Ìwé Ìyìnrere Mátíù 4:1-25 BYB2014 - Bible AI

1ⓐ Nígbà náà ni Ẹ̀mí Mímọ́ darí Jésù sí ihà láti dán an wò láti ọwọ́ èsù.

2ⓑ Lẹ́yìn tí Òun ti gbààwẹ̀ ní ogójì ọ̀sán àti ogójì òru, ebi sì ń pa á.

3Nígbà náà ni olùdánwò tọ̀ ọ́ wá, ó wí pé, “Bí ìwọ bá ṣe Ọmọ Ọlọ́run, pàṣẹ kí àwọn òkúta wọ̀nyí di àkàrà.”

4ⓒ Ṣùgbọ́n Jésù dáhùn pé, “A ti kọ ìwé rẹ̀ pé: ‘Ènìyàn kì yóò wà láàyè nípa àkàrà nìkan, bí kò ṣe nípa gbogbo ọ̀rọ̀ ti ó ti ẹnu Ọlọ́run jáde wá.’ ”

5ⓓ Lẹ́yìn èyí ni èṣù gbé e lọ sí ìlú mímọ́ náà; ó gbé e lé ibi ṣóńṣó tẹ̀ḿpìlì.

6ⓔ Ó wí pé, “Bí ìwọ̀ bá jẹ́ ọmọ Ọlọ́run, Bẹ́ sílẹ̀ fún ara rẹ. A sa ti kọ̀wé rẹ̀ pé:

6“ ‘Yóò pàṣẹ fún àwọn ańgẹ́lì rẹ̀ nítorí tìrẹ wọn yóò sì gbé ọ sókè ni ọwọ́ wọn kí ìwọ kí ó má baà fi ẹsẹ̀ rẹ gbún òkúta.’ ”

7ⓕ Jésù sì da lóhùn, “A sìáà ti kọ ọ́ pé: ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ dán Olúwa Ọlọ́run rẹ wò.’ ”

8Lẹ́ẹ̀kan sí i, èṣù gbé e lọ sórí òkè gíga, ó sì fi gbogbo orílẹ̀-èdè ayé àti gbogbo ẹwà wọn hàn án.

9Ó sì wí fún un pé, “Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni èmi yóò fi fún ọ, bí ìwọ bá foríbalẹ̀ tí o sì sìn mi.”

10ⓖ Jésù wí fún un pé, “Kúrò ní ọ̀dọ̀ mi, ìwọ Sàtánì! Nítorí a ti kọ ọ́ pé: ‘Olúwa Ọlọ́run rẹ ni kí ìwọ kí ó fi orí balẹ̀ fún, òun nìkan ṣoṣo ni kí ìwọ ó sìn.’ ”

11ⓗ Nígbà náà ni èṣù fi í sílẹ̀ lọ, àwọn ańgẹ́lì sì tọ̀ ọ́ wá láti jísẹ́ fún un.

12ⓘ Nígbà tí Jésù gbọ wí pé a ti fi Jòhánù sínu túbú ó padà sí Gálílì.

13ⓙ Ó kúrò ní Násárẹ́tì, ó sì lọ ígbé Kápánámù, èyí tí ó wà létí òkun Sébúlónì àti Náfítálì.

14Kí èyí tí a ti sọ tẹ́lẹ̀ láti ẹnu wòlíì Àìsáyà lè ṣẹ pé:

15ⓚ “Iwọ Sébúlónì àti ilẹ̀ Náfítalì ọ̀nà tó lọ sí òkun, ní ọ̀nà Jọ́dánì, Gálílì ti àwọn aláìkọlà,

16Àwọn ènìyàn tí ń gbé ni òkùnkùn tí ri ìmọ́lẹ̀ ńlá, àwọn tó ń gbé nínú ilẹ̀ òjijì iku ni ìmọ́lẹ̀ tan fún.”

17ⓛ Láti ìgbà náà lọ ni Jésù ti bẹ̀rẹ̀ sí wàásù: “Ẹ ronú pìwàdà, nítorí tí ìjọba ọ̀run kù sí dẹ̀dẹ̀.”

18ⓜ Bí Jésù ti ń rìn létí òkun Gálílì, ó rí àwọn arákùnrin méjì, Símónì, ti à ń pè ní Pétérù, àti Ańdérù arákùnrin rẹ̀. Wọ́n ń ju sọ àwọn wọn sínú òkun nítorí apẹja ni wọ́n.

19Jésù wi fun wọn pé, “Ẹ wá, ẹ máa tọ̀ mí lẹ́yìn èmi yóò sì sọ yín di apẹja ènìyàn.”

20Lójú kan náà, wọ́n fi àwọ̀n wọn sílẹ̀, wọ́n sì tẹ̀lé e.

21Bí ó sì ti kúrò ní ibẹ̀, ò rí àwọn arákùnrin méjì mìíràn, Jákọ́bù ọmọ Sébédè àti Jòhánù, arákùnrin rẹ̀. Wọ́n wà nínú ọkọ̀ ojú-omi pẹ̀lú Sébédè baba wọn, wọ́n ń dẹ àwọ̀n wọn, Jésù sì pè wọn náà pẹ̀lú.

22Lójú kan náà, wọ́n fi ọkọ̀ ojú-omi àti baba wọn sílẹ̀, wọ́n sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.

23ⓝ Jésù sì rin káàkiri gbogbo Gálílì, ó ń kọ́ni ní sínágọ́gù, ó ń wàásù ìyìn rere ti ìjọba ọ̀run. ó sì ń ṣe ìwòsàn àrùn gbogbo àti àìsàn láàrin gbogbo ènìyàn.

24Òkìkí rẹ̀ sì kàn yí gbogbo Síríà ká; wọ́n sì gbé àwọn aláìsàn tí ó ní onírúurú àrùn, àwọn tí ó ní ìnira ẹ̀mí èṣù, àti àwọn ti o ní wárápá àti àwọn tí ó ní ẹ̀gbà; ó sì wò wọ́n sàn.

25Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn láti Gálílì, Dékápólì, Jerúsálémù, Jùdíà, àti láti òkè odò Jọ́dánì sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.

cle>