1Ti ènìyàn ni ìgbèrò inú ọkàn Ṣùgbọ́n láti ọ̀dọ̀ OLÚWA ni ìdáhùn ahọ́n ti ń wá.
2Gbogbo ọ̀nà ènìyàn ni ó dà bí i pé ó dára lójú ara rẹ̀ Ṣùgbọ́n OLÚWA ló ń díwọ̀n èrò inú ọkàn.
2
3Fi ohun gbogbo tí o bá ṣe lé OLÚWA lọ́wọ́ Èrò rẹ yóò sì ṣe é ṣe.
3
4OLÚWA ti ṣe ohun gbogbo láti mú kí ó rí bí ó ṣe fẹ́ Kódà ènìyàn búburú fún ọjọ́ ìpọ́njú.
4
5OLÚWA kórìíra gbogbo ẹni tí ń gbéraga lọ́kàn rẹ̀ mọ èyí dájú pé wọn kò ní lọ láìjìyà.
5
6Nípaṣẹ̀ ìfẹ́ àti òtítọ́ a ṣètùtù ẹ̀ṣẹ̀ nípaṣẹ̀ ìbẹ̀rù OLÚWA ènìyàn sá fún ibi.
6
7Nígbà tí ọ̀nà ènìyàn bá tẹ́ OLÚWA lọ́rùn, yóò mú kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ gàn-án bá a gbé ní àlàáfíà.
7
8Ó sàn kí ó kéré pẹ̀lú òdodo ju èrè púpọ̀ pẹ̀lú èrú.
8
9Ènìyàn a máa pète ọ̀nà ara rẹ̀ lọ́kàn an rẹ̀ ṣùgbọ́n OLÚWA ní í pinnu ìgbésẹ̀ rẹ̀.
9
10Ètè ọba a máa sọ̀rọ̀ nípa inú síi ẹnu rẹ̀ kò gbọdọ̀ gbé ẹ̀bi fún ara rẹ̀.
10
11Òdiwọ̀n àti òṣùwọ̀n òtítọ́ wá láti ọ̀dọ̀ OLÚWA; gbogbo wíwúwo àpò jẹ́ láti ọwọ́ rẹ̀.
11
12Àwọn ọba kórìírà ìwà àìtọ́ nítorí òdodo ní í fi ìdí ìtẹ́ múlẹ̀.
12
13Àwọn ọba ní inú dídùn sí ètè tí ń ṣòótọ́ ènìyàn tí ń sọ òtítọ́ ṣe iyebíye sí wọn.
13
14Ìrànṣẹ́ ikú ni ìbínú ọba jẹ́ ṣùgbọ́n ọlọgbọ́n ènìyàn yóò tù ú nínú.
14
15Nígbà tí ojú ọba bá túká, ó túmọ̀ sí ìyè; ojú rere rẹ̀ dàbí i ṣíṣú òjò ní ìgbà òjò.
15
16Ó ti dára tó láti ní ọgbọ́n ju wúrà lọ àti láti yan òye dípò o fàdákà!
16
17Òpópó ọ̀nà àwọn ẹni dídúró ṣinṣin yàgò fún ibi, ẹni tí ó ṣọ́ ọ̀nà rẹ̀, ṣọ́ ẹnu ara rẹ̀.
17
18Ìgbéraga ní í ṣáájú ìparun, agídí ọkàn ní í ṣáájú ìṣubú,
19ó sàn láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ọkàn láàrin àwọn olùpọ́njú jù láti máa pín ìpín pẹ̀lú àwọn agbéraga.
19
20Ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé ẹ̀kọ́ yóò rí ire, ìbùkún sì ni fún ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀ lé OLÚWA.
20
21Àwọn tí ó gbọ́n nínú ọkàn là ń pè ní olóye ọ̀rọ̀ ìtura sì ń mú ẹ̀kọ́ gbèrú.
21
22Òye jẹ́ oríṣun ìyè fún àwọn tí ó ní i, ṣùgbọ́n ìwà òmùgọ̀ ń kó ìyà jẹ aláìgbọ́n.
22
23Ọkàn ọlọgbọ́n ènìyàn a máa ṣọ́ ẹnu rẹ̀ ètè rẹ̀ sì ń mú kí ẹ̀kọ́ gbèrú.
23
24Ọ̀rọ̀ ìtura dàbí afárá oyin ó dùn fún ọkàn, ó sì fi ìlera fún egungun.
24
25Ọ̀nà kan tí ó dàbí i pé ó dára lójú ènìyàn ṣùgbọ́n ní ìgbẹ̀yìn a ṣokùnfà ikú.
25
26Ìfẹ́-àti-jẹun alágbàṣe ń ṣiṣẹ́ fún un nítorí ebi rẹ̀ mú kí ó máa ṣiṣẹ́ ni.
26
27Ènìyàn búburú ń pète ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì dàbí i iná tí ń jóni.
27
28Aláyìídáyidà ènìyàn dá ìjà sílẹ̀ olófòófó a sì máa pín ọ̀rẹ́ kòríkòsùn níyà.
28
29Oníjàgídíjàgan ènìyàn tan aládùúgbò rẹ̀ ó sì mú un sọ̀kalẹ̀ lọ sí ọ̀nà tí kò dára.
29
30Ẹni tí ń ṣẹ́jú ń pètekéte; ẹni tí ó ṣu ẹnu jọ ń pète aburú.
30
31Ewú orí jẹ́ ògo ìgbé ayé òdodo ní í múni débẹ̀.
31
32Ó sàn láti jẹ́ oníṣùúrù ju ajagun ènìyàn lọ, ẹni tí ó pa ìbínú mọ́ra ju ajagun-gbàlú lọ.
32
33A ṣẹ́ kèké dàsí ìṣẹ́po aṣọ, ṣùgbọ́n gbogbo ìdájọ́ rẹ̀ wá láti ọ̀dọ̀ OLÚWA.