1Òkèlè gbígbẹ tòun tàlàáfíà àti ìdákẹ́jẹ́ sàn ju ilé tí ó kún fọ́fọ́ fún ẹran àti ìjà.
2Ọlọ́gbọ́n ìránṣẹ́ yóò ṣàkóso adójútini ọmọ, yóò sì pín ogún gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ.
2
3Iná ni a fi fọ́ Sílífà àti wúrà Ṣùgbọ́n OLÚWA ló ń dán ọkàn wò.
3
4Ènìyàn búburú ń tẹ́tí sí ètè tí ń sọ ibi òpùrọ́ a máa fetí sí ahọ́n búburú.
4
5Ẹni tí ó fi talákà ṣe yẹ̀yẹ́ kórìíra ẹlẹ́dàá talákà náà ẹnikẹ́ni tí ń yọ̀ torí ìyọnu kò ní lọ láìjìyà.
5
6Ọmọ-Ọmọ ni adé orí arúgbó òbí sì ni ìyangàn àwọn ọmọ.
6
7Ọ̀rọ̀ dídùn kò yẹ aláìgbọ́n, mélòó mélòó ni ètè tí ń parọ́ fún àwọn alákóso!
7
8Àbẹ̀tẹ́lẹ̀ jẹ́ oògùn fún ẹni tí ó ń fún ni ohun gbogbo, ibikíbi tí ó bá tẹ̀ sí ni ó ń yege.
8
9Ẹni tí ó fojú fo ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ṣẹ̀ẹ́ mú kí ìfẹ́ gbòòrò sí i. Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ń tẹnumọ́ ọ̀rọ̀ yóò pín ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ méjì níyà.
9
10Ọ̀rọ̀ ìbáwí dun ènìyàn olóye ju ọgọ́rùn ún pàsán lẹ́yìn aláìgbọ́n.
10
11Oríkunkun ni ènìyàn ìkà máa ń ṣe, ìjòyè aláìláàánú ni a ó rán sí i.
11
12Ó sàn kí ènìyàn pàdé béárì tí a ti kó lọ́mọ jù aláìgbọ́n nínú ìwà òmùgọ̀ rẹ̀.
12
13Bí ènìyàn kan bá fi ibi san ire, ibi kì yóò kúrò nílé rẹ̀ láéláé.
13
14Bíbẹ̀rẹ̀ ìjà dàbí ẹni tí ó dá ojú fún adágún omi nítorí náà mẹ́nu kúrò nínú ọ̀rọ̀ kí ó tó di ìjà.
14
15Gbígbé ẹ̀bi fún aláre àti dídá ẹni jàre lẹ́bi, OLÚWA kóríra méjèèjì.
15
16Kí ni ìwúlò owó lọ́wọ́ aṣiwèrè níwọ̀n bí kò ti ní èròńgbà láti rí ọgbọ́n?
16
17Ọ̀rẹ́ a máa fẹ́ni nígbà gbogbo, Arákùnrin sì wà fún ìgbà ìpọ́njú.
17
18Ènìyàn aláìgbọ́n ṣe ìbúra ó sì ṣe onídùúró fún aládùúgbò rẹ̀.
18
19Ẹni tí ó fẹ́ràn ìjà fẹ́ràn ẹ̀ṣẹ̀; ẹni tí ó kọ́ ibodè gígàn ń wá ìparun.
19
20Ènìyàn aláyìídáyidà ọkàn kì í gbèrú ẹni tí ó ní ahọ́n ẹ̀tàn bọ́ sínú ìyọnu.
20
21Láti bí aláìgbọ́n lọmọ a máa fa ìbànújẹ́ ọkàn kò sí ayọ̀ fún baba ọmọ tí kò gbọ́n.
21
22Ọkàn tí ó túká jẹ́ ogún gidi ṣùgbọ́n ọkàn tí ó bàjẹ́ a máa mú kí egungun gbẹ.
22
23Ènìyàn búburú a gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀ láti yí ìdájọ́ po.
23
24Olóyè ènìyàn gbójú wo ọgbọ́n níwájú ṣùgbọ́n ojú aláìgbọ́n ń wò káàkiri ilẹ̀ ayé.
24
25Aláìgbọ́n ọmọ mú ìbànújẹ́ bá baba rẹ̀ àti ìkorò fún ẹni tí ó bí i lọ́mọ.
25
26Kò dára láti fìyà jẹ ènìyàn tí kò ṣẹ̀ tàbí láti na ìjòyè lórí òtítọ́ inú wọn.
26
27Ènìyàn tó ní ìmọ̀ máa ń ṣọ́ra fún àwọn ọ̀rọ̀ tí ó ń sọ ènìyàn olóye sì máa ń ní ṣùúrù.
27
28Kódà aláìgbọ́n máa ń dàbí ọlọgbọ́n bí ó bá dákẹ́ àti bí olóye bí ó bá fètèmétè.