1Tẹ́tí, Ẹ̀yin ọmọ mi, sí ẹ̀kọ́ baba; fetí sílẹ̀ kí o sì ní òye sí i
2Mo fún ọ ní ẹ̀kọ́ tí ó yè kooro Nítorí náà má ṣe kọ ìkọ́ni mi sílẹ̀
3Nígbà tí mo jẹ́ ọ̀dọ́mọkùnrin ní ilé baba à mí, mo jẹ́ èwe, tí mo sì jẹ́ ọ̀kanṣoṣo lọ́wọ́ ìyá mi
4Ó kọ́ mi ó sì wí pé “Jẹ́ kí àyà rẹ kí ó gba ọ̀rọ̀ mi dúró, pa òfin mí mọ́, kí ìwọ kí ó sì yè.
5Gba ọgbọ́n, gba òye, Má ṣe gbàgbé ọ̀rọ̀ mi tàbí kí o yẹṣẹ̀ kúrò nínú rẹ̀
6Má ṣe kọ ọgbọ́n sílẹ̀, yóò sì dáàbò bò ọ́, fẹ́ràn rẹ̀, yóò sì bojú tó ọ.
7Ọgbọ́n ni ó ga jù; Nítorí náà gba ọgbọ́n. Bí ó tilẹ̀ ná gbogbo ohun tí o ní, gba òye
8Gbé e ga, yóò sì gbé ọ ga dìrọ̀ mọ́ ọn, yóò sì bu iyì fún ọ.
9Yóò fi òdòdó ọ̀ṣọ́ ẹwà sí orí rẹ yóò sì fi adé ẹlẹ́wà fún ọ.”
9
10Tẹ́tí, ọmọ mi, gba ohun tí mo sọ, Ọjọ́ ayé è rẹ yóò sì gùn.
11Mo tọ́ ọ sọ́nà ní ọ̀nà ti ọgbọ́n mo sì mú ọ lọ ní ọ̀nà ti tààrà.
12Nígbà tí o rìn, ìgbẹ́sẹ̀ rẹ kò ní ní ìdíwọ́ nígbà tí o bá sáré, iwọ kì yóò kọsẹ̀.
13Di ẹ̀kọ́ mú, má ṣe jẹ́ kí ó lọ; tọ́jú u rẹ̀ dáradára Nítorí òun ni ìyè rẹ.
14Má ṣe gbé ẹṣẹ̀ rẹ sí ojú ọnà àwọn ènìyàn búburú tàbí kí o rìn ní ọ̀nà àwọn ẹni ibi.
15Yẹra fún un, má ṣe rìn níbẹ̀; yàgò fún un kí o sì bá ọ̀nà tìrẹ lọ
16Nítorí wọn kò le sùn àyàfi tí wọ́n bá ṣe ibi, wọn kò ní tòògbé àyàfi tí wọ́n bá gbé ẹlòmíràn ṣubú
17Wọ́n ń jẹ oúnjẹ ìwà búrurú wọ́n sì ń mu wáìnì ìwà ìkà.
17
18Ipa ọ̀nà Olódodo dàbí àṣẹ̀ṣẹ̀yọ oòrùn tí ń tànmọ́lẹ̀ sí i títí ọjọ́ fi kanrí
19ṣùgbọ́n ọ̀nà ènìyàn búburú dàbí òkùnkùn biribiri; wọn kò mọ ohun tí ó ń mú wọn kọsẹ̀.
19
20Ọmọ mi, tẹ́tí sí ohun tí mo sọ; fetísílẹ̀ dáradára sí ọ̀rọ̀ mi
21Má ṣe jẹ́ kí wọ́n rá mọ́ ọ lójú pa wọ́n mọ́ sínú ọkàn rẹ;
22Nítorí ìyè ni wọ́n jẹ́ fún gbogbo ẹni tí ó rí wọn àti ìlera fún gbogbo ara ènìyàn
23Ju gbogbo nǹkan tó kù lọ, pa ọkàn rẹ mọ́ Nítorí òun ni oríṣun ìyè,
24mú àrékérekè kúrò ní ẹnu rẹ; sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ìṣọkúṣọ jìnnà réré sí ẹnu rẹ.
25Jẹ́ kí ojú ù rẹ máa wo iwájú, jẹ́ kí ìwo ojú ù rẹ máa wo ọ̀kánkán iwájú rẹ sáá.
26ⓐ Kíyèsí ìrìn ẹṣẹ̀ rẹ sì rìn ní àwọn ọ̀nà tí ó dára nìkan
27má ṣe yà sọ́tùn-ún tàbí ṣósì pa ẹṣẹ̀ rẹ mọ́ kúrò nínú ibi.