1Ọgbọ́n ti kọ́ ilé rẹ̀, ó ti gbẹ́ òpó o rẹ̀ méjèèjì
2ó ti fi ilé pọn tí ó ti fọ̀nà rokà ó sì ti ṣètò o tábìlì oúnjẹ rẹ̀
3ó ti rán àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ jáde, ó sì ń pè, láti ibi tí ó ga jù láàrin ìlú.
4“Jẹ́ kí gbogbo àwọn aláìgbọ́n wọ ibí wá!” Ó ń wí fún àwọn tí kò lọ́gbọ́n pé
5“Wá, ẹ wá fẹ́ oúnjẹ mi sì mu wáìnì tí mo ti pò pọ̀.
6Fi ìwà àìmọ̀kan rẹ sílẹ̀ ìwọ yóò sì yè; rìn ní ọ̀nà òye.
6
7“Ẹnikẹ́ni tí ó bá bá ẹlẹ́gàn wí, kọ lẹ́tà sí àbùkù ẹnikẹ́ni tí ó bá bá ẹni búburú wí kọ lẹ́tà sí èébú.
8Má ṣe bá ẹlẹ́gàn wí, àìṣebẹ́ẹ̀ yóò kórìíra rẹ. Bá Ọlọgbọ́n wí yóò sì fẹ́ràn rẹ;
9kọ́ Ọlọgbọ́n ènìyàn lẹ́kọ̀ọ́, yóò sì gbọ́n sí i kọ́ Olódodo ènìyàn lẹ́kọ̀ọ́, yóò sì fi kún ìmọ̀ rẹ̀.
9
10“Ìbẹ̀rù OLÚWA ni ìbẹ̀rẹ̀ ọgbọ́n, ìmọ̀ nípa Ẹni mímọ́ ni òye.
11Nítorí nípasẹ̀ mi ọjọ́ rẹ yóò gùn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún yóò sì kún ọjọ́ ayé rẹ.
12Bí ìwọ bá gbọ́n, ọgbọ́n rẹ yóò fún ọ ní èrè: bí ìwọ bá jẹ́ ẹlẹ́gàn, ìwọ nìkan ni yóò jìyà.”
12
13Òmùgọ̀ obìnrin jẹ́ aláriwo; ó jẹ́ aláìlẹ́kọ̀ọ́ àti aláì ní ìmọ̀.
14Ó jókòó lẹ́nu ọ̀nà ilé rẹ̀ lórí ìjòkó níbi tí ó ga jù láàrin ìlú,
15ó ń pe àwọn tí ó ń kọjá lọ, tí wọn ń lọ tààrà ní ọ̀nà wọn.
16“Jẹ́ kí gbogbo ẹni tí ó jẹ́ aláìlóye súnmọ́ bí!” Ni ó wí fún ẹni tí òye kù díẹ̀ ká à tó fún.
17“Omi tí a jí mu dùn oúnjẹ tí a jẹ ní ìkọ̀kọ̀ a máa ládùn!”
18Ṣùgbọ́n wọn ò funra pé àwọn òkú wà níbẹ̀, pé àwọn àlejò rẹ̀ wà ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀ isà òkú.