọ Dáfídì, ṣàánú fún wa!”
32Jésù dúró lójú ọ̀nà, ó sì pè wọ́n pé, Ó béèrè pé, “Kí ni ẹ̀yin fẹ́ kí èmi ṣe fún yín?”
33Wọ́n dáhùn pé, “Olúwa, àwa fẹ́ kí a ríran.”
34Àánú wọn sì ṣe Jésù, ó fi ọwọ́ kan ojú wọn. Lójú kan náà, wọ́n sì ríran, wọ́n sì ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.