Ìwé Òwe 31:1-31 BYB2014 - Bible AI

1Àwọn ọ̀rọ̀ ti Lémúélì ọ̀rọ̀ ìṣọtẹ́lẹ̀, tí ó jẹ́ pé mọ̀mọ́ rẹ̀ ló kọ ọ́:

2“Ìwọ ọmọ mi, ìwọ ọmọ inú mi, ìwọ ọmọ ẹ̀jẹ̀ mi.

3Má ṣe lo agbára rẹ lórí obìnrin, okun rẹ lórí àwọn tí ó pa àwọn ọba run.

3

4“Kì í ṣe fún àwọn ọba, ìwọ Lémúélì kì í ṣe fún ọba láti mu ọtí wáìnì kì í ṣe fún alákòóso láti máa wá ọtí líle

5Kí wọn má ba à mu ọtí yó kí wọn sì gbàgbé ohun tí òfin wí kí wọn sì fi ẹ̀tọ́ àwọn tí ara ń ni dù wọ́n

6Fi ọtí líle fún àwọn tí ń ṣègbé wáìnì fún àwọn tí ó wà nínú ìrora;

7Jẹ́ kí wọn mu ọtí kí wọn sì gbàgbé òsì wọn kí wọn má sì rántí òsì wọn mọ́.

7

8“Ṣọ̀rọ̀ lórúkọ àwọn tí kò le sọ̀rọ̀ fún ra wọn fún ẹ̀tọ́ àwọn ẹni tí ń parun

9sọ̀rọ̀ kí o sì ṣe ìdájọ́ àìṣègbè jà fún ẹ̀tọ́ àwọn tálákà àti aláìní.”

9

10Ta ni ó le rí aya oníwà rere? Ó níye lórí ju iyùn lọ

11ọkọ rẹ̀ ní ìgbẹ́kẹ̀lẹ́ púpọ̀ nínú rẹ̀ kò sì sí ìwà rere tí kò pé lọ́wọ́ rẹ̀.

12Ire ní ó ń ṣe fún un, kì í ṣe ibi ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.

13Ó sa aṣọ irun àgùtàn olówùú àti ọ̀gbọ̀ Ó sì ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ìyárí.

14Ó dàbí ọkọ̀ ojú omi tí àwọn oníṣòwò; ó ń gbé oúnjẹ rẹ̀ wá láti ọ̀nà jínjìn

15Ó dìde nígbà tí òkùnkùn sì kùn; ó ṣe oúnjẹ fún ìdílé rẹ̀ àti ìpín oúnjẹ fún àwọn ìránṣẹ́-bìnrin rẹ̀.

16Ó kíyèsí oko kan, ó sì rà á; nínú ohun tí ó ń wọlé fún un ó gbin àjàrà rẹ̀

17Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ tagbáratagbára Apá rẹ̀ le koko fún iṣẹ́

18Ó ríi pé òwò òun pé fìtílà rẹ̀ kì í sìí kú ní òru

19Ní ọwọ́ rẹ̀, ó di kẹ̀kẹ́ òwú mú ó sì na ọwọ́ rẹ̀ di ìrànwú mú

20ó la ọwọ́ rẹ̀ sí àwọn talákà ó sì na ọwọ́ rẹ̀ sí àwọn aláìní.

21Nígbà tí òjò dídì rọ̀, kò bẹ̀rù nítorí ìdílé rẹ̀ nítorí gbogbo wọn ni ó wọ aṣọ tí ó nípọn.

22Ó ṣe aṣọ títẹ́ fún ibùsùn rẹ̀; ẹwu dáradára àti eléṣè é àlùkò ni aṣọ rẹ̀

23A bọ̀wọ̀ fún ọkọ rẹ̀ ní ẹnu ibòde ìlú níbi tí ó ń jókòó láàrin àwọn àgbà ìlú

24Ó ń ṣe àwọn aṣọ dáradára ó sì ń tà wọ́n ó sì ń kó ọjà fún àwọn oníṣòwò

25Agbára àti ọlá ni ó wò ọ́ láṣọ ó le fi ọjọ́ iwájú rẹ́rìn-ín.

26A sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ọgbọ́n ìkọ́ni òtítọ́ sì ń bẹ létè e rẹ̀

27Ó ń bojú tó gbogbo ètò ilé rẹ̀ kì í sì í jẹ oúnjẹ ìmẹ́lẹ́

28Àwọn ọmọ rẹ̀ dìde wọ́n sì pè é ní alábùkún ọkọ rẹ̀ pẹ̀lú ń gbóríyìn fún un

29“Ọ̀pọ̀lọpọ̀ òbìnrin ní ń ṣe nǹkan ọlọ́lá ṣùgbọ́n ìwọ ju gbogbo wọn lọ”

30Ojú dáradára a máa tan ni, ẹwà sì jẹ́ asán nítorí obìnrin tí ó bẹ̀rù OLÚWA yẹ kí ó gba oríyìn

31sì fún un ní èrè tí ó tọ́ sí i kí o sì jẹ́ kí iṣẹ́ rẹ̀ fún un ní ìyìn ní ẹnu ibòde ìlú.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide