1Ẹnikẹ́ni tí ó fẹ́ ẹ̀kọ́ fẹ́ ìmọ̀, ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó kórìíra ìbáwí jẹ́ aláìgbọ́n.
2Ènìyàn rere gba ojú rere lọ́dọ̀ OLÚWA ṣùgbọ́n OLÚWA kórìíra alárekérekè ènìyàn.
2
3A kò lè fi ẹsẹ̀ ènìyàn múlẹ̀ nípa ìwà búburú ṣùgbọ́n a kò le è fa Olódodo tu.
3
4Aya oníwà rere ni adé ọkọ rẹ̀ ṣùgbọ́n aya adójútini dàbí ìgbà tí inú egungun rẹ̀ jẹrà.
4
5Ète àwọn Olódodo dára ṣùgbọ́n ìmúra ènìyàn búburú jẹ́ ẹ̀tàn.
5
6Ọ̀rọ̀ ènìyàn búburú lúgọ de ẹ̀jẹ̀ ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ àwọn Olódodo gbà wọ́n là.
6
7A sí àwọn ènìyàn búburú ní ìdí, wọn kò sì sí mọ́; ṣùgbọ́n ilé Olódodo dúró ṣinṣin.
7
8A ń yín ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n ọgbọ́n rẹ̀ ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn ọlọ́pọlọ wúruwùru ni a kẹ́gàn.
8
9Ó sàn kí a má jẹ́ ènìyàn pàtàkì kí a sì ní ìránṣẹ́ ju kí a díbọ́n pé a jẹ́ ẹni pàtàkì láì lóúnjẹ.
9
10Ènìyàn rere ń ṣaájò ohun tí àwọn ohun ọ̀sìn rẹ̀ nílò Àmọ́ ìwà tó dára jù tí ènìyàn búburú lè hù, ibi ni.
10
11Ẹni tí ó bá dáko yóò ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ oúnjẹ, ṣùgbọ́n ẹni tí ń lépa òjìji lásánlàsàn kò gbọ́n.
11
12Ènìyàn búburú ń fẹ́ ìkógún àwọn ènìyàn ìkà ṣùgbọ́n gbòǹgbò Olódodo ń gbilẹ̀.
12
13A mú ènìyàn búburú nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ ẹsẹ̀ rẹ̀ ṣùgbọ́n Olódodo bọ́ kúrò lọ́wọ́ ìdàámú.
13
14Láti inú èso rẹ̀, ènìyàn kún fún onírúurú ohun rere bí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ti ń pín in lérè dájúdájú.
14
15Ọ̀nà aláìgbọ́n dára lójú ara rẹ̀ ṣùgbọ́n Ọlọgbọ́n ènìyàn a máa gba ìmọ̀ràn.
15
16Aláìgbọ́n ènìyàn fi ìbínú un rẹ̀ hàn lẹ́ṣẹ̀kẹṣẹ̀, ṣùgbọ́n olóye ènìyàn fojú fo ìyànjẹ.
16
17Ẹni tí ó jẹ́ ajẹ́rìí tòótọ́ jẹ́rìí ohun tí ojú rẹ̀ rí ṣùgbọ́n ajẹ́rìí èké máa ń parọ́.
17
18Ọ̀rọ̀ tí a kò rò jinlẹ̀ máa ń gún ni bí ọ̀kọ̀ ṣùgbọ́n ahọ́n ọlọgbọ́n ń mú ìwòsàn wá.
18
19Ètè tí ń sòótọ́ yóò wà láéláé ṣùgbọ́n ahọ́n tí ń parọ́ kì í tọ́jọ́.
19
20Ẹ̀tàn wà nínú ọkàn àwọn tí ń pète búburú ṣùgbọ̀n ayọ̀ wà fún àwọn tí ń mú kí àlàáfíà gbilẹ̀.
20
21Ibi kì í ṣubú lu Olódodo rárá ṣùgbọ́n ènìyàn búburú gba ìpín ìyọnu tiwọn.
21
22OLÚWA kóìríra ètè tí ń parọ́ ṣùgbọ́n ó ní inú dídùn sí àwọn Olóòótọ́.
22
23Ènìyàn Olóye fi ìmọ̀ rẹ̀ pamọ́ sínú ara rẹ̀ ṣùgbọ́n ọkàn ènìyàn búburú ń gbé ìwà òmùgọ̀ jáde.
23
24Ọwọ́ àìṣọ̀lẹ yóò jọba ṣùgbọ́n ọ̀lẹ ṣíṣe a máa yọrí sí sínsìnrú.
24
25Ìbànújẹ́ ní ọkàn ènìyàn ní dorí rẹ̀ kodò ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ rere a máa mú kó yọ̀.
25
26Olódodo ènìyàn máa ń ṣọ́ra láti dọ́rẹ̀ẹ́ ṣùgbọ́n ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú ń mú wọn sìnà.
26
27Ọ̀lẹ ènìyàn kò sun ẹran tí ó pa lóko ọdẹ ṣùgbọ́n ẹni tí kì í ṣe ọ̀lẹ máa ń díwọ̀n ohun ìní rẹ̀.
27
28Ní ọ̀nà àwọn Olódodo ni ìyè wà ní ọ̀nà náà ni àìkú wà.