1Ọkàn ọba ń bẹ lọ́wọ́ OLÚWA; a máa darí rẹ̀ lọ ibi tí ó fẹ́ bí ipa omi.
2Gbogbo ọ̀nà ènìyàn dàbí i pé ó dára lójú rẹ̀ ṣùgbọ́n, OLÚWA ló ń díwọ̀n ọkàn.
2
3Ṣíṣe ohun tí ó dára tí ó sì tọ̀nà ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà sí OLÚWA ju ẹbọ lọ.
3
4Ojú tí ó gbéga àti ọkàn ìgbéraga, ìmọ́lẹ̀ àwọn ènìyàn búburú, ẹ̀ṣẹ̀ ni!
4
5Ètè àwọn olóye já sí èrè bí ìkánjú ṣe máa ń fa òsì kíákíá.
5
6Ìṣúra tí a kójọ nípaṣẹ̀ ahọ́n tí ń parọ́ jẹ́ ìrì lásán àti ìkẹkùn ikú.
6
7Ìwà ipá àwọn ènìyàn búburú yóò wọ́ wọn lọ, nítorí wọ́n kọ̀ láti ṣe ohun tí ó tọ́.
7
8Ọ̀nà ẹlẹ́ṣẹ̀ kún fún ìwà ẹ̀ṣẹ̀ ṣùgbọ́n iṣẹ́ onínú funfun jẹ́ títọ́.
8
9Ó sàn láti máa gbé ní kọ̀rọ̀ orí òrùlé ju láti ṣe àjọpín ilé pẹ̀lú aya oníjà.
9
10Ènìyàn búburú ń fẹ́ ibi aládùúgbò rẹ̀ kì í rí àánú kankan gbà lọ́dọ̀ rẹ̀.
10
11Nígbà tí a bá ń fìyà jẹ ẹlẹ́gàn, òpè a máa kọ́gbọ́n.
11
12Olódodo ṣàkíyèsí ilé ènìyàn búburú ó sì mú ènìyàn búburú wá sí ìparun.
13Ẹnikẹ́ni tí ó bá ti di etí rẹ̀ sí igbe olùpọ́njú, òun tìkárarẹ̀ yóò ké pẹ̀lú; ṣùgbọ́n a kì yóò gbọ́.
13
14Ọ̀rẹ́ ìkọ̀kọ̀, mú ìbínú kúrò: àti owó-àbẹ̀tẹ́lẹ̀ láti ibi ìkọ̀kọ̀ wá, dẹ́kun ìbínú líle.
14
15Ayọ̀ ni fún olódodo láti ṣe ìdájọ́: ṣùgbọ́n ìparun ni fún àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.
15
16Ẹni tí ó bá yà kúrò ní ọ̀nà òye, yóò máa gbé inú ìjọ àwọn òkú.
16
17Ẹni tí ó bá fẹ́ afẹ́, yóò di talákà: ẹni tí ó fẹ́ ọtí-wáìnì pẹ̀lú òróró kò le lọ́rọ̀.
17
18Ènìyàn búburú ni yóò ṣe owó-ìràpadà fún olódodo, àti olùrékọjá fún ẹni dídúró-ṣinṣin.
18
19Ó sàn láti jókòó ní ihà ju pẹ̀lú oníjà obìnrin àti òṣónú lọ.
19
20Ìṣúra iyebíye àti òróró wà ní ibùgbé ọlọ́gbọ́n; ṣùgbọ́n ènìyàn aṣiwèrè (òmùgọ̀) jẹ ẹ́ run.
20
21Ẹni tí ó bá tẹ̀lé òdodo àti àánú yóò rí ìyè, òdodo, àti ọlá.
21
22Ọlọ́gbọ́n gòkè odi ìlú àwọn alágbára, ó sì bi ibi-gíga agbára ìgbẹ́kẹ̀lé wọn ṣubú.
22
23Ẹnikẹ́ni tí ó bá pa ẹnu àti ahọ́n rẹ̀ mọ́, ó pa ọkàn rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ìyọnu.
23
24Agbéraga àti alágídí ènìyàan ń gan orúkọ ara rẹ̀ nítorí ó ń hùwà nínú ìwà ìgbéraga rẹ̀, tí ń hùwà nínú àdábọwọ́ ìgbéraga.
24
25Ẹlẹ́rìí èké yóò ṣègbé, àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ yóò parun láé; nítorí tí ọwọ́ rẹ̀ kọ iṣẹ́ ṣíṣe.
25
26Ó ń fi ìlara ṣojúkòkòrò ní gbogbo ọjọ́: ṣùgbọ́n olódodo a máa fi fún ni kì í sì í dáwọ́ dúró.
26
27Ẹbọ ènìyàn búburú, ìríra ni: mélòómélòó ni nígbà tí ó mú un wá pẹ̀lú èrò ìwà-ibi?
27
28Ẹlẹ́rìí èké yóò ṣègbé: ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ ẹni tí ó gbọ́, yóò dúró.
28
29Ènìyàn búburú mú ojú ara rẹ̀ le: ṣùgbọ́n ẹni ìdúró-ṣinṣin ni ó ń mú ọ̀nà rẹ̀ tọ́.
29
30Kò sí ọgbọ́n, kò sí ìmòye, tàbí ìmọ̀ràn tí ó le mókè níwájú OLÚWA.
30
31A ń múra ẹṣin sílẹ̀ de ọjọ́ ogun: ṣùgbọ́n ìṣẹ́gun jẹ́ ti OLÚWA.