1Ọmọ mi, fiyè sí ọgbọ́n ọ̀n mi tẹ́tí sílẹ̀ dáradára sí ọ̀rọ̀ àròjinlẹ̀ mi
2kí ìwọ sì lè ní ìṣọ́ra kí ètè rẹ sì le pa ìmọ̀ mọ́.
3Nítorí ètè alágbèrè aṣẹ́wó obìnrin a máa ṣun oyin, ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì kúnná ju òróró lọ
4ṣùgbọ́n ní ìgbẹ̀yìngbẹ́yín, ó korò ju òróòro lọ ó mú bí idà olójú méjì.
5Ẹsẹ̀ rẹ̀ lọ sí ọ̀nà ikú ìgbéṣẹ̀ rẹ̀ lọ tààrà sí ibojì òkú.
6Kò tilẹ̀ ronú nípa ọ̀nà ìyè ọ̀nà rẹ̀ rí pálapàla, ṣùgbọ́n kò tilẹ̀ mọ́.
6
7Nítorí náà, ẹ̀yin ọmọ tẹ́tí sí mi má ṣe yàgò kúrò nínú àwọn nǹkan tí mo sọ
8Rìn ní ọ̀nà tí ó jìnnà síi dáadáa má ṣe súnmọ́ ẹnu ọ̀nà ilé rẹ̀
9àìṣe bẹ́ẹ̀ ìwọ yóò gbé gbogbo agbára rẹ lé ẹlòmíràn lọ́wọ́ àti ọjọ́ ayé rẹ fún ìkà ènìyàn
10kí àwọn àjòjì ó má baà fi ọrọ̀ rẹ ṣara rindin kí làálàá rẹ sì sọ ilé ẹlòmíràn di ọlọ́rọ̀.
11Ní ìgbẹ̀yìn ayé rẹ ìwọ yóò kérora, nígbà tí agbára rẹ àti ara rẹ bá ti joro tán
12Ìwọ yóò wí pé, “Mo ti kórìíra ẹ̀kọ́ tó! Ọkàn mi ṣe wá kóòríra ìbáwí!
13N kò gbọ́ràn sí àwọn olùkọ́ mi lẹ́nu, tàbí kí n fetí sí àwọn tí ń kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́.
14Mo ti bẹ̀rẹ̀ ìparun pátapáta ní àárin gbogbo àwùjọ ènìyàn.”
14
15Mu omi láti inú un kànga tìrẹ Omi tí ń ṣàn láti inú kànga rẹ.
16Ó ha yẹ kí omi ìṣun rẹ kún àkúnya sí ojú ọ̀nà àti odò tí ń sàn lọ sí àárin ọjà?
17Jẹ́ kí wọn jẹ́ tìrẹ nìkan, má ṣe ṣe àjọpín wọn pẹ̀lú àjòjì láéláé.
18Ǹjẹ́, kí oríṣun rẹ di àbùkù fún; kí ó sì yọ nínú aya ìgbà èwe rẹ.
19Abo àgbọ̀nrín tó dára, ìgalà tí ó wu ni jọjọ Jẹ́ kí ọmú rẹ̀ tẹ́ ọ lọ́rùn nígbà gbogbo jẹ́ kí ìfẹ́ rẹ̀ máa fà ọ́ títí láéláé
20Ọmọ mi, èéṣe tí ìfẹ́ aṣẹ́wó fi ń fà ọ́ tí ìwọ sì ń dì mọ́ ìyàwó ẹlòmíràn?
20
21Nítorí ọ̀nà ènìyàn kò farasin rárá fún OLÚWA Ó sì ń gbé gbogbo ọ̀nà rẹ̀ yẹ̀wò
22Ìwà búburú ènìyàn búburú ni yóò mú kó bọ́ sínú okùn; okùn ẹ̀ṣẹ̀ ẹ rẹ̀ dì í le kankan
23Yóò kú nítorí àìgba ẹ̀kọ́ ìwà òmùgọ̀ ara rẹ̀ ló mú kó ṣáko lọ.