Ìwé Òwe 10:1-32 BYB2014 - Bible AI

1Àwọn òwe Sólómónì: Ọlọgbọ́n ọmọ ń mú inú baba rẹ̀ dùn ṣùgbọ́n aláìgbọ́n ọmọ ń ba inú ìyá rẹ̀ jẹ́.

2Ìṣúra tí a kójọ nípa ìwà búburú kò ní èrè ṣùgbọ́n òdodo a máa gbani lọ́wọ́ ikú.

2

3OLÚWA kì í jẹ́ kí ebi máa pa Olódodo ṣùgbọ́n ó ba ète àwọn ènìyàn búburú jẹ́.

3

4Ọwọ́ tí ó lẹ máa ń sọ ènìyàn di talákà, ṣùgbọ́n ọwọ́ tí ó múra síṣẹ́ a máa sọni di ọlọ́rọ̀.

4

5Ẹni tí ó kó irúgbìn jọ ní àsìkò òjò jẹ́ Ọlọ́gbọ́n ọmọ, ṣùgbọ́n ẹni tí ó sùn ní àsìkò ìkórè jẹ́ adójútini ọmọ.

5

6Ìbùkún ní ó máa ń kún orí Olódodo ṣùgbọ́n ìwà ipá máa ń kún ẹnu ènìyàn búburú.

6

7Ìrántí Olódodo yóò jẹ́ ìbùkún ṣùgbọ́n orúkọ ènìyàn búburú yóò jẹrà.

8Ẹni tí ó gbọ́n nínú ọkàn rẹ̀ máa ń gba àṣẹ ṣùgbọ́n ètè wérewère yóò parun.

8

9Ẹni oníwà títọ́ ń rìn láìléwu ṣùgbọ́n àsírí ẹni tí ń rin ọ̀nà pálapàla yóò tú.

9

10Ẹni tí ń sẹ́jú pàkòpàkò fún ibi ń fa àìbalẹ̀ ọkàn Aláìgbọ́n tí ń ṣàròyé kiri yóò parun.

10

11Ẹnu Olódodo jẹ́ oríṣun ìyè ṣùgbọ́n ìwà ipá ni ó gba gbogbo ẹnu ènìyàn búburú.

11

12Ìríra a máa dá ìjà sílẹ̀, ṣùgbọ́n ìfẹ́ a máa bo gbogbo àṣìṣe mọ́lẹ̀.

12

13Ọgbọ́n ni a ń bá lẹ́nu àwọn olóye ṣùgbọ́n kùmọ wà fún ẹ̀yìn àwọn aláìlóye.

13

14Ọlọ́gbọ́n ènìyàn kó ìmọ̀ jọ ṣùgbọ́n ẹnu aláìgbọ́n a máa ṣokùnfà ìparun.

14

15Ọrọ̀ àwọn Olódodo ni ìlú olódi wọn, ṣùgbọ́n òsì ni ìparun aláìní.

15

16Èrè Olódodo ń mú ìyè wá fún wọn ṣùgbọ́n èrè ènìyàn búburú ń mú ìjìyà wá fún wọn.

16

17Ẹni tí ó gbọ́ ìbáwí fi ọ̀nà sí ìyè hàn ṣùgbọ́n ẹni tí ó kọ ìbáwí mú àwọn mìíràn sìnà.

17

18Ẹni tí ó pa ìkórìíra rẹ̀ mọ́ jẹ́ òpùrọ́ ẹni tí ó sì ń báni jẹ́ jẹ́ aláìgbọ́n.

18

19Nínú ọ̀rọ̀ púpọ̀ a kò le fẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ kù ṣùgbọ́n ẹni tí ó pa ẹnu rẹ̀ mọ́ jẹ́ ọlọ́gbọ́n.

19

20Ètè Olódodo jẹ́ àṣàyan fàdákà ṣùgbọ́n ọkàn ènìyàn buburú kò níye lórí.

20

21Ètè Olódodo ń bọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ṣùgbọ́n aláìgbọ́n ń kú nítorí àìlóye.

21

22Ìbùkún OLÚWA ń mú ọrọ̀ wá, kì í sìí fi ìdàámú sí i.

22

23Aláìgbọ́n a máa ní inú dídùn sí ìwà búburú ṣùgbọ́n olóye ènìyàn a máa ní inú dídùn sí ọgbọ́n.

23

24Ohun tí ènìyàn búburú bẹ̀rù yóò dé bá a; Olódodo yóò rí ohun tí ó fẹ́ gbà.

24

25Nígbà tí ìjì bá ti jà kọjá, ènìyàn búburú a kọjá lọ, ṣùgbọ́n Olódodo yóò dúró ṣinṣin láéláé.

25

26Bí ọtí kíkan sí eyín, àti èéfín sí ojú bẹ́ẹ̀ ni ọ̀lẹ sí ẹni tí ó rán an níṣẹ́.

26

27Ìbẹ̀rù OLÚWA ń mú ọjọ́ ayé gígùn wá, ṣùgbọ́n a gé ojọ́ ayé ènìyàn búburú kúrú.

27

28Ìrètí Olódodo ni ayọ̀ ṣùgbọ́n ìrètí ènìyàn buburú já sí òfo.

28

29Ọ̀nà OLÚWA jẹ́ ààbò fún Olódodo, ṣùgbọ́n ìparun ni ó jẹ́ fún àwọn tí ń se ibi.

29

30A kì yóò fa Olódodo tu láéláé ṣùgbọ́n ènìyàn buburú kì yóò dúró pẹ́ lórí ilẹ̀.

30

31Ẹnu Olódodo ń mú ọgbọ́n jáde wá, ṣùgbọ́n ètè àyípadà ni a ó gé kúrò.

31

32Ètè Olódodo mọ ohun tí ó tọ́, ṣùgbọ́n ètè ènìyàn búburú kò mọ̀ ju èké lọ.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide