Ìwé Òwe 25:1-28 BYB2014 - Bible AI

1Wọ̀nyí ni àwọn òwé mìíràn tí Sólómónì pa, tí àwọn ọkùnrin Hẹsikáyà ọba Júdà dà kọ.

2Ògo OLÚWA ní láti fi ọ̀rọ̀ kan pamọ́; láti rí ìdí ọ̀rọ̀ kan ni ògo àwọn ọba.

3Bí ọ̀run ṣe ga tó tí ayé sì jìn bẹ́ẹ̀ ni ó ṣòro láti mọ èrò ọkàn ọba.

3

4Mú ìdàrọ́ kúrò lára fàdákà ohun èlò yóò sì jáde fún alágbẹ̀dẹ fàdákà

5mú ènìyàn búburú kúrò níwájú ọba a ó sì fìdí ìtẹ́ rẹ múlẹ̀ nípaṣẹ̀ òdodo.

5

6Má ṣe gbé ara rẹ ga níwájú ọba, má sì ṣe jìjàdù ààyè láàrin àwọn ènìyàn pàtàkì

7Ó sàn kí ó wí fún ọ pé, “Gòkè wá síhìn ín” ju wí pé kí ó dójú tì ọ́ níwájú ènìyàn pàtàkì.

7

8Ohun tí o ti fi ojú ara rẹ rí má ṣe kánjú gbé e lọ sílé ẹjọ́ nítorí kí ni ìwọ yóò ṣe ní ìgbẹ̀yìn bí aládùúgbò rẹ bá dójú tì ọ́?

8

9Bí o bá ń ṣe àwíjàre rẹ níwájú aládùúgbò rẹ, má ṣe tú àsírí tí ẹlòmíràn ní lọ́dọ̀ rẹ,

10àìṣe bẹ́ẹ̀ ẹni tí ó gbọ́ ọ le dójú tì ọ́ orúkọ burúkú tí ìwọ bá sì gba kì yóò tán láéláé.

10

11Ọ̀rọ̀ tí a sọ ní àkókò tí ó yẹ ó dàbí èṣo wúrà nínú àpẹẹrẹ fàdákà.

12Bí i yẹtí wúrà tàbí ohun ọ̀ṣọ́ ti wúrà dáradára ni ìbáwí ọlọ́gbọ́n fún etí tí ó bá fetísílẹ̀.

12

13Bí títutù òjò yìnyín ní àsíkò ìkórè ni ìránṣẹ́ tí ó jẹ́ olóòtọ́ sí àwọn tí ó rán an ó ń tu ọ̀gá rẹ̀ nínú.

14Bí ojú ṣíṣú àti afẹ́fẹ́ láì sí òjò ni ènìyàn tí ń yangàn nípa ẹ̀bùn tí kò fún ni.

14

15Nípa ṣùúrù a lè yí ọba lọ́kàn padà ahọ́n tí ń sọ̀rọ̀ rírọ̀ sí egungun.

15

16Bí ìwọ bá rí oyin, jẹ ẹ́ ní ìwọ̀nba bí o bá jẹ ẹ́ jù, ìwọ yóò sì bì í.

17Má ṣe máa lọ sí ilé aládùúgbò rẹ nígbà gbogbo tàbí kí ó máa lọ ṣíbẹ̀ lálọ jù, yóò sì kórìíra rẹ.

17

18Bí àdá, idà tàbí ọ̀kọ̀ tí ó mú ni ènìyàn tí ó jẹ́rìí èké lòdì sí aládùúgbò rẹ̀.

19Bí eyín tí ó bàjẹ́ tàbí ẹṣẹ̀ tí ó rọ ni ìgbẹ́kẹ̀lé lórí aláìṣòótọ́ ní àsìkò ìdàámú.

20Bí ẹni tí ó bọ́ra kalẹ̀ ní ọjọ́ tí òtútù mú, tàbí iyọ̀ tí a fi ra ojú egbò ọgbẹ́ tàbí bí ọtí kíkan tí a dà sórí sódà ní ẹni tí ń kọ orin sí ọkàn tí ó bàjẹ́.

20

21ⓐ Bí ebi bá ń pa ọ̀tá rẹ, fún un ní oúnjẹ jẹ; bí òrùngbẹ bá ń gbẹ ẹ́, fún un ní omi mú.

22Nípa ṣíṣe báyìí, ìwọ yóò wa ẹ̀yín iná lé e lórí OLÚWA yóò sì san ọẹ̀san rẹ̀ fún ọ.

22

23Bí afẹ́fẹ́ gúṣù ti í mú òjò wá, bí ahọ́n tí ń sọ̀rọ̀ ẹ̀yìn ṣe ń mú ojú ìbínú wá.

23

24Ó sàn láti gbé ní ibi igun kan lórí òrùlé ju láti bá aya oníjà gbé ilé pọ̀.

24

25Bí omi tútù sí ẹni tí òrùngbẹ ń gbẹ ni ìròyìn ayọ̀ láti ọ̀nà jíjìn.

26Bí ìsun tí ó di àbàtà tàbí kanga tí omi rẹ̀ bàjẹ́ ni olódodo tí ó fi àyè gba ènìyàn búburú.

26

27Kò dára láti jẹ oyin àjẹjù, bẹ́ẹ̀ ni kò pọ́nni lé láti máa wá ọlá fún ara ẹni.

27

28Bí ìlú tí odi rẹ̀ ti wó lulẹ̀ ni ènìyàn tí kò le kó ara rẹ̀ ní ìjánu.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide