1
2Lẹ́yìn èyí, wọ́n fi ẹ̀wọ̀n dè é, wọ́n sì jọ̀wọ́ rẹ̀ fún Pílátù tí i ṣe gómìnà.
3
4Ó wí pé, “Mo ti ṣẹ̀ nítorí tí mo ti ta ẹ̀jẹ̀ aláìlẹ́ṣẹ̀ sílẹ̀.”
5Nígbà náà ni Júdásì da owó náà sílẹ̀ nínú tẹ̀ḿpìlì. Ó jáde, ó sì lọ pokùnṣo.
6
7Nítorí náà wọ́n pínnú, láti fi owó náà ra ilẹ̀ kan, níbi tí àwọn amọ̀kòkò ti ń rí amọ̀ wọn, àti láti lo ilẹ̀ náà fún ìsìnkú fún àwọn àlejò tí ó bá kú ní Jerúsálémù.
8Ìdí nìyìí tí à ń pe ibi ìsìnkú náà ní “Ìlẹ̀ Ẹ̀jẹ̀” títí di òní.
9
10Wọ́n sì fi ra ilẹ̀ kan lọ́wọ́ àwọn amọ̀kòkò gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa á láṣẹ.”
11
12Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn olórí àlùfàà àti àwọn àgbààgbà Júù fi gbogbo ẹ̀sùn wọn kàn án, Jésù kò dáhùn kan.
13Nígbà náà ni Pílátù, béèrè lọ́wọ́ Jésù pé, “Àbí ìwọ kò gbọ́ ẹ̀rí tí wọn ń wí nípa rẹ ni?”
14
15Ó jẹ́ àṣà Baálẹ̀ láti dá ọ̀kan nínú àwọn ẹlẹ́wọ̀n Júù sílẹ̀ lọ́dọọdún, ní àsìkò àjọ̀dún ìrékọjá. Ẹnikẹ́ni tí àwọn ènìyàn bá ti fẹ́ ni.
16Ní àsìkò náà ọ̀daràn paraku kan wà nínú ẹ̀wọ̀n tí à ń pè Bárábbà.
17Bí ọ̀pọ̀ ènìyàn ti pé jọ ṣíwájú ilé Pílátù lówúrọ̀ ọjọ́ náà, ó béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ta ni ẹ̀yin ń fẹ́ kí n dá sílẹ̀ fún yín, Bárábbà tàbí Jésù, ẹni tí ń jẹ́ Kírísítì?”
18Òun ti mọ̀ pé nítorí ìlara ni wọn fi fà á lé òun lọ́wọ́,;
19
20Ṣùgbọ́n àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbààgbà Júù rọ àwọn ènìyàn, láti béèrè kí a dá Bárábà sílẹ̀, kí a sì béèrè ikú fún Jésù.
21
22Pílátù béèrè pé, “Kí ni kí èmi ṣe sí Jésù ẹni ti a ń pè ní Kírísítì?”
23Pílátù sì béèrè pé, “Nítorí kí ni? Kí ló ṣe tí ó burú?”
24
25
26Nígbà náà ni Pílátù dá Bárábà sílẹ̀ fún wọn. Lẹ́yìn tí òun ti na Jésù tán, ó fi í lé wọn lọ́wọ́ láti mú un lọ kàn mọ́ àgbélébùú.
27
28Wọ́n tú Jésù sì ìhòòhò, wọ́n sì wọ̀ ọ́ láṣọ òdòdó,
29Wọ́n sì hun adé ẹ̀gún. Wọ́n sì fi dé e lórí. Wọ́n sì fi ọ̀pá sí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀pá ọba. Wọ́n sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀, wọ́n fi í ṣe ẹlẹ́yà pé, “Kábíyèsí, Ọba àwọn Júù!”
30Wọ́n sì tu itọ́ sí i lójú àti ara, wọ́n gba ọ̀pá wọ́n sì nà án mọ́ ọn lórí.
31Nígbà tí wọ́n fi ṣẹ̀sín tán, wọ́n bọ́ aṣọ ara rẹ̀. Wọ́n tún fi aṣọ tirẹ̀ wọ̀ ọ́. Wọ́n sì mú un jáde láti kàn án mọ́ àgbélébùú.
32
33
34Níbẹ̀ ni wọn ti fún un ni ọtí wáìnì tí ó ní egbòogi nínú láti mu. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó tọ́ ọ wò, ó kọ̀ láti mu ún.
35
36Nígbà náà ni wọ́n jókòó yí i ká. Wọ́n ń ṣọ́ ọ níbẹ̀.
37Ní òkè orí rẹ̀, wọ́n kọ ohun kan tí ó kà báyìí pé: “ÈYÍ NI JÉSÙ, ỌBA ÀWỌN JÚÙ” síbẹ̀.
38Wọ́n kan àwọn olè méjì pẹ̀lú rẹ̀ ní òwúrọ̀ náà. Ọ̀kan ní ọwọ́ ọ̀tún, àti èkejì ní ọwọ́ òsì rẹ̀.
39
40
41Bákan náà àwọn olórí àlùfáà pẹ̀lú àwọn akọ̀wé òfin àti àwọn àgbààgbà Júù sì fi í ṣe ẹlẹ́yà.
42Wọ́n kẹ́gàn Rẹ̀ pé, “Ó gba àwọn ẹlòmíràn là, kò sí lè gba ara rẹ̀. Ìwọ ọba àwọn Ísírẹ̀lì? Sọ̀ kalẹ̀ láti orí àgbélébùú nísinsìn yìí, àwa yóò sì gbà ọ́ gbọ́.
43Ó gba Ọlọ́run gbọ́, jẹ́ kí Ọlọ́run gbà á là ní ìsinsin yìí tí òun bá fẹ́ ẹ. Ǹjẹ́ òun kò wí pé, èmi ni Ọmọ Ọlọ́run?”
44Bákan náà, àwọn olè tí a kàn mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú Rẹ̀ fi í ṣe ẹlẹ́yà.
45
46
47Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ kò yé díẹ̀ nínú àwọn ẹni tí ń wòran, nígbà tíwọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, Wọ́n wí pé ọkùnrin yìí ń pe Èlíjà.
48
49Ṣùgbọ́n àwọn ìyókù wí pé, “Ẹ fi í sílẹ̀. Ẹ jẹ́ kí a wò ó bóyá Èlíjà yóò sọ̀ kalẹ̀ láti gbà á là.”
50Nígbà tí Jésù sì kígbe ní ohùn rara lẹ́ẹ̀kan sí i, ó jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀, ó sì kú.
51
52Àwọn isà òkú sì sí sílẹ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn olódodo ọkùnrin àti obìnrin tí ó ti kú sì tún jíǹde.
53Wọ́n jáde wá láti isà òkú lẹ́yìn àjíǹde Jésù, wọ́n sì lọ sí ìlú mímọ́. Níbẹ̀ ni wọ́n ti fi ara han ọ̀pọ̀ ènìyàn.
54
55Ọ̀pọ̀ obìnrin tí ó wá láti Gálílì pẹ̀lú Jésù láti tọ́jú Rẹ̀ wọn ń wò ó láti òkèèrè.
56
57
58lọ sọ́dọ̀ Pílátù, ó sì tọrọ òkú Jésù. Pílátù sì pàṣẹ kí a gbé é fún un.
59Jósẹ́fù sì gbé òkú náà. Ó fi aṣọ funfun mímọ́ dì í.
60Ó sì tẹ́ ẹ sínú ibojì òkúta tí ó gbẹ́ nínú àpáta fúnraa rẹ̀. Ó sì yí òkúta ńlá dí ẹnu ọ̀nà ibojì náà, ó sì lọ.
61Màríà Magidalénì àti Màríà kejì wà níbẹ̀, wọn jòkóò dojú kọ ibojì náà.
62Lọjọ́ kejì tí ó tẹlé ọjọ́ ìpalẹ̀mọ́ àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisí lọ sọ́dọ̀ Pílátù.
63
64Nítorí náà, pàṣẹ kí a ti ibojì rẹ̀ gbọn-ingbọn-in títí ọjọ́ kẹta, kí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Rẹ̀ má ṣe wá jí i gbé lọ, wọn a sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún gbogbo ènìyàn pé, ‘Òun ti jíǹde,’ Bí èyí bá ní láti ṣẹlẹ̀, yóò burú fún wa púpọ̀ ju ti àkọ́kọ́ lọ.”
65Pílátù sì pàṣẹ pé, “Ẹ lo àwọn olùṣọ́ yín kí wọn dáàbò bo ibojì náà bí ẹ bá ti fẹ́.”
66