1ⓐ Ǹjẹ́ ọgbọ́n kò ha ń kígbe síta? Òye kò ha ń gbé ohùn rẹ sókè?
2Ní ibi gíga ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà ní ìkòríta, ní ó dúró;
3Ní ẹgbẹ́ ibodè tí ó wọ ìlú, ní ẹnu ibodè ni ó ń kígbe sókè:
4Sí i yín ẹ̀yin ènìyàn, ní mo ń kígbe pè; Mo gbé ohun mi sókè sí gbogbo ènìyàn,
5Ẹ̀yin aláìmọ́kan, ẹ kọ́gbọ́n; ẹ̀yin aláìgbọ́n, ẹ gba òye.
6Tẹ́tí, nítorí mo ní àwọn ohun iyebíye láti sọ; Mo ya ẹnu mi láti sọ àwọn ohun tí ó tọ̀nà,
7Ẹnu mi ń sọ ohun tí í ṣe òtítọ́, nítorí ètè mi kórìíra ibi.
8Gbogbo ọrọ ẹnu mi ni ó tọ́, kò sí èyí tí ó jẹ́ ẹ̀tàn tàbí àyídáyídà níbẹ̀
9Fún Olóye gbogbo rẹ̀ ni ó tọ̀nà; wọ́n jẹ́ aláìlẹ́gàn fún gbogbo ẹni tí ó ní ìmọ̀.
10Yan ẹ̀kọ́ mi dípò fàdákà, ìmọ̀ dípò o wúrà àṣàyàn,
11Nítorí ọgbọ́n ṣe iyebíye jù ìyùn lọ, kò sí ohun tí ọkàn rẹ̀ fẹ́ tí a sì le fi wé e.
11
12“Èmi, ọgbọ́n ń gbé pẹ̀lú òye; mo ní ìmọ̀ àti ọgbọ́n-inú.
13Ìbẹ̀rù OLÚWA ni ìkóòríra ibi mo kóríra ìgbéraga àti agídí, ìwà ibi àti ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn.
14Ìmọ̀ràn àti ọgbọ́n tí ó yè kooro jẹ́ tèmi mo ní òye àti agbára.
15Nípaṣẹ̀ mi ni ọba ń ṣàkóso tí àwọn aláṣẹ sì ń ṣe òfin tí ó dára
16Nípasẹ̀ mi àwọn ọmọ aládé ń ṣàkóso àti gbogbo ọlọ́lá tí ń ṣàkóso ilẹ̀ ayé.
17Mo fẹ́ràn àwọn tí ó fẹ́ràn mi àwọn tí ó sì wá mi rí mi.
18Lọ́dọ̀ mi ni ọrọ̀ àti ọlá wà Ọrọ̀ tí í tọ́jọ́ àti ìgbéga rere.
19Èso mi dára ju wúrà dáradára lọ; ohun tí mò ń mú wá ju àṣàyàn fàdákà lọ.
20Mò ń rìn ní ọ̀nà òdodo, ní ojú ọ̀nà òtítọ́,
21mò ń fi ọrọ̀ fún gbogbo àwọn tí ó fẹ́ràn mi mo sì ń mú kí ilé ìṣúra wọn kún.
21
22“Èmi ni OLÚWA kọ́kọ́ dá nínú iṣẹ́ rẹ̀. Ṣáájú àwọn iṣẹ́ rẹ̀ àtijọ́;
23A ti yàn mí láti ayérayé, láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, kí ayé tó bẹ̀rẹ̀.
24Nígbà tí kò tíì sí òkun, ni a ti bí mi nígbà tí kò tíì sí ìsun tí ó ní omi nínú;
25kí a tó fi àwọn òkè sí ipò wọn, ṣáájú àwọn òkè ni a ti bí mi,
26kí ó tó dá ilẹ̀ ayé tàbí àwọn oko rẹ̀ tàbí èyíkéyìí nínú eruku ayé.
27Mo wà níbẹ̀ nígbà tí ó fi àwọn ọ̀run sí ipò wọn, nígbà tí ó fi òṣùwọ̀n àyíká sórí ibú omi,
28Nígbà tí ó ṣẹ̀dá òfuurufú lókè tí ó sì fi oríṣun ibú omi sí ipò rẹ̀ láì le è yẹṣẹ̀,
29Nígbà tí ó ṣe ààlà fún omi òkun kí omi má baà kọjá ààlà àṣẹ rẹ̀, àti nígbà tí ó pààlà ìpìlẹ̀ ayé.
30Nígbà náà èmi ni gbẹ́nàgbẹ́nà ẹ̀gbẹ́ẹ rẹ̀ mo kún fún inú dídùn lójoojúmọ́, mo ń yọ̀ nígbà gbobgbo níwájú rẹ̀
31mo ń yọ̀ nínú gbogbo àgbáyé tí ó dá mo sì ní inú dídùn sí àwọn ọmọ ènìyàn.
31
32“Nítorí náà báyìí, ẹ̀yin ọmọ mi, ìbùkún ni fún àwọn tí ó pa ọ̀nà mi mọ́
33fetí sí ìtọ́ṣọ́nà mi kí o sì gbọ́n; má ṣe pa á tì sápá kan.
34Ìbùkún ni fún ẹni tí ó fetí sílẹ̀ sí mi, tí ń sọ́nà ní ẹnu ọ̀nà mi lójoojúmọ́, tí ń dúró ní ẹnu ọ̀nà mi.
35Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá rí mi rí ìyè ó sì rí ojú rere gbà lọ́dọ̀ OLÚWA.
36Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ̀ láti rí ń pa ara rẹ̀ lára gbogbo ẹni tí ó kórira mi fẹ́ ikú.”