1Ẹni tí ó sì ń ṣorí kunkun lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbáwí yóò parun lójijì láìsí àtúnṣe.
2Nígbà tí olódodo bá ń gbilẹ̀, àwọn ènìyàn a yọ̀ nígbà tí ènìyàn búburú ń ṣàkóso, àwọn ènìyàn ń kórìíra.
2
3Ènìyàn tí ó fẹ́ràn ọgbọ́n mú kí baba rẹ̀ láyọ̀ ṣùgbọ́n ẹni ti ń bá aṣẹ́wó kẹ́gbẹ́ ba ọrọ̀ ọ rẹ̀ jẹ́
3
4Nípa ìdájọ́ òdodo ni ọba fi í mú ìlú tòrò nini, ṣùgbọ́n èyí tí ń ṣojúkòkòrò àbẹ̀tẹ́lẹ̀ fà á lulẹ̀.
4
5Ẹnikẹ́ni tí ó bá tan aládúgbò rẹ̀ ó ń dẹ àwọ̀n de ẹsẹ̀ ẹ rẹ̀.
5
6Ẹ̀ṣẹ̀ ènìyàn ibi ni ó jẹ́ ìdẹkùn rẹ̀ ṣùgbọ́n olódodo le è kọrin kí ó sì máa yọ̀.
6
7Olódodo ń ṣaápọn nípa ìdájọ́ òtítọ́ fún àwọn tálákà, ṣùgbọ́n kò sí ohun tí ó kan ènìyàn búburú nínú irú rẹ̀.
7
8Àwọn Ẹlẹ́yà a máa ru ìlú sókè, ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn máa ń mú ìbínú kúrò.
8
9Bí ọlọ́gbọ́n ènìyàn bá lọ sí ilé ẹjọ́ pẹ̀lú aláìgbọ́n aláìgbọ́n a máa bínú a sì máa jà, kò sì ní sí àlàáfíà.
9
10Àwọn tí ó ń tàjẹ̀ sílẹ̀ kòrí ẹni-dídúró-ṣinṣin wọ́n sì ń wá ọ̀nà láti pa olódodo.
10
11Aláìgbọ́n ènìyàn fi gbogbo ẹ̀nú rẹ̀ bínú ṣùgbọ́n ọlọgbọ́n ènìyàn a máa kó ìbínú rẹ̀ ní ìjánu.
11
12Bí olórí bá fetí sí irọ́, gbogbo àwọn ìjòyè rẹ̀ a di ènìyàn búburú lójú rẹ̀.
12
13Tálákà ènìyàn àti aninilára jọ ní àbùdá yìí, OLÚWA jẹ́ kí ojú àwọn méjèèjì máa ríran.
13
14Bí ọba kan bá ń ṣe ìdájọ́ talákà pẹ̀lú òtítọ́ ìtẹ́ ìjọba rẹ yóò fìdí múlẹ̀ nígbà gbogbo.
14
15Ọ̀pá ìbániwí ń fún ni ní ọgbọ́n ṣùgbọ́n ọmọ tí a fi sílẹ̀ fúnra rẹ̀ a dójú ti ìyá rẹ̀.
15
16Nígbà tí ènìyàn búburú ń gbilẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni ẹ̀ṣẹ̀ ń gbilẹ̀ ṣùgbọ́n Olódodo yóò rí ìṣubú wọn.
16
17Bá ọmọ rẹ wí, yóò sì fún ọ ní àlàáfíà yóò sì mú inú dídùn wá sí inú ọkàn rẹ.
17
18Níbi tí kò ti sí ìfihàn, àwọn ènìyàn a gbé ìgbé ayé àìbìkítà. Ṣùgbọ́n ìbùkún ní fún àwọn tí ń pa òfín mọ́.
18
19A kò le fi ọ̀rọ̀ lásán kìlọ̀ fún ìránṣẹ́ bí ó tilẹ̀ yé e, kò ní kọbi-ara-síi.
19
20Njẹ́ ó rí ènìyàn tí ń kánjú sọ̀rọ̀? Ìrètí wà fún aláìgbọ́n jù ú lọ.
20
21Bí ènìyàn kan bá kẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ lákẹ̀ẹ́jù láti kékeré yóò mú ìbànújẹ́ wá ní ìgbẹ̀yìn.
21
22Oníbìínú ènìyàn a ru ìjà sókè, Onínú-fùfù ènìyàn a sì máa dá ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀.
22
23Ìgbéraga ènìyàn a máa sọ ọ́ di ẹni ilẹ̀ ṣùgbọ́n onírẹ̀lẹ̀ ènìyàn a máa gba iyì kún iyì.
23
24Ẹni tí ó ń ran olè lọ́wọ́ gan an ni ọ̀ta rẹ̀ O ń gbọ́ epe olóhun kò sì le è fọhùn.
24
25Ìbẹ̀rù ènìyàn kan yóò sì di ìdẹkùn ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bẹ̀rù OLÚWA wà láìléwu.
25
26Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ń wá ojúrere alákòóṣo, ṣùgbọ́n láti ọdọ OLÚWA ni ènìyàn tí ń gba ìdájọ́ òdodo.
26
27Olódodo kórìíra àwọn aláìsòótọ́: ènìyàn búburú kórìíra olódodo.