Ìwé Òwe 7:1-27 BYB2014 - Bible AI

1Ọmọ mi, pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, sì fi àwọn òfin mi pamọ́ sínú ọkàn rẹ.

2Pa òfin mi mọ́, ìwọ yóò sì yè tọ́jú ẹ̀kọ́ mi bí ẹyinlójú rẹ

3Kọ wọ́n sí ọwọ́ òsì rẹ, má ṣe fi jẹun kọ wọ́n sí inú ọkàn rẹ.

4Wí fún ọgbọ́n pé, “Ìwọ ni arábìnrin mi,” sì pe òye ní ìbátan rẹ;

5wọn yóò pa ó mọ́ kúrò lọ́wọ́ obìnrin alágbèrè, kúrò lọ́wọ́ ìyàwó onírìnkurìn àti ọ̀rọ̀ ìtànjẹ rẹ̀.

5

6Ní ojú fèrèsé ilé è mi mo wo ìta láti ojú ù fèrèsé.

7Mo rí i láàrin àwọn aláìmọ́kan mo sì kíyèsí láàrin àwọn ọ̀dọ́kùnrin, ọ̀dọ́ kan tí ó ṣe aláìgbọ́n.

8Ó ń lọ ní pópónà ní tòsí i ilé alágbérè obìnrin náà, ó ń rìn lọ sí ọ̀nà ilé e rẹ̀

9ní ìrọ̀lẹ́ bí oòrùn ṣe ń wọ̀, bí òkùnkùn ṣẹ ń bo ni lára.

9

10Bẹ́ẹ̀ ni obìnrin kan jáde wá láti pàdé rẹ̀, ó múra bí aṣẹ́wó pẹ̀lú ètè búburú.

11(Ó jẹ́ aláriwo àti alágídí, ìdí rẹ̀ kì í jókòó nílé;

12bí ó ti ń já níhìn ín ní ó ń já lọ́hùn ún gbogbo orígun ni ó ti ń ba ní ibùba.)

13Ó dìí mú, ó sì fẹnu kò ó ní ẹnu pẹ̀lú ojú dídín ó wí pé:

13

14“Mo ní ọrẹ àlàáfíà ní ilé; lónìí ni mo san ẹ̀jẹ́ mi.

15Nítorí náà ni mo ṣe jáde wá pádé è rẹ; mo wá ọ káàkiri mo sì ti rí ọ!

16Mo ti tẹ́ ibùṣùn mi pẹ̀lú aṣọ aláràbarà láti ilẹ̀ Éjíbítì.

17Mo ti fi nǹkan Olóòórùn dídùn sí ibùṣùn mi bí i míra, álóè àti kínámónì.

18Wá, jẹ́ kí a lo ìfẹ́ papọ̀ ní kíkún títí di àárọ̀; jẹ́ kí a gbádùn ara wa pẹ̀lú ìfẹ́!

19Ọkọ ọ̀ mi ò sí nílé; ó ti lọ sí ìrìnàjò jínjìn.

20Ó mú owó púpọ̀ lọ́wọ́ kò sì ní darí dé kí ó tó di ọ̀sán.”

20

21Pẹ̀lú ọ̀rọ̀ dídùn ó sì í lọ́nà; ó tàn án jẹ pẹ̀lú ẹnu dídùn.

22Kíákíá ni ó tẹ̀lé e bí i màlúù tí ń lọ sí odò ẹran bí àgbọ̀nrín tí ó fẹ́ kẹsẹ̀ bọ pàkúté

23títí tí ọ̀kọ̀ fi gún un ní ẹ̀dọ̀, bí ẹyẹ ṣe ń fẹ́ wọ inú okùn, Láì mọ̀ pé yóò gba ẹ̀mí òun.

23

24Nítorí náà báyìí ẹ̀yin ọmọ mi, tẹ́tí sí mi fọkàn sí nǹkan tí mo sọ.

25Má ṣe jẹ́ kí ọkàn rẹ kí ó yà sí ọ̀nà rẹ̀, tàbí kí ó rìn lọ sí ipa ọ̀nà rẹ̀.

26Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn tí ó ti fà lulẹ̀ Ogunlọ́gọ̀ àwọn alágbára ni ó ti pa.

27Ilé e rẹ̀ ni ọ̀nà tààra sí iṣà òkú, tí ó lọ tààra sí àgbàlá ikú.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
/div>