1
2Èyí ni ohun tí Sáírúsì ọba Páṣíà wí pé:
3Ẹnikẹ́ni nínú àwọn ènìyàn rẹ̀ láàárin yín—kí Ọlọ́run rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀, kí ó sì gòkè lọ sí Jérúsálẹ́mù tí ó wà ní Júdà, láti kọ́ tẹ́ḿpìlì OLÚWA Ọlọ́run Ísírẹ́lì, Ọlọ́run tí ó wà ní Jérúsálẹ́mù.
4Kí àwọn ènìyàn ní ibikíbi tí ẹni tí ó lù ú bá ń gbé kí ó fi fàdákà àti wúrà pẹ̀lú ohun tí ó dára àti ẹran-ọ̀sìn, pẹ̀lú ọrẹ àtinúwá ràn án lọ́wọ́ fún tẹ́ḿpìlì Ọlọ́run ní Jérúsálẹ́mù.
5Nígbà náà àwọn olórí ìdílé Júdà àti Bẹ́ńjámínì àti àwọn àlùfáà àti àwọn ará Léfì—olúkúlùkù ẹni tí Ọlọ́run ti fọwọ́ tọ́ ọkàn rẹ̀—múra láti gòkè lọ láti kọ ilé OLÚWA ní Jérúsálẹ́mù.
6Gbogbo àwọn aládùúgbò wọn ràn wọ́n lọ́wọ́ pẹ̀lú ohun èlò ti fàdákà àti wúrà, pẹ̀lú onírúurú ohun ìní àti ẹran ọ̀sìn àti pẹ̀lú àwọn ẹ̀bùn iyebíye, ní àfikún gbogbo àwọn ọrẹ àtinúwá.
7Ní àfikún, ọba Ṣáírúsì mú àwọn ohun èlò tí ó jẹ́ ti ilé OLÚWA jáde wá, tí Nebukadinésárì ti kó lọ láti Jérúsálẹ́mù tí ó sì ti kó sí ilé òrìṣà rẹ̀.
8Ṣáírúsì ọba Páṣíà pàṣẹ fún Mítúrédátì olùṣọ́ ilé ìṣúra láti kó wọn jáde, ó sì kà wọ́n fún Ṣéṣíbásárì ìjòyè Júdà.
9Èyí ni iye wọn:
10
11Gbogbo ohun èlò wúrà àti ti fàdákà ní àpapọ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún márùn ún-ó-lé-irinwó (5,400). Ṣéṣíbáṣárì kó gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí wá pẹ̀lú àwọn ìgbèkùn tí ó gòkè wá láti Bábílónì sí Jérúsálẹ́mù.