1Ènìyàn tí kò báni rẹ́ a máa lépa ìmọ̀ ara rẹ̀; ó kọjú ìjà sí gbogbo ìdájọ́ òdodo.
2Aláìgbọ́n kò rí inú dídùn sí òye ṣùgbọn ó ní inú dídùn sí ṣíṣọ èrò tirẹ̀.
2
3Nígbà ti ènìyàn búburú dé ni ẹ̀gàn dé nígbà ti ẹ̀gàn dé ni ìtìjú dé.
3
4Ọ̀rọ̀ ẹnu ènìyàn jẹ́ omi jínjìn ṣùgbọ́n oríṣun ọgbọ́n jẹ́ odò tí ń ṣàn.
4
5Kò dára kí ènìyàn ṣe ojúṣáájú fún ènìyàn búburú tàbí kí a fi ìdájọ́ òdodo du aláìṣẹ̀.
5
6Ètè aláìgbọ́n dá ìjà sílẹ̀ ẹnu rẹ̀ sì ń ṣokùnfà ẹgba.
6
7Ẹnu aláìgbọ́n ni ó ba tirẹ̀ jẹ́ ètè rẹ̀ sì jẹ́ ìdẹkùn fún ọkàn rẹ̀.
7
8Ọ̀rọ̀ olófòófó dàbí oúnjẹ àdídùn wọ́n ń sọ̀kalẹ̀ lọ sí akínyẹmí ara.
8
9Ẹni tí kò ṣe déédé nínú iṣẹ́ rẹ̀ arákùnrin ló jẹ́ fún apanirun.
9
10Orúkọ OLÚWA, ilé ìṣọ́ agbára ni; olódodo sá wọ inú rẹ̀, ó sì rí ìgbàlà.
10
11Ọ̀rọ̀ olówó ni ìlú olódi wọn wọ́n rò ó bí i wí pé odi tí kò ṣe é gùn ni.
11
12Sáájú ìṣubú ọkàn ènìyàn a kọ́kọ́ máa gbéraga ṣùgbọ́n ìrẹ̀lẹ̀ ni ó máa ń ṣáájú ọlá.
12
13Ẹni tí ó ń fèsì kí ó tó gbọ́ òun náà ni ìwà òmùgọ̀ àti ìtìjú rẹ̀.
13
14Ọkàn ènìyàn a máa gbé e ró nígbà àìsàn ṣùgbọ́n ta ni ó le forí ti ọkàn tí ó rẹ̀wẹ̀sì.
14
15Ọkàn olóye ní i gba ìmọ̀; etí ọlọ́gbọ́n ní í ṣe àwárí rẹ̀.
15
16Ẹ̀bùn máa ń sí ọ̀nà fún ẹni tí ń fún ni lẹ́bùn a sì mú un wọlé sí ọ̀dọ̀ àwọn olókìkí.
16
17Ẹni tí ó kọ́kọ́ rojọ́ máa ń dàbí i pé ó jàre títí ẹlòmíràn yóò fi bọ́ síwájú kí ó sì tú àsírí gbogbo.
17
18Ìbò dídì máa ń parí ìjà a sì mú kí àwọn alátakò méjì jìnnà sí ara wọn.
18
19Arákùnrin tí a ṣẹ̀ ṣòroó yípadà ju ìlú olódi lọ, ìjà sì dàbí ibodè ìlú olódi ńlá tí a ṣe.
19
20Láti inú èso ẹnu rẹ̀ ikùn ènìyàn a yó; láti inú ìkórè ẹnu rẹ̀ ni ó ti jẹ yó.
20
21Ahọ́n ni agbára ìyè àti ikú, àwọn tí ó sì fẹ́ràn rẹ̀ yóò jẹẹ́.
21
22Ẹni tí ó rí aya fẹ́, rí ohun rere, Ó sì gba ojú rere lọ́dọ̀ OLÚWA.
22
23Tálákà ń bẹ̀bẹ̀ fún àánú, Ṣùgbọ́n ọlọ́rọ̀ a dáhùn pẹ̀lú ìkanra.
23
24Ènìyàn tí ó ní ọ̀rẹ́ púpọ̀ le è parun Ṣùgbọ́n ọ̀rẹ́ kan wà tí ó sún mọ́ ni tímọ́ tímọ́ ju arákùnrin.