Ìwé Òwe 27:1-27 BYB2014 - Bible AI

1Má ṣe yangàn nítorí ọ̀la nítorí o kò mọ ohun tí ọjọ́ kan le è mú wáyé.

2Jẹ́ kí ẹlòmíràn yìn ọ́ dípò ẹnu ara rẹ àní ẹlòmíràn, kì í ṣe ètè ìwọ fúnra rẹ.

2

3Òkúta wúwo, erùpẹ̀ sì wúwo ṣùgbọ́n ìmúbínú un aṣiwèrè wúwo ju méjèèjì lọ.

3

4Ìbínú ni ìkà, ìrunú sì burú púpọ̀ ṣùgbọ́n tani ó le è dúró níwájú owú?

4

5Ìbániwí gbangba sàn ju ìfẹ́ ìkọ̀kọ̀ lọ.

5

6Ọgbẹ́ láti ọ̀dọ̀ ọ̀rẹ́ ṣe é gbẹ́kẹ̀lé ṣùgbọ́n ọ̀tá máa ń fẹnu-koni-lẹ́nu púpọ̀.

6

7Kódà oyin kò dùn lẹ́nu ẹni tí ó ti yó ṣùgbọ́n òróòro gan an dùn lẹ́nu ẹni tí ebi ń pa.

7

8Bí ẹyẹ tí ó ṣáko lọ kúrò níbi ìtẹ́ rẹ̀ ni ènìyàn tí ó ṣáko lọ kúrò ní ilé rẹ̀.

8

9Ìpara olóòórùn dídùn àti tùràrí ń mú ayọ̀ wá sínú ọkàn bẹ́ẹ̀ ni inú dídùn láti ọ̀dọ̀ ọ̀rẹ́ ń wá láti inú ìmọ̀ràn tí ó Ṣàkóso.

9

10Má ṣe kọ ọ̀rẹ́ rẹ àti ọ̀rẹ́ baba rẹ sílẹ̀, má sì ṣe lọ sílé arákùnrin rẹ nígbà tí ìdàámú dé bá ọ ó sàn kí o jẹ́ aládúúgbò tí ó súnmọ́ ni ju arákùnrin tí ó jìnnà síni.

10

11Gbọ́n, ọmọ mi, kí o sì mú ayọ̀ wá sínú ọkàn mi nígbà náà ni mo le dá gbogbo ẹni tí ó bá kẹ́gàn mi.

11

12Ọlọ́gbọ́n rí ewu, ó sì fara pamọ́ ṣùgbọ́n aláìgbọ́n rí kàkàkí ó dúró ó tẹ̀ṣíwájú, ó sì jìyà rẹ̀.

12

13Gba aṣọ ẹni tí ó ṣe onídùúró fún àjòjì fi ṣe ẹ̀rí ìdúró bí o bá ṣe onídùúró fún obìnrin oní ìṣekúṣe.

13

14Bí ènìyàn kan ń kígbe e ṣúre fún aládùúgbò rẹ ní òwúrọ̀ a ó kà á sí bí èpè.

14

15Àyà tí ó máa ń jà dàbí ọ̀wààrà òjò ní ọjọ́ tí òjò ń rọ̀;

16dídá a lẹ́kun dàbí ìgbà tí ènìyàn ń dá afẹ́fẹ́ lẹ́kun tàbí bí ẹni tí ó gbá òróró.

16

17Bí irin tí ń pọ́n irin mú bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn kan ń pọ́n ẹlòmíràn mú.

17

18Ẹni tí ó tọ́jú igi ọ̀pọ̀tọ́ yóò jẹ èṣo rẹ̀ ẹni tí ó sì fojú tó ọ̀gá rẹ̀ yóò gba ọlá.

18

19Bí omi tí ń ṣe àfihàn ojú, nígbà tí a bá wò ó bẹ́ẹ̀ ni ọkàn ènìyàn ń ṣe àfihàn ènìyàn.

19

20Kò tẹ́ ikú àti ìparun lọ́rùn rí bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni ojú ènìyàn kò rí ìtẹ́lọ́rùn rí.

20

21Iná fún fàdákà iná ìlérú fún wúrà, ṣùgbọ́n a ń dán ènìyàn wò nípa ìyìn tí ó ń gbà.

21

22Bí a tilẹ̀ gún aláìgbọ́n nínú odó, fi ọmọ odó gún-un bí èlùbọ́ ìwọ kì yóò le è yọ ìwà òmùgọ̀ rẹ̀ kúrò ní inú rẹ̀.

22

23Rí i dájú pé o mọ ipò tí àwọn agbo àgùntàn rẹ wà bojú tó àwọn agbo màlúù rẹ dáradára;

24nítorí ọrọ̀ kì í pẹ́ lọ títí adé kì í sì í wà lórí títí láéláé.

24

25Nígbà tí a bá kó koríko jọ láti orí òkè

26àwọn àgùntàn yóò pèṣè aṣọ fún ọ, àti ewúrẹ́ yóò pèṣè owó oko.

26

27Ìwọ yóò ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ mílíkì ewúrẹ́ láti bọ́ ọ àti ìdílé rẹ àti láti tọ́jú àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide