1
2“Ìjọba ọ̀run dàbí ọba kan ti ó múra àṣè ìgbéyàwó ńlá fún ọmọ rẹ̀ ọkùnrin.
3
4“Lẹ́yìn náà ó tún rán àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ mìíràn pé, ‘Ẹ sọ fún àwọn tí mo ti pè wí pé, mo ti se àsè náà tán. A pa màlúù àti ẹran àbọ́pa mi, a ti ṣe ohun gbogbo tán, ẹ wa sí ibi àsè ìgbéyáwó.’
5“Ṣùgbọ́n àwọn wọ̀n-ọn-nì tí ó ránṣẹ́ lọ pè kò kán á si. Wọ́n ń bá iṣẹ́ wọn lọ, ọ̀kan sí ọ̀nà oko rẹ̀, òmíràn sí ibi òwò rẹ̀.”
6Àwọn ìyókù sì lu àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n ta àbùkù fún wọn, wọ́n lù wọ́n pa.
7Ọba yìí bínú gidigidi, ó sì rán àwọn ọmọ-ogun rẹ̀, ó sì pa àwọn apànìyàn náà run, ó sì jó ìlú wọn
8“Nígbà náà ni ó wí fún àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé, ‘Àsè ìgbéyàwó ti ṣe tàn, ṣùgbọ́n àwọn tí a pè kò yẹ fún ọlá náà.
9Ẹ lọ sí ìgboro àti òpópónà kí ẹ sì pe ẹnikẹ́ni tí ẹ bá lè rí wá àsè ìgbéyàwó náà.’
10
11“Ṣùgbọ́n nígbà tí ọba sì wọlé wá láti wo àwọn àlejò tí a pè, ó sì rí ọkùnrin kan nínú wọn tí kò wọ àṣọ ìgbéyàwó.
12
13
14“Nítorí ọ̀pọ̀ ni a pè ṣùgbọ́n díẹ̀ ni a yàn.”
15
16Wọ́n sì rán àwọn ọmọ-ẹ̀yìn wọn pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Hérọ́dù lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Olùkọ́, àwa mọ̀ pé olótìítọ́ ni ìwọ, ìwọ sì ń kọ́ni ní ọ̀nà Ọlọ́run ní òtítọ́. Bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kì í wo ojú ẹnikẹ́ni; nítorí tí ìwọ kì í ṣe ojúsàájú ènìyàn.
17Nísinsìn yìí sọ fún wa, kí ni èrò rẹ? Ǹjẹ́ ó tọ́ láti san owó-orí fún Késárì tàbí kò tọ́?”
18Ṣùgbọ́n Jésù ti mọ èrò búburú inú wọn, ó wí pé, “Ẹ̀yin àgàbàgebè, è é se ti ẹ̀yin fi ń dán mi wò?
19Ẹ fi owo ẹyọ tí a fi ń san owo-orí kan hàn mi.” Wọn mú dínárì kan wá fún un,
20ó sì bi wọ́n pé, “Àwòrán tabi èyí? Àkọlé tà sì ní?”
21
22Nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí, ẹnú yà wọ́n. Wọ́n fi í sílẹ̀, wọ́n sì bá tiwọn lọ.
23
24
25Bí ó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, láàrin wa níhìn-in yìí, ìdílé kan wà tí ó ní arákùnrin méje. Èyí èkínní nínú wọn gbéyàwó, lẹ́yìn náà ó kú láìlọ́mọ. Nítorí náà ìyàwó rẹ̀ di ìyàwó arákùnrin kejì.
26Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ arákùnrin èkejì náà sì tún kú láìlọ́mọ. A sì fi ìyàwó rẹ̀ fún arákùnrin tí ó tún tẹ̀lé e. Bẹ́ẹ̀ sì ni títítí òun fi di ìyàwó ẹnì kéje.
27Níkẹyìn obìnrin náà pàápàá sì kú.
28Nítorí tí ó ti ṣe ìyàwó àwọn arákùnrin méjèèje, ìyàwó ta ni yóò jẹ́ ní àjíǹde òkú?”
29Ṣùgbọ́n Jésù dá wọn lóhùn pé, “Àìmọ̀kan yín ni ó fa irú ìbéèrè báyìí. Nítorí ẹ̀yin kò mọ ìwé Mímọ́ àti agbára Ọlọ́run.
30Nítorí ní àjíǹde kò ní sí ìgbéyàwó, a kò sì ní fi í fún ni ní ìyàwó. Gbogbo ènìyàn yóò sì dàbí àwọn ańgẹ́lì ní ọ̀run.
31Ṣùgbọ́n nísinsìn yìí, nípa ti àjíǹde òkú, tàbí ẹ̀yin kò mọ̀ pé Ọlọ́run ń bá yín sọ̀rọ̀ nígbà ti ó wí pé:
32
33
34
35
36Ó wí pé, “Olùkọ́ èwo ni ó ga jùlọ nínú àwọn òfin?”
37
38Èyí ni òfin àkọ́kọ́ àti èyí tí ó tóbi jùlọ.
39
40Lórí àwọn òfin méjèèjì yìí ni gbogbo òfin àti àwọn wòlíì rọ̀ mọ́.”
41
42“Kí ni ẹ rò nípa Kírísítì? Ọmọ ta ni òun ń ṣe?”
43Ó sì wí fún wọn pé, “Kí ni dé tí Dáfídì, tí ẹ̀mí ń darí, pè é ní ‘Olúwa’? Nítorí ó wí pé,
44
45Ǹjẹ́ bí Dáfídì bá pè é ni ‘Olúwa,’ báwo ni òun se lè jẹ́ ọmọ rẹ̀?”
46