1Ọmọ mi, bí ìwọ bá ṣe oníduúró fún aládùúgbò rẹ bí ìwọ bá ti bọwọ́ ní ìlérí májẹ̀mu pẹ̀lú ẹlòmíràn
2Bí a bá ti fi ọ̀rọ̀ tí ó sọ dẹkùn mú ọ, tí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ ti kó ọ sí pàkúté,
3Nígbà náà, ṣe èyí, ìwọ ọmọ mi, láti gba ara rẹ níwọ̀n bí o ti kó sọ́wọ́ aládùúgbò rẹ: lọ kí o sì rẹ ara rẹ sílẹ̀; bẹ aládùúgbò rẹ dáadáa
4Má ṣe jẹ́ kí oorun kí ó kùn ọ́, tàbí kí o tilẹ̀ tòògbé rárá.
5Gba ara rẹ sílẹ̀, bí abo àgbọ̀nrín kúrò lọ́wọ́ ọdẹ, bí ẹyẹ kúrò nínú okùn àwọn pẹyẹpẹyẹ.
5
6Tọ èèrùn lọ, ìwọ ọ̀lẹ kíyèsí ìṣe rẹ̀, kí o sì gbọ́n!
7Kò ní olùdarí, kò sí alábojútó tàbí ọba,
8síbẹ̀, a kó ìpèsè rẹ̀ jọ ní àsìkò òjò yóò sì kó oúnjẹ rẹ̀ jọ ní àsìkò ìkórè.
8
9Yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò dùbúlẹ̀, ìwọ ọ̀lẹ? Nígbà wo ni ìwọ yóò jí kúrò lójú oorun rẹ?
10Oorun díẹ̀, Òògbé díẹ̀, ìkáwọ́gbera láti sinmi díẹ̀
11Òsì yóò sì wá sórí rẹ bí ìgárá ọlọ́ṣà àti àìní bí adigunjalè.
11
12Ènìyàn kénìyàn àti ènìyàn búburú, tí ń ru ẹnu àrékérekè káàkiri,
13tí ó ń sẹ́jú pàkòpàkò, ó ń fi ẹsẹ̀ ṣe àmì ó sì ń fi ìka ọwọ́ rẹ̀ júwe,
14tí ó ń pète búburú pẹ̀lú ẹ̀tàn nínú ọkàn rẹ̀ ìgbà gbogbo ni ó máa ń dá ìjà sílẹ̀.
15Nítorí náà ìdààmú yóò dé báa ní ìsẹ́jú akàn; yóò parun lójijì láì sí àtúnṣe.
15
16Àwọn ohun mẹ́fà wà tí OLÚWA kórìíra, ohun méje ní ó jẹ́ ìríra síi:
17Ojú ìgbéraga, Ahọ́n tó ń parọ́ ọwọ́ tí ń ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀,
18ọkàn tí ń pète ohun búburú, ẹsẹ̀ tí ó yára láti sáré sínú ìwà ìkà,
19Ajẹ́rìí èké tí ń tú irọ́ jáde lẹ́nu àti ènìyàn tí ń dá ìjà sílẹ̀ láàrin àwọn ọmọ ìyá kan.
20Ọmọ mi, pa àṣẹ baba rẹ mọ́ má sì ṣe kọ ẹ̀kọ́ ìyá rẹ sílẹ̀.
21Jẹ́ kí wọn wà nínú ọkàn rẹ láéláé so wọ́n mọ́ ọrùn rẹ
22Nígbà tí ìwọ bá ń rìn, wọn yóò ṣe amọ̀nà rẹ; nígbà tí ìwọ bá sùn, wọn yóò máa ṣe olùsọ́ rẹ; nígbà tí o bá jí, wọn yóò bá ọ sọ̀rọ̀.
23Nítorí àwọn àṣẹ yìí jẹ́ àtùpà, ẹ̀kọ́ yìí jẹ́ ìmọ́lẹ̀, àti ìtọ́niṣọ́nà ti ìbáwí ni ọ̀nà sí ìyè
24yóò pa ọ́ mọ́ kúrò lọ́dọ̀ obìnrin oníṣekúṣe kúrò lọ́wọ́ ẹnu dídùn aya tí ń rin ìrìnkurìn
25Má ṣe ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ síi nínú ọkàn rẹ nítorí ẹwà rẹ tàbí kí o jẹ́ kí ó fi ojú rẹ̀ fà ọ́ mọ́ra,
26nítorí Aṣẹ́wó yóò sọ ọ́ di àkàrà lásánlàsàn ẹ̀mí rẹ gan an sì ni alágbérè ń dọdẹ.
27Ǹjẹ́ ènìyàn ha le è gbé iná lé orí itan kí aṣọ rẹ̀ sì má jòó?
28Ǹjẹ́ ènìyàn le è máa rìn lórí iná? Kí ẹṣẹ̀ rẹ̀ sì má jóná?
29Bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ń lọ sùn pẹ̀lú aya aláya; kò sí ẹni tí ó fọwọ́ kàn án tí yóò lọ láì jìyà.
29
30Àwọn ènìyàn kì í kẹ́gàn olè tí ó bá jalè nítorí àti jẹun nígbà tí ebi bá ń pa á.
31Ṣíbẹ̀ bí ọwọ́ bá tẹ̀ẹ́, ó gbọdọ̀ san ìlọ́po méje bí ó tilẹ̀ kó gbogbo ohun tó ní nílé tà.
32Ṣùgbọ́n ẹni tí ń ṣe àgbérè kò nírònú; ẹnikẹ́ni tí ó bá ń ṣe bẹ́ẹ̀ ó ń pa ara rẹ̀ run ni
33Ìfarapa àti ìtìjú ni tirẹ̀, ẹ̀gàn rẹ̀ kì yóò sì kúrò láéláé;
34nítorí owú yóò ru ìbínú ọkọ sókè, kì yóò sì ṣàánú nígbà tí ó bá ń gbẹ̀san.
35Kò ní gba nǹkankan bí ohun ìtanràn; yóò kọ àbẹ̀tẹ́lẹ̀, bí ó ti wù kí ó pọ̀ tó.