Ìwé Òwe 20:1-30 BYB2014 - Bible AI

1Ẹlẹ́yà ni ọtí wáìnì, aláriwo sì ní ọ̀tí líle ẹnikẹ́ni tí ó bá sìnà nìpaṣẹ̀ wọn kò gbọ́n.

2Ìbínú ọba dàbí kíké e kìnnìún; ẹnikẹ́ni tí ó bá mú-un bínú ba ayé ara rẹ̀ jẹ́.

2

3Iyì ni ó jẹ́ fún ènìyàn láti sá fún ìjà ṣùgbọ́n gbogbo aláìgbọ́n a máa tètè wá ìjà.

3

4Ọ̀lẹ kì í ṣiṣẹ́ oko nígbà tí ó yẹ nítorí náà ní àsìkò ìkórè, yóò wá kò sì ní rì nǹkan.

4

5Ètè ọkàn ènìyàn dàbí, omi jínjìn; ṣùgbọ́n ènìyàn olóye á wá wọn jáde.

5

6Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni wọ́n máa ń wí oore wọn jáde, ṣùgbọ́nn kò rọrùn láti rí ènìyàn olóòótọ́.

6

7Olódodo ènìyàn a máa gbé ìgbé ayé àìlábùkù ìbùkún ni fún àwọn ọmọ rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀.

7

8Nígbà tí ọba bá jókóò sórí ilẹ̀ rẹ̀ láti ṣe ìdájọ́ yóò fẹ́ gbogbo ibi dànù pẹ̀lú ojú rẹ̀.

8

9Táni ó le è wí pé, “Mo ti ṣe ọkàn mi ní mímọ́, mo mọ́, n kò sì lẹ́ṣẹ̀”?

9

10Ìdíwọ̀n èké àti òṣùwọ̀n ìrẹ́jẹ OLÚWA kórìíra méjèèjì.

10

11Kódà a mọ ọmọdé nípa iṣẹ́ rẹ̀ nípa pe bóyá iṣẹ́ rẹ mọ́ tàbí pé ó tọ̀nà.

11

12Etí tí ó ń gbọ́ àti ojú tí ó ń ríran OLÚWA ni ó dá méjèèjì.

12

13Má ṣe fẹ́ràn oorun, àìṣe bẹ́ẹ̀ ìwọ yóò di talákà má ṣe sùn ìwọ yóò sì ní oúnjẹ láti tún fi tọrọ.

13

14“Kò dára, kò dára” ní ẹni tó ra ọjà máa ń wí nígbà tí ó bá kúrò níbẹ̀ tán, yóò máa yangàn bí òun tí ṣe rí i rà sí.

14

15Góòlù wà, iyùn sì wà rẹpẹtẹ ṣùgbọ́n, ahọ́n tí ń sọ ìmọ̀ gan an ni ọ̀ṣọ́ iyebíye.

15

16Gba abọ́ ẹni tí ó ṣe onídùúró fún àlejò; mú un lọ́wọ́ bí ìbúra bí ó bá ṣe é fún obìnrin onírìnkurìn.

16

17Oúnjẹ tí a fi ọ̀nà ẹ̀rú rí máa ń dùn lẹ́nu ènìyàn ṣùgbọ́n, a yọrí sí bi ẹnu tí ó kún fún èèpẹ̀.

17

18Pa ètè rẹ mọ́ nípa wíwá ìmọ̀ràn bí o bá ń jagun, gba ìtọ́ṣọ́nà.

18

19Olófòófó dalẹ̀ àsírí nítorí náà yẹra fún ènìyàn tí ń rojọ́ jù.

19

20Bí ènìyàn kan bá ṣépè fún baba tàbí ìyá rẹ̀, ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ ni a ó pa kú nínú òkùnkùn biribiri.

20

21Ogún tí a kó jọ kíákíá ní ìbẹ̀rẹ̀ kì yóò ní ìbùkún ní ìgbẹ̀yìn gbẹ́yín.

21

22Má ṣe wí pé, “N ó ṣẹ̀ṣan àṣìṣe rẹ yìí fún ọ” Dúró de OLÚWA yóò sì gbà ọ́ là.

22

23OLÚWA kórìíra òdiwọ̀n èké. Òṣùwọ̀n ìrẹ́jẹ kò sì tẹ́ ẹ lọ́rùn.

23

24OLÚWA ni ó ń ṣe olùdarí ìgbésẹ̀ ènìyàn Báwo wá ni òye gbogbo ọ̀nà ènìyàn ṣe le yé ni?

24

25Ìdẹkùn ni fún ènìyàn láti ṣe ìlérí kíákíá nígbà tí ó bá sì yá kí ó máa ro ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wò.

25

26Ọlọgbọ́n ọba tú ènìyàn búburú ká; Ó sì fi òòlọ ìpakà lọ̀ wọ́n.

26

27Àtùpà OLÚWA ń ṣe àwárí ẹ̀mí ènìyàn a máa ṣàwárí ibi ìkọ̀kọ̀ inú

28Ìfẹ́ àti òdodo pa ọba mọ́, nípa ìfẹ́, ìtẹ́ rẹ̀ wà láìléwu.

28

29Ògo ọ̀dọ́mọkùnrin ni agbára wọn jẹ́ ewú orí ni iyì arúgbó.

29

30Ìgbájú ìgbámú àti ìfarapa máa ń mú ibi lọ, pàsán sì máa ń ṣe àfọ̀mọ́ ibi ìkọ̀kọ̀ inú.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide