1
2
3Ní àsìkò tí Jésù ń sọ̀rọ̀ yìí, àwọn olórí àlùfàá àti àwọn àgbààgbà kó ara wọn jọ ní ààfin olórí àlùfàá náà tí à ń pè ní Káíáfà.
4Láti gbèrò àwọn ọ̀nà tí wọ́n yóò fi mú Jésù pẹ̀lú ẹ̀tàn, kí wọn sì pa á.
5Ṣùgbọ́n wọ́n fohùn ṣọ̀kan pé, “Kì í ṣe lásìkò àsè àjọ ìrékọjá, nítorí rògbòdìyàn yóò ṣẹlẹ̀.”
6
7Bí ó ti ń jẹun, obìnrin kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú ìgò òróró ìkunra iyebíye, ó sì dà á sí i lórí.
8Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yin rí i, inú bí wọn. Wọ́n wí pé, “Irú ìfowóṣòfò wo ni èyí?
9È é ha ti ṣe, obìnrin yìí ìbá tà á ní owó púpọ̀, kí a sì fi owó náà fún àwọn aláìní.”
10Jésù ti mọ èrò ọkàn wọn, ó wí pé, “È é ṣe ti ẹ̀yin fi ń dá obìnrin yìí lẹ́bi? Ó ṣe ohun tí ó dára fún mi
11
12
13Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, a ó sì máa ṣe ìrántí rẹ̀ nígbà gbogbo fún ìṣesí rẹ̀ yìí. Níbikíbi tí a bá ti wàásù ìyìn rere yìí ní gbogbo àgbáyé ni a ó ti sọ ìtàn ohun tí obìnrin yìí ṣe.”
14
15
16Láti ìgbà náà lọ ni Júdásì ti bẹ̀rẹ̀ sí i wá ọ̀nà láti fà á lé wọn lọ́wọ́.
17
18
19
20
21nígbà tí wọ́n sì ń jẹun, ó wí pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ọ̀kan nínú yín yóò fi mí hàn.”
22Ìbànújẹ́ sì bo ọkàn wọn nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí i bi í pé, “Olúwa, èmi ni bí?”
23Jésù dáhùn pé, “Ẹni ti ó bá mi tọwọ́ bọ inú àwo, ni yóò fi mi hàn.
24
25Júdásì, ẹni tí ó fi í hàn pẹ̀lú béèrè pé, “Ráábì, èmi ni bí?”
26
27Bákan náà, ó sì mú aago wáìnì, ó dúpẹ́ fún un, ó sí fún wọn. Ó wí pé, “Kí gbogbo yín mu nínú rẹ̀.
28
29Sì kíyèsí àwọn ọ̀rọ̀ mi. Èmi kì yóò tún mu nínú ọtí wáìnì yìí mọ́ títí di ọjọ́ náà tí èmi yóò mu ún ní titun pẹ̀lú yín ní ìjọba Baba mi.”
30
31
32
33Pétérù sì dá a lóhùn pé, “Bí gbogbo ènìyàn tilẹ̀ kọ̀ ọ́ sílẹ̀, èmi kì yóò ṣe bẹ́ẹ̀.”
34Jésù wí fún un pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún ọ pé, ní òru yìí, kí àkùkọ kí ó tó kọ, ìwọ yóò sẹ́ mi nígbà mẹ́ta.”
35Pétérù wí fún un pé, “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ láti kú pẹ̀lú, èmi kò jẹ́ sẹ́ ọ.” Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni gbogbo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn wí.
36
37Ó sì mú Pétérù àti àwọn ọmọ Sébédè méjèèjì Jákọ́bù àti Jòhánù pẹ̀lú rẹ̀, ìrora àti ìbànújẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí i gba ọkà rẹ̀.
38
39
40Bí ó ti padà sọ́dọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, ó bá wọn, wọ́n ń sùn. Ó kígbe pé, “Pétérù, ẹ̀yin kò tilẹ̀ lè bá mi ṣọ́nà fún wákàtí kan?
41Ẹ kún fún ìṣọ́ra, kí ẹ sì máa gbàdúrà kí ẹ̀yin má ba à bọ́ sínú ìdẹ́wò. Nítorí Ẹ̀mi ń fẹ́ nítòótọ́, ṣùgbọ́n ó ṣe àìlera fún ara.”
42
43Nígbà tí ó tún padà dé sọ́dọ̀ wọn, Ó rí i pé wọn ń sùn, nítorí ojú wọn kún fún oorun.
44Nítorí náà, ó fi wọn sílẹ̀ ó tún padà lọ láti gbàdúrà nígbà kẹta, ó ń wí ohun kan náà.
45
46Ẹ dìde! Ẹ jẹ́ kí a máa lọ! Ẹ wò ó, ẹni tí yóò fi mi hàn ń bọ̀ wá!”
47
48Ẹni tí ó sì fi í hàn ti fi àmì fún wọn, pé, “Ẹnikẹ́ni tí mo bá fi ẹnu kò ní ẹnu, òun náà ni; ẹ mú un.”
49Nísinsìn yìí, Júdásì wá tààrà sọ́dọ̀ Jésù, ó wí pé, “Àlàáfíà, Ráábì” ó fi ẹnu kò ó ní ẹnu.
50
51Sì wò ó, ọ̀kan nínú àwọn tí ó wà pẹ̀lú Jésù na ọwọ́ rẹ̀, ó sì fa idà yọ, ó sì ṣá ọ̀kan tí i ṣe ọmọ-ọ̀dọ̀ olórí àlùfáà, ó sì gé e ní etí sọnù.
52
53Ìwọ kò mọ̀ pé èmi lè béèrè lọ́wọ́ Baba mi kí ó fún mi ju légíónì (6,000) ańgẹ́lì méjìlá? Òun yóò sì fi wọ́n ránṣẹ́ lẹsẹ̀kẹsẹ̀.
54Ṣùgbọ́n bí mo bá ṣe eléyìí ọ̀nà wo ni a ó fi mú ìwé Mímọ́ ṣẹ, èyí tí ó ti sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ nísinsìn yìí?”
55
56Ṣùgbọ́n gbogbo wọ̀nyí ń ṣẹlẹ̀ kí ọ̀rọ̀ tí a tì ẹnu àwọn wòlíì sọ, tí a kọ sínú ìwé Mímọ́ lè ṣẹ.” Nígbà yìí gan-an ni gbogbo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ti sá kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì sá lọ.
57
58Ṣùgbọ́n Pétérù ń tẹ̀lé e lókèèrè. Òun sì wá sí àgbàlá olórí àlùfáà. Ó wọlé, ó sì jókòó pẹ̀lú àwọn olùṣọ́. Ó ń dúró láti ri ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí Jésù.
59Nígbà náà ni àwọn olórí àlùfáà àti gbogbo ìgbìmọ̀ Júù ní ilé-ẹjọ́ tí ó ga jùlọ ti Júù pé jọ síbẹ̀, wọ́n wá àwọn ẹlẹ́rìí tí yóò purọ́ mọ́ Jésù, kí a ba à lè rí ẹjọ́ rò mọ́ ọn lẹ́sẹ̀, eléyìí tí yóò yọrí si ìdájọ́ ikú fún un.
60Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹlẹ́rìí èké dìde, ṣùgbọ́n wọn kò rí ohun kan.
61
62Nígbà náà ni olórí àlùfáà sì dìde, ó wí fún Jésù pé, “Ẹ̀rí yìí ńkọ́? Ìwọ sọ bẹ́ẹ̀ tàbí ìwọ kò sọ bẹ́ẹ̀?”
63
64
65
66Ki ni ẹ ti rò èyí sí.
67Wọ́n tu itọ́ sí i ní ojú. Wọ́n gbá a lẹ́sẹ̀ẹ́. Àwọn ẹlòmíràn sì gbá a lójú.
68Wọ́n wí pé, “Sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún wa! Ìwọ Kírísítì, Ta ni ẹni tí ó ń lù Ọ́?”
69Lákòókò yìí, bí Pétérù ti ń jókòó ní ọgbà ìgbẹ́jọ́, ọmọbìnrin kan sì tọ̀ ọ́ wá, ó ní, “Ìwọ wà pẹ̀lú Jésù ti Gálílì.”
70Ṣùgbọ́n Pétérù ṣẹ̀ ní ojú gbogbo wọn pé “Èmi kò tilẹ̀ mọ ohun tí ẹ ń sọ nípa rẹ̀.”
71Lẹ́yìn èyí, ní ìta lẹ́nu ọ̀nà, ọmọbìnrin mìíràn tún rí i, ó sì wí fún àwọn tí ó dúró yíká pé, “Ọkùnrin yìí wà pẹ̀lú Jésù ti Násárẹ́tì.”
72Pétérù sì tún ṣẹ́ lẹ́ẹ̀kejì pẹ̀lú ìbúra pé, “Èmi kò tilẹ̀ mọ ọkùnrin náà rárá.”
73Nígbà tí ó pẹ́ díẹ̀, àwọn ọkùnrin tí ó ń dúró níbi ìran yìí tọ̀ ọ́ wá, wọ́n wí pé, “Lóòótọ́, ìwọ jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn, àwa mọ̀ ọ́. Èyí sì dá wa lójú nípa àmì ohùn rẹ̀ tí ó ń ti ẹnu rẹ jáde.”
74Pétérù sì tún bẹ̀rẹ̀ sí íbúra ó sì fi ara rẹ̀ ré wí pé, “Mo ní èmi kò mọ ọkùnrin yìí rárá.”
75