Ìwé Òwe 22:1-29 BYB2014 - Bible AI

1Yíyan orúkọ rere ṣàn ju púpọ̀ ọrọ̀ lọ, àti ojúrere dára ju fàdákà àti wúrà lọ.

2Ọlọ́rọ̀ àti tálákà péjọ pọ̀: OLÚWA ni ẹlẹ́dàá gbogbo wọn.

2

3Ọlọ́gbọ́n ènìyàn ti rí ibi tẹ́lẹ̀, ó ṣé ara rẹ̀ mọ́: ṣùgbọ́n àwọn òpè tẹ̀síwájú, a sì jẹ wọ́n níyà.

3

4Èrè ìrẹ̀lẹ̀ àti ìbẹ̀rù OLÚWA ni ọrọ̀ ọlá, àti ìyè.

4

5Ègún àti ìdẹkun ń bẹ ní ọ̀nà aláyídáyidà: ẹni tí ó bá pa ọkàn rẹ̀ mọ́ yóò jìnnà sí wọn.

5

6Tọ́ ọmọdé ní ọ̀nà tí yóò tọ̀: nígbà tí ó bá dàgbà, kì yóò kúrò nínú rẹ̀.

6

7Ọlọ́rọ̀ ṣe olórí olùpọ́njú, ajigbésè sì ṣe ìránṣẹ́ fún ẹni tí a jẹ ní gbèsè.

7

8ⓐ Ẹni tí ó bá fúnrúgbìn ẹ̀ṣẹ̀, yóò ká aṣán: ọ̀pá ìbínú rẹ̀ yóò kùnà.

8

9Ẹni tí ó ní ojú àánú ni a ó bùkún fún; nítorí tí ó fi nínú oúnjẹ rẹ̀ fún olùpọ́njú.

9

10Lé ẹlẹ́gàn sí ìta, ìjà yóò sì jáde; nítòótọ́ ìjà àti ẹ̀gàn yóò dẹ́kun.

10

11Ẹni tí ó fẹ́ ìwà-funfun ti àyà, tí ó sì ń sọ̀rọ̀ iyì jáde, ọba yóò ṣe ọ̀rẹ́ rẹ̀.

11

12Ojú OLÚWA pa ìmọ̀ mọ́, ó sì yí ọ̀rọ̀ olùrékọjá pò.

12

13Ọ̀lẹ wí pé, “Kìnnìún ń bẹ lóde! Ó pa mí ní ìgboro!”

13

14Ẹnu àwọn Àṣẹ́wó obìnrín, ihò jínjìn ni; ẹni tí a ń bínú sí láti ọ̀dọ̀ OLÚWA wá ni yóò ṣubú sínú rẹ̀.

14

15Àyà ọmọdé ni ìwà-wèrè dì sí; ṣùgbọ́n pàṣán ìtọ́ni ni yóò lé e jìnnà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.

15

16Ẹni tó ń ni talákà lára láti ní ọrọ̀, tí ó sì ń ta ọlọ́rọ̀ lọ́rẹ, yóò di aláìní bí ó ti wù kó rí. Gbọ́ ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n ènìyàn.

17Dẹtí rẹ sílẹ̀, kí o gbọ́ ọ̀rọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n, kí o sì fi àyà rẹ sí ẹ̀kọ́ mi.

18Nítorí ohun dídùn ni bí ìwọ bá pa wọ́n mọ́ ní inú rẹ; nígbà tí a sì pèṣè wọn tán ní ètè rẹ.

19Kí ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ lè wà níti OLÚWA, èmi fi hàn ọ́ lónìí, àní fún ọ.

20Èmi kò ha ti kọ̀wé ohun dáradára sí ọ níti ìmọ̀ràn àti níti ẹ̀kọ́,

21Kí ó lè mú ọ mọ dídájú ọ̀rọ̀ òtítọ́; kí ìwọ le máa fi ìdáhùn òtítọ́ fún àwọn tí ó rán ọ?

21

22Má ṣe ja talákà ní olè, nítorí tí ó jẹ́ talákà: bẹ́ẹ̀ ni kí o má sì ṣe ni olùpọ́njú lára ní ibodè:

23Nítorí OLÚWA yóò gbéjà wọn, yóò sì gba ọkàn àwọn tí ń gba tiwọn náà.

23

24Má ṣe bá oníbìínu ènìyàn ṣe ọ̀rẹ́; má sì ṣe bá ọkùnrin onínú-fùfù rìn.

25Kí ìwọ má ba à kọ́ ìwà rẹ̀, ìwọ a sì gba ìkẹ́kùn fún ara rẹ.

25

26Má ṣe wà nínú àwọn tí ń ṣe ìgbọ̀wọ́, tàbí nínú àwọn tí ó dúró fún gbèsè.

27Bí ìwọ kò bá ní nǹkan tí ìwọ ó fi ṣan, nítorí kín ni yóò ṣe gba ẹní rẹ kúrò lábẹ́ rẹ?

27

28Má ṣe yẹ ààlà ilẹ ìgbàanì, tí àwọn baba rẹ ti pa.

28

29Ìwọ ha rí ènìyàn tí ó ń fi ìmẹ́lẹ́ ṣe iṣẹ́ rẹ̀? Òun yóò dúró níwájú àwọn ọba; òun kì yóò dúró níwájú àwọn ènìyàn lásán.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide