Ìwé Òwe 3:1-35 BYB2014 - Bible AI

1Ọmọ mi, má ṣe gbàgbé ẹ̀kọ́ mi. Ṣùgbọ́n pa òfin mi mọ́ sí ọkàn rẹ.

2Nítorí wọn yóò fún ọ ní ọjọ́ gígùn fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún kí ó sì mú ọ̀rọ̀ wá fún ọ.

3Má ṣe jẹ́ kí ìfẹ́ àti òtítọ́ ṣíṣe fi ọ́ sílẹ̀ láéláé so wọ́n mọ́ ọrùn rẹ, kọ wọ́n sí síléètì àyà rẹ.

4ⓐ Nígbà náà ni ìwọ yóò rí ojú rere àti orúkọ rere ní ojú Ọlọ́run àti lójú ènìyàn.

4

5Gbẹ́kẹ̀lé OLÚWA pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ má ṣe sinmi lé òye ara à rẹ;

6Jẹ́wọ́ rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà rẹ yóò sì ṣe àkóso ọ̀nà rẹ.

6

7ⓑ Má ṣe jẹ́ ọlọ́gbọ́n lójú ara à rẹ bẹ̀rù OLÚWA kí o sì kórìíra ibi.

8Èyí yóò mú ìlera fún ara à rẹ àti okun fún àwọn egungun rẹ.

8

9Fi ọrọ̀ rẹ bọ̀wọ̀ fún OLÚWA, pẹ̀lú àkọ́so oko ò rẹ

10Nígbà náà ni àká rẹ yóò kún àkúnya àgbá rẹ yóò kún à kún wọ́ sílẹ̀ fún wáìnì tuntun.

10

11ⓒ Ọmọ mi, má ṣe kẹ́gàn ìbáwí OLÚWA má si ṣe bínú nígbà tí ó bá ń bá ọ wí,

12Nítorí OLÚWA a máa bá àwọn tí ó fẹ́ràn wí bí baba ti í bá ọmọ tí ó bá nínú dídùn sí wí.

12

13Ìbùkún ni fún ẹni tí ó ní ìmọ̀, ẹni tí ó tún ní òye síi

14Nítorí ó ṣe èrè ju fàdákà lọ ó sì ní èrè lórí ju wúrà lọ.

15Ó ṣe iyebíye ju iyùn lọ; kò sí ohunkohun tí a lè fi wé e nínú ohun gbogbo tí ìwọ fẹ́.

16Ẹ̀mí gígùn ń bẹ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀; ní ọwọ́ òsì rẹ̀ sì ni ọrọ̀ àti ọlá.

17Àwọn ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ ọ̀nà ìtura, òpópónà rẹ̀ sì jẹ́ ti àlàáfíà.

18Igi ìyè ni ó jẹ́ fún gbogbo ẹni tí ó bá gbàá; àwọn tí ó bá sì dìí mú yóò rí ìbùkún gbà.

18

19Nípa ọgbọ́n, OLÚWA fi ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé sọlẹ̀; nípa òye, ó fi àwọn ọ̀run sí ipòo wọn;

20Nípa ìmọ̀ rẹ̀ ó pín ibú omi ní ìyà, àwọ̀sánmọ̀ sì ń sẹ ìrì.

20

21Ọmọ mi pa ìdájọ́ tí ó yè kooro mọ́ àti ìmọ̀yàtọ̀, má jẹ́ kí wọn lọ kúrò ní ibi tí ojú rẹ ti le tó wọn

22wọn yóò jẹ́ ìyè fún ọ àti ẹ̀ṣọ́ fún ọrùn rẹ

23Nígbà náà ni ìwọ yóò bá ọ̀nà rẹ lọ ní àìṣéwu, ìwọ kì yóò sì kọsẹ̀;

24Nígbà tí ìwọ bá dùbúlẹ̀, ìwọ kì yóò bẹ̀rù nígbà tí ìwọ bá dùbúlẹ̀, oorun rẹ yóò jẹ́ oorun ayọ̀

25má ṣe bẹ̀rù ìdàámú òjijì tàbí ti ìparun tí ó ń dé bá àwọn ènìyàn búburú

26Nítorí OLÚWA yóò jẹ́ ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ kì yóò sì jẹ́ kí ẹsẹ̀ rẹ bọ́ sínú pàkúté.

26

27Má ṣe fa ọwọ́ ire sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ àwọn tí ó tọ́ sí, nígbà tí ó bá wà ní ìkápá rẹ láti ṣe ohun kan.

28Má ṣe wí fún aládùúgbò rẹ pé, “Padà wá nígbà tó ṣe díẹ̀; ó fún ọ lọ́lá” nígbà tí o ní i pẹ̀lú rẹ nísinsin yìí.

28

29Má ṣe pète ohun búburú fún aládùúgbò rẹ, ti o gbé nítòsí rẹ, tí ó sì fọkàn tán ọ.

30Má ṣe fẹ̀ṣùn kan ènìyàn láì-ní-ìdí nígbà tí kò ṣe ọ́ ní ibi kankan rárá.

30

31Má ṣe ṣe ìlara ènìyàn jàgídíjàgan tàbí kí o yàn láti rìn ní ọ̀nà rẹ̀,

32Nítorí OLÚWA kórìíra ènìyàn aláyìídáyidà ṣùgbọ́n a máa fọkàn tán ẹni dídúró ṣinṣin.

32

33Ègún OLÚWA ń bẹ lórí ilé ènìyàn búburú, ṣùgbọ́n ó bùkún fún ilé olódodo

34ⓓ Ó fi àwọn oníyẹ̀yẹ́ ṣe yẹ̀yẹ́ Ṣùgbọ́n ó fi oore ọ̀fẹ́ fún onírẹ̀lẹ̀

35ọlọ́gbọ́n jogún iyì Ṣùgbọ́n àwọn aláìgbọ́n ni ó dójú tì.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
/div>