1Ọmọ mi, bí ìwọ bá gba ọ̀rọ̀ mi, tí ìwọ sì pa òfin mi mọ́ sí inú rẹ,
2tí o tẹ́ etí rẹ sílẹ̀ sí ọgbọ́n tí o sì fi ọkàn rẹ sí òye,
3bí ìwọ sì pè fún ojú inú rẹ ríran tí o sì kígbe sókè fún òye
4bí ìwọ bá wá ṣàfẹ́rì rẹ̀ bí i fàdákà tí o sì wa kiri bí i fún ohun iyebíye tó fara sin.
5Nígbà náà ni òye ẹ̀rù OLÚWA yóò yé ọ, tí ó sì rí ìmọ̀ Ọlọ́run.
6Nítorí OLÚWA ni ó ń fún ni ní ọgbọ́n, láti ẹnu rẹ̀ sì ni ìmọ̀ àti òye ti ń wá
7Ó to ìgbàlà fún àwọn olódodo, Òun ni aṣà fún àwọn tí ń rìn déédé,
8ó pa ipa ọ̀nà ìdájọ́ mọ́ Ó sì ń pa ọ̀nà àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ mọ́.
9Nígbà náà ni òye ohun tí ó tọ̀nà tí ó sì dára, tí ó dára yóò yẹ́ ọ—gbogbo ọ̀nà dídara.
10Nítorí ọgbọ́n yóò wọ inú ọkàn rẹ ìmọ̀ yóò sì jẹ́ ìtura fún ọkàn rẹ
11Ara (ikú) sísọ ni yóò dáàbò bò ọ Òye yóò sì pa ọ́ mọ́.
11
12Ọgbọ́n yóò gbà ọ́ là kúrò ní ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú, lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn tí ọrọ̀ ọ wọn jẹ́ àyídáyidà,
13tí ó kúrò ní ọ̀nà tààrà láti rìn ní ọ̀nà tí ó ṣókùnkùn,
14tí ó ní inú dídùn sí ibi ṣíṣe tí ó sì ń yayọ̀ nínú àyídáyidà ibi,
15ọ̀nà àwọn tí ó ṣe pálapàla tí wọ́n sì jẹ́ alérekérekè ní ọ̀nà wọn.
15
16Yóò gba ìwọ pẹ̀lú là kúrò lọ́wọ́ àwọn àgbèrè Obìnrin lọ́wọ́ aya oníwàkúwà àti àwọn ọ̀rọ̀ ìtànjẹ rẹ̀,
17tí ó ti fi ọkọ àkọ́fẹ́ ìgbà èwe rẹ̀ sílẹ̀ tí ó sì gbàgbé májẹ̀mú tí ó ti dá níwájú Ọlọ́run.
18Nítorí ilé rẹ̀ jẹ́ ọ̀nà sí ikú ọ̀nà rẹ̀ sì lọ sí ibi ẹ̀mí àwọn òkú.
19Kò sẹ́ni tó lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ tí ó padà tàbí tí ó rí ipa ọ̀nà ìyè.