Ìwé Òwe 13:1-25 BYB2014 - Bible AI

1Ọlọ́gbọ́n ọmọ pa àṣẹ baba rẹ̀ mọ́ ṣùgbọ́n ẹlẹ́gàn kò fetí sí ìbáwí.

2Láti inú èso ẹnu rẹ̀ ènìyàn ń gbádùn àwọn ohun rere ṣùgbọ́n, aláìsòótọ́ ní ìfẹ́ ọkàn láti inú ìwà ipá.

2

3Ẹnikẹ́ni tí ó ṣọ́ ẹnu rẹ̀ pa ẹnu ara rẹ̀ mọ́, ṣùgbọ́n ẹni tí ó ń sọ̀rọ̀ gbàù-gbàù yóò parun.

3

4Ọkàn ọ̀lẹ ń fẹ́, ṣùgbọ́n kò rí nǹkankan, ṣùgbọ́n ọkàn àwọn ti kì í ṣọ̀lẹ rí ìtẹ́lọ́rùn.

4

5Olódodo kórìíra ohun tí í ṣe irọ́ Ṣùgbọ́n ènìyàn búburú hu ìwà ìríra àti ìtìjú.

5

6Òdodo ń ṣamọ̀nà ènìyàn olóòótọ́ inú, ṣùgbọ́n ìwà búburú sí ẹlẹ́ṣẹ̀ nípò.

6

7Ènìyàn kan díbọ́n bí ẹni tí ó ní ọrọ̀ síbẹ̀ kò ní nǹkankan ẹlòmííràn díbọ́n bí i talákà, síbẹ̀ ó ní ọrọ̀ púpọ̀.

7

8Ọrọ̀ ènìyàn le è ra ẹ̀mí rẹ̀ ṣùgbọ́n talákà kì í gbọ́ ìdẹ́rùbà.

8

9Ìmọ́lẹ̀ olódodo tàn roro, ṣùgbọ́n àtùpà ènìyàn búburú ni a pa kú.

9

10Ìgbéraga máa ń dá ìjà sílẹ̀ ni ṣùgbọ́n ọgbọ́n wà nínú àwọn tí ń gba ìmọ̀ràn.

10

11Owó tí a fi ọ̀nà èrú kó jọ yóò sí lọ, ṣùgbọ́n ẹni tí ń kó owó jọ díẹ̀ díẹ̀ yóò pọ̀ síi.

11

12Ìrètí tí ń falẹ̀ máa ń mú kí ọkàn ṣàárẹ̀ ṣùgbọ́n ìrètí tí a rí gbà jẹ́ igi ìyè.

12

13Ẹni tí ó kẹ́gàn ẹ̀kọ́ yóò jìyà rẹ̀ ṣùgbọ́n ẹni tí ó pa àṣẹ mọ́ gba èrè rẹ̀.

13

14Ìkọ́ni ọlọ́gbọ́n jẹ́ orísun ìyè, tí ń yí ènìyàn padà kúrò nínú ìdẹkùn ikú.

14

15Òye pípé ń mú ni rí ojú rere Ṣùgbọ́n ọ̀nà aláìsòótọ́ kì í tọ́jọ́.

15

16Gbogbo olóye ènìyàn máa ń hùwà pẹ̀lú ìmọ̀ Ṣùgbọ́n aláìgbọ́n a fi ìwà òmùgọ̀ rẹ̀ hàn.

16

17Ìránṣẹ́ búburú bọ́ sínú ìdàámú ṣùgbọ́n aṣojú olóòtọ́ mú ìwòsàn wá.

17

18Ẹni tí ó kọ ìbáwí yóò di talákà yóò sì rí ìtìjú, ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbọ́ ìbáwí ni yóò rí ọlá.

18

19Ìfẹ́ tí a múṣẹ dùnmọ́ ọkàn ṣùgbọ́n ìríra ni fún aṣiwèrè láti kúrò nínú ibi.

19

20Ẹni tí ó ń bá ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n ṣùgbọ́n ẹni tí ń bá aláìgbọ́n kẹ́gbẹ́ ń pa ara rẹ̀ lára.

20

21Òsì a máa ta ẹlẹ́ṣẹ̀, ṣùgbọ́n ọrọ̀ ni èrè fún olódodo.

21

22Ènìyàn rere a máa fi ogún sílẹ̀ fún àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀, ṣùgbọ́n, a kó ọrọ̀ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ pamọ́ fún àwọn olódodo.

22

23Ilẹ̀ ẹ talákà le è mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ irè oko wá ṣùgbọ́n àìsòdodo gbá gbogbo rẹ̀ lọ.

23

24Ẹni tí ó fa ọwọ́ ìbáwí sẹ́yìn kórìíra ọmọ rẹ̀ ṣùgbọ́n ẹni tí ó fẹ́ràn ọmọ rẹ̀ yóò máa báa wí.

24

25Olódodo jẹ́wọ́ títí ó fi tẹ́ ọkàn rẹ̀ lọ́rùn ṣùgbọ́n ebi yóò máa pa ikùn ènìyàn búburú.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide