1Ènìyàn búburú ń sá bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹnìkan kò lé e ṣùgbọ́n olódodo láyà bí i kìnnìún.
2Nígbà tí orílẹ̀ èdè bá ní orí kunkun, àwọn ọba rẹ̀ a máa pọ̀ ṣùgbọ́n olóye àti onímọ̀ a máa pa òfin mọ́
2
3ọba tí ó ni àwọn talákà lára dàbí àgbàrá òjò tí ó ń gbá gbogbo ẹ̀gbìn lọ.
3
4Àwọn tí ó kọ òfin sílẹ̀ a máa gbóríyìn fún ènìyàn búburú ṣùgbọ́n àwọn tí ó pa òfin mọ́ kọjú ìjà sí ènìyàn búburú.
4
5Òye ìdájọ́ òdodo kò yé àwọn ẹni ibi ṣùgbọ́n ó yé àwọn tí ń wá OLÚWA dáradára.
5
6Ó sàn láti jẹ́ talákà tí ìrìn rẹ̀ jẹ́ aláìlábùkù ju ọlọ́rọ̀ tí ọ̀nà rẹ̀ rí pálapàla.
6
7Ẹni tí ó pa òfin mọ́ jẹ́ olóye ọmọ ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá jẹgúdújẹrá kẹ́gbẹ́ dójú ti baba rẹ̀.
7
8Ẹni tí ó mú ọrọ̀ rẹ̀ di púpọ̀ nípa èrè àjẹjù ń kó o jọ fún ẹlòmìíràn, tí yóò ní àánú àwọn talákà.
8
9Bí ẹnikẹ́ni bá kọ etí ikún sí òfin, kódà àdúrà rẹ̀ jẹ́ ìríra.
9
10Ẹni tí ó mú olódodo rìn ọ̀nà búburú yóò bọ́ sínú pàkúté ara rẹ̀ ṣùgbọ́n aláìlẹ́gàn yóò gba ogún rere.
10
11Ọlọ́rọ̀ ènìyàn le è gbọ́n lójú ara rẹ̀ ṣùgbọ́n talákà tí ó ní òye rí ìdí, rẹ̀.
11
12Nígbà tí olódodo ń lékè ariwo ayọ̀ ta; ṣùgbọ́n nígbà tí ènìyàn búburú gorí òye, àwọn ènìyàn a na pápá bora.
12
13Ẹni tí ó bo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀ kì í ṣe rere, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá jẹ́wọ́ tí ó sì kọ̀ wọ́n sílẹ̀ máa ń rí àánú gbà.
13
14Ìbùkún ni fún ènìyàn náà tí ó bẹ̀rù OLÚWA nígbà gbogbo ṣùgbọ́n ẹni tí ó ṣé ọkàn rẹ̀ le bọ́ sínú wàhálà.
14
15Bí kìnnìún tí ń ké tàbí Béárì tí ń halẹ̀ ni ènìyàn búburú tí ń jọba lórí àwọn aláìlágbára.
15
16Ọba tí ó jẹ gàba lórí ìlú láì gbàmọ̀ràn kò gbọ́n ṣùgbọ́n ẹni tí ó kórìíra èrè ìjẹkújẹ yóò gbádùn ọjọ́ gígùn.
16
17Ẹni tí ọkàn rẹ̀ kò balẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ìpànìyàn yóò máa joró rẹ̀ títí ikú má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ràn án lọ́wọ́.
17
18Ẹni tí ìrìn rẹ̀ kò ní àbùkù wà láìléwu ṣùgbọ́n ẹni tí ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ ayípadà yóò ṣubú lójijì.
18
19Ẹni tí ó bá ro ilẹ̀ rẹ̀ yóò ní oúnjẹ lọ́pọ̀lọpọ̀ ṣùgbọ́n ẹni tí ń lé ohun aṣán yóò kún fún òsì.
19
20Olóòótọ́ ènìyàn yóò rí ìbùkún gbà gan an ṣùgbọ́n ẹni tí ojú ń kán láti di ọlọ́rọ̀ kì yóò lọ, láìjìyà.
20
21Ojúṣááj ú ṣíṣe kò dára ṣíbẹ̀ ènìyàn kan ń ṣẹ̀ nítorí òkèlè oúnjẹ kan.
21
22Ahun ń sáré àti là kò sì funra pé òsì dúró de òun.
22
23Ẹni tí ó bá ènìyàn kan wí yóò rí ojú rere síi nígbẹ̀yìn ju ẹni tí ó ní ètè ẹ̀tàn lọ.
23
24Ẹni tí ó ja baba tàbí ìyá rẹ̀ lólè tí ó sì wí pé “Kì í ṣe ẹ̀ṣẹ̀” irú kan ni òun àti ẹni tí ń panírun.
24
25Ọ̀kanjúà ènìyàn a máa dá ìjà sílẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé OLÚWA yóò gbilẹ̀.
25
26Ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀lé ara rẹ̀ jẹ́ aláìgbọ́n ṣùgbọ́n ẹni tí ń rìn nínú ọgbọ́n wà láìléwu.
26
27Ẹni tí ó ń fifún talákà kì yóò ṣe aláìní ohunkóhun ṣùgbọ́n ẹni tí ó di ojú rẹ̀ sí wọn gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ègún.
27
28Nígbà tí ènìyàn búburú bá dórí ìjọba, àwọn ènìyàn a na pápá bora; ṣùgbọ́n nígbà tí ènìyàn búburú bá ṣègbé, àwọn olódodo ń gbilẹ̀ síi.