Ìwé Òwe 24:1-34 BYB2014 - Bible AI

1Má ṣe ṣe ìlara àwọn ènìyàn búburú má ṣe jẹ́ kí àwùjọ wọn wù ọ́;

2Nítorí ọkàn wọn ń gbérò ohun búburú, ètè wọn sì ń sọ̀rọ̀ nípa dídá rúgúdù sílẹ̀.

2

3Nípa ọgbọ́n ni ilé di kíkọ́ nípa òye sì ni ó ti fìdí múlẹ̀;

4Nípa ìmọ̀ ni àwọn yàrá rẹ̀ kún pẹ̀lú àwọn ohun ọ̀ṣọ́ tí ó lẹ́wà tí ó sì ṣọ̀wọ́n.

4

5Ọlọ́gbọ́n ènìyàn ní agbára púpọ̀, ènìyàn tí ó ní ìmọ̀ sì ń ní agbára síi

6Láti jagun, ó nílò ìtọ́sọ́nà: nínú ìsẹ́gún ni ọ̀pọ̀ onígbìmọ̀.

6

7Ọgbọ́n ga ju fún aṣiwèrè àti gbọ̀ngàn ìlú níbi ibodè kò ní ohun tí yóò wí.

7

8Ẹni tí ń pète ibi ni a ó mọ̀ bí ènìyàn ibi.

9Ète òmùgọ̀ ènìyàn jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀, àwọn ènìyàn sì kórìíra ẹlẹ́gàn.

9

10Bí ìwọ bá dákú lásìkò ìdààmú báwo ni agbára rẹ ha ti kéré tó!

11Gba àwọn tí a ń wọ́ lọ síbi ikú là; fa àwọn tó ń ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n lọ síbi ìparun padà.

12Bí ìwọ bá wí pé, “Ṣùgbọ́n a kò mọ nǹkankan nípa èyí,” ǹjẹ́ ẹni tí ń díwọ̀n ọkàn kò kíyèsíi? Ǹjẹ́ ẹni tí ń ṣọ́ ẹ̀mí rẹ kò mọ̀ ọ́? Ǹjẹ́ kò ní san án fún ẹnìkọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó ti ṣe?

12

13Jẹ oyin, ìwọ ọmọ mi, nítorí tí ó dára, oyin láti inú afárá oyin dùn lẹ́nu.

14Mọ̀ pẹ̀lú pé ọgbọ́n pẹ̀lú dùn fún ọkàn rẹ bí ìwọ bá rí i ìrètí ọjọ́ iwájú wà fún ọ ìrètí rẹ kì yóò sì já sófo.

14

15Má ṣe ba ní ibùba bí i arúfin dé ilé Olódodo, má ṣe kó ibùgbé è rẹ̀ lọ;

16Nítorí bí olódodo ènìyàn bá tilẹ̀ ṣubú ní ìgbà méje, yóò tún padà dìde ṣáá ni, ṣùgbọ́n ìdàámú yóò fa ènìyàn búburú lulẹ̀.

16

17Má ṣe yọ̀ nígbà tí ọ̀tá rẹ bá ṣubú; nígbà tí ó bá kọsẹ̀, má ṣe jẹ́ kí ọkàn rẹ kí ó yọ̀

18àìṣe bẹ́ẹ̀ OLÚWA yóò rí i yóò sì bínú yóò sì yí ìbínú rẹ̀ padà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.

18

19Má ṣe fòyà nítorí àwọn ènìyàn ibi tàbí jowú àwọn ènìyàn búburú,

20nítorí ẹni ibi kò ní ìrètí ọjọ́ iwájú a ó sì pa fìtílà àwọn ènìyàn búburú kú.

20

21Bẹ̀rù OLÚWA àti ọba, ọmọ mi, má sì ṣe dara pọ̀ pẹ̀lú àwọn olórí kunkun

22nítorí àwọn méjèèjì yóò rán ìparun òjijì sórí wọn, ta ni ó sì mọ irú ìyọnu tí wọ́n lè mú wá?

23Àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú tún jẹ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́gbọ́n láti ṣe ojúṣàájú níbi ìdájọ́ kò dára rárá:

24Ẹnikẹ́ni tí ó wí fún ẹlẹ́bi pé, “Ìwọ lo jàre” àwọn ènìyàn yóò ṣẹ́ èpè fún un àwọn orílẹ̀ èdè yóò sì kọ̀ ọ́.

25Ṣùgbọ́n yóò dára fún àwọn tí ń dá ẹlẹ́bi lẹ́bi, ọ̀pọ̀ ìbùkún yóò sì wá sórí wọn.

25

26Ìdáhùn òtítọ́ ó dàbí ìfẹnu-koni-ní-ẹnu.

26

27Parí gbogbo iṣẹ́ ajé rẹ sì rí i pé oko rẹ ti ṣe dáradára; lẹ́yìn náà kọ́ ilé rẹ.

27

28Má ṣe rojọ́ èké mọ́ aládúgbò rẹ láìnídìí, tàbí kí o fi ètè rẹ tannijẹ.

29Má ṣe wí pé, “Mà á ṣe é fún un gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe fún mi; Èmi yóò san ohun tí ó ṣe fún mi padà fún un.”

29

30Mo kọjá níbi oko ọ̀lẹ, mo kọjá níbi oko aláìgbọ́n ènìyàn;

31ẹ̀gún ti hù ní ibi gbogbo, koríko ti gba gbogbo oko náà

32Mo fi ọkàn mi sí nǹkan tí mo kíyèsí mo sì kẹ́kọ̀ọ́ lára ohun tí mo rí;

33oorun díẹ̀, òògbé díẹ̀, ìkáwọ́ gbera díẹ̀ láti sinmi

34Òsì yóò sì dé bá ọ bí adigunjalè àti àìní bí olè.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide