1Ó sàn kí èèyàn jẹ́ tálákà tí ìrìn rẹ̀ kò lábùkù ju aláìgbọ́n tí ètè rẹ̀ jẹ́ àyídáyidà.
2Kò dára láti ní ìtara láì ní ìmọ̀ tàbí kí ènìyàn kánjú kí ó sì sìnà.
2
3Ìwà òmùgọ̀ ènìyàn fúnra rẹ̀ a pa ẹ̀mí rẹ̀ run; ṣíbẹ̀ ọkàn rẹ̀ yóò máa bínú sí OLÚWA.
3
4Ọrọ̀ má a ń fa ọ̀rẹ́ púpọ̀; ṣùgbọ̀n ọ̀rẹ́ ẹ talákà tún kọ̀ ọ́ sílẹ̀.
4
5Ajẹ́rìí èké kò ní lọ láì jìyà, ẹni tí ó sì ń tú irọ́ jáde kò ní lọ lọ́fẹ̀ẹ́.
5
6Ọ̀pọ̀ ń wá ojú rere Olórí; gbogbo ènìyàn sì ni ọ̀rẹ́ ẹni tí ó lawọ́.
6
7Gbogbo ará ilé e talákà ni ó pa á tì mélòómélòó ni ti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tí ń sá fún un! Bí ó tilẹ̀ ń lé wọn kiri pẹ̀lú ẹ̀bẹ̀, kò tilẹ̀ rí wọn rárá.
7
8Ẹni tí ó gba ọgbọ́n fẹ́ràn ọkàn ara rẹ̀; ẹni tí ó bá káràmáṣìkí òye yóò gbèrú.
8
9Ajẹ́rìí èké kì yóò lọ láìjìyà ẹni tí ó sì ń tú irọ́ jáde yóò parun.
9
10Kò yẹ aláìgbọ́n láti máa gbé nínú ọlá ńlá, mélòó mélòó bí ó ti burú tó fún ẹrú láti jọba lórí ọmọ aládé.
10
11Ọgbọ́n ènìyàn a máa fún un ní ṣùúrù; fún ògo rẹ̀ ni láti fojú fo àṣìṣe dá.
11
12Ìbínú ọba dàbí kíke e kìnnìún, ṣùgbọ́n ojúrere rẹ̀ dàbí ìrì lára koríko.
12
13Aláìgbọ́n ọmọ jẹ́ ìparun baba rẹ̀, Aya tí ó máa ń jà sì dàbí ọ̀sọ̀ọ̀rọ̀ òjò.
13
14A máa ń jogún ilé àti ọrọ̀ lọ́dọ̀ òbí ṣùgbọ́n aya olóye láti ọdọ̀ OLÚWA ni.
14
15Ọ̀lẹ ṣíṣẹ́ máa ń fa oorun sísùn fọnfọnfọn ebi yóò sì máa pa ènìyàn tí ó lọ́ra.
15
16Ẹni-kẹ́ni tí ó gbọ́ ẹ̀kọ́ pa ẹnu rẹ̀ mọ́ ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá kẹ́gàn ọ̀nà rẹ̀ yóò kú.
16
17Ẹni tí ó ṣáànú talákà, OLÚWA ní ó yá yóò sì pín in lérè ohun tí ó ti ṣe.
17
18Bá ọmọ rẹ wí nítorí nínú ìyẹn ni ìrètí wà; àìṣe bẹ́ẹ̀ ìwọ lọ́wọ́ nínú iparun un rẹ̀.
18
19Ènìyàn onínú-fùfù gbọdọ̀ gba èrè ìwà rẹ̀ bí ìwọ bá gbàá là, ìwọ yóò tún ní láti ṣe é lẹ́ẹ̀kan síi.
19
20Fetí sí ìmọ̀ràn kí o sì gba ẹ̀kọ́ ní ìgbẹ̀yìn gbẹ́yín ìwọ yóò di ọlọ́gbọ́n.
20
21Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ète inú ọkàn ènìyàn ṣùgbọ́n ìfẹ́ OLÚWA ní ó máa ń borí.
21
22Ohun tí ènìyàn ń fẹ́ ni ìfẹ́ tí kì í yẹ̀; ó sàn láti jẹ́ talákà ju òpùrọ́ lọ.
22
23Ìbẹ̀rù OLÚWA ń mú ìyè wá: nígbà náà ọkàn ń balẹ̀, láì sí ewu.
23
24Ọ̀lẹ ki ọwọ́ rẹ̀ bọ inú àwo oúnjẹ; kò tilẹ̀ ní mú u padà wá sí ẹnu rẹ̀.
24
25Na ẹlẹ́gàn, òpè yóò sì kọ́gbọ́n; bá olóye ènìyàn wí, yóò sì ní ìmọ̀ síi.
25
26Ẹni tí ó já baba rẹ̀ lulẹ̀, tí ó sì lé ìyá rẹ̀ jáde ó jẹ́ adójútini ọmọ.
26
27Yéé tẹ́tí sí ẹ̀kọ́ tí í mú ni ṣìnà ọmọ mi, ìwọ kì yóò sì sìnà kúrò nínú ọ̀rọ̀ ìmọ̀.
27
28Ajẹ́rìí tí ó bàjẹ́ máa ń kẹ́gàn ìdájọ́ òtítọ́ ẹnu ènìyàn búburú sì ń gbé ibi mi.
28
29A ti pèṣè ìjìyà sílẹ̀ fún ẹlẹ́gàn; àti pàṣán fún ẹ̀yìn aláìgbọ́n.