1Nígbà tí ó ti orí òkè sọ̀ kalẹ̀, ọ̀pọ̀ ènìyàn ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.
2
3Jésù si nà ọwọ́ rẹ̀, ó fi bà á, ó wí pé, “Mo fẹ́, ìwọ di mímọ́”. Lójú kan náà, ẹ̀tẹ̀ rẹ̀ sì mọ́!
4
5
6O sì wí pé, “Olúwa, ọmọ-ọ̀dọ̀ mi dùbúlẹ̀ àrùn ẹ̀gbà ni ilé, tòun ti ìrora ńlá.”
7Jésù sì wí fún un pé, “Èmi ń bọ̀ wá mú un láradá.”
8Balógun ọ̀rún náà dahùn, ó wí pé, “Olúwa, èmi kò yẹ ní ẹni tí ìwọ ń wọ̀ abẹ́ òrùlé rẹ̀, ṣùgbọ́n sọ kìkì ọ̀rọ̀ kan, a ó sì mú ọmọ-ọ̀dọ̀ mi láradá.
9Ẹni tí ó wà lábẹ́ àṣẹ sá ni èmi, èmi sí ní ọmọ-ogun lẹ́yìn mi. Bí mo wí fún ẹni kan pé, ‘Lọ,’ a sì lọ, àti fún ẹnì kejì pé, ‘Wá,’ a sì wá, àti fún ọmọ-ọ̀dọ̀ mi pé, ‘Ṣe èyí,’ a sì ṣe é.”
10Nígbà tí Jésù gbọ́ èyí ẹnu yà á, ó sì wí fún àwọn tí ó ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, èmi kò rí ẹnìkan ni Ísírẹ́lì tó ní ìgbàgbọ́ ńlá bí irú èyí.
11
12
13Nítorí náà Jésù sì wí fún balógun ọ̀run náà pé, “Máa lọ ilé, ohun tí ìwọ gbàgbọ́ ti rí bẹ́ẹ̀.” A sì mú ọmọ-ọ̀dọ̀ náà lára dá ní wákàtí kan náà.
14
15Ṣùgbọ́n nígbà tí Jésù fi ọwọ́ kan ọwọ́ rẹ̀, ibà náà fi í sílẹ̀, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ó sì dìde ó ń ṣe ìrànṣẹ fún wọn.
16Nígbà tí ó di àṣálẹ́, ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ó ní ẹ̀mí èṣù ni a mú wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ lé àwọn ẹ̀mí èṣù náà jáde. A sì mú gbogbo àwọn olókùnrùn láradá.
17
18
19Olùkọ́ òfin kan sì tọ̀ ọ́ wá, ó wí fún un pé, “Olùkọ́, èmi ó má tọ̀ ọ́ lẹ́yìn níbikíbi tí ìwọ bá ń lọ.”
20Jésù dá lóhùn pé, “Àwọn kọ̀lọ̀lọ̀kọ̀ ní ihò, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ni ìtẹ́; ṣùgbọ́n Ọmọ Ènìyàn kò ní ibi tí yóò fi orí rẹ̀ lé.”
21Ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ mìíràn sì wí fún un pé, “Olúwa, kọ́kọ́ jẹ́ kí èmi kí ó kọ́ lọ sìnkú bàbá mi ná.”
22
23
24Ní àìròtẹ́lẹ̀, ìjì-líle dìde lórí òkun tó bẹ́ẹ̀ tí rírú omi fi bò ọkọ̀ náà mọ́lẹ̀; ṣùgbọ́n Jésù ń sùn.
25Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, wọn jí i, wọ́n wí pe, “Olúwa, ‘gbà wá,’ àwa yóò rì.”
26
27Ṣùgbọ́n ẹnu yà àwọn ọkùnrin náà, wọ́n sì béèrè pé, “Irú ènìyàn wo ni èyí? kódà ìji-líle àti rírú omi òkun gbọ́ tirẹ̀?”
28
29
30Agbo ẹlẹ́dẹ̀ ńlá tí ń jẹ̀ ń bẹ ní ọ̀nà jíjìn díẹ̀ sí wọn
31Àwọn ẹ̀mí-èsú náà bẹ̀ Jésù wí pé, “Bí ìwọ bá lé wa jáde, jẹ́ kí àwa kí ó lọ sínú agbo ẹlẹ́dẹ̀ yìí.”
32Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ máa lọ!” Nígbà tí wọn sì jáde, wọn lọ sínú agbo ẹlẹ́dẹ̀ náà; sì wò ó, gbogbo agbo ẹlẹ́dẹ̀ náà sì rọ́ gììrì sọ̀ kalẹ̀ bèbè-odò bọ́ sínú òkun, wọ́n sì ṣègbé nínú omi.
33Àwọn ẹni tí ń ṣọ wọn sì sá, wọ́n sì mú ọ̀nà wọn pọ̀n lọ sí ìlú, wọ́n ròyìn ohun gbogbo, àti ohun tí a ṣe fún àwọn ẹlẹ́mìí-èṣù.
34Nígbà náà ni gbogbo ará ìlú náà sì jáde wá í pàdé Jésù. Nígbà tí wọ́n sì rí i, wọ́n bẹ̀ ẹ́, kí ó lọ kúrò ní agbégbé wọn.