Ìwé Ẹ́sírà 10:1-44 BYB2014 - Bible AI

1Nígbà tí Ẹ́sirà ń gbàdúrà tí ó sì ń jẹ́wọ́, ti ó ń sunkún ti ó sì ń gbárayílẹ̀ níwájú ilé Ọlọ́run, ogunlọ́gọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lí ọkùnrin, obìnrin àti àwọn ọmọdé pagbo yí i ká. Àwọn náà ń sunkún kíkorò.

2Nígbà náà ni Ṣékáníáyà ọmọ Jéhíélì, ọ̀kan lára ìran Élámù, sọ fún Ẹ́sírà pé, Àwa ti jẹ́ aláìsọ̀ọ́tọ́ sí Ọlọ́run wa nípa fífẹ́ àwọn obìnrin àjèjì láàrin àwọn ènìyàn tí ó wà yí wa ká. Ṣùgbọ́n ṣíbẹ̀ náà, ìrètí sì wà fún Ísírẹ́lì

3Ní sinsin yìí, ẹ jẹ́ kí a dá májẹ̀mú níwájú Ọlọ́run wa láti lé àwọn obìnrin yìí àti àwọn ọmọ wọn lọ. Gẹ́gẹ́ bí ìmọ̀ràn Ẹ́sírà OLÚWA mi àti ti àwọn tí ó bẹ̀rù àṣẹ OLÚWA Ọlọ́run wa. Ẹ jẹ́ kí a ṣe gẹ́gẹ́ bí òfin.

4Dìde, nítorí, ọ̀rọ̀ tìrẹ ni èyí. Gbogbo wà yóò wá pẹ̀lú rẹ, mú ọkàn le kí o sì ṣe é.

5Nígbà náà ni Ésírà dìde, ó sì fi àwọn aṣíwájú àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì àti gbogbo Ísírẹ́lì sí abẹ́ ìbúra, láti ṣe ohun tí wọ́n dá lábàá. Wọ́n sì búra.

6Nígbà náà ni Ẹ́sírà padà sẹ́yìn kúrò níwájú ilé Ọlọ́run, ó sì lọ sí iyàrá Jéhóhánánì ọmọ Élíásíbù. Nígbà tí ó wà níbẹ̀, kò jẹ oúnjẹ bẹ́ẹ̀ ni kò sì mu omi, nítorí ó sì ń káàánú fún àìsòótọ́ àwọn ìgbèkùn.

7Ìkèdè kan jáde lọ jákèjádò Júdà àti Jérúsálẹ́mù fún gbogbo àwọn ìgbèkùn láti péjọ sí Jérúsálẹ́mù.

8Ẹnikẹ́ni tí ó ba kọ̀ láti jáde wá láàrin ọjọ́ mẹ́ta yóò pàdánù ohun ìní rẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ìpinnu àwọn ìjòyè àti àwọn àgbààgbà, àti pé a ó lé òun fúnraaarẹ̀ jáde kúrò láàrin ìpéjọpọ̀ àwọn ìgbèkùn.

9Láàrin ọjọ́ mẹ́ta náà, gbogbo àwọn ọkùnrin Júdà àti Bẹ́ńjámínì tí péjọ sí Jérúsálẹ́mù. Ní ogúnjọ́ oṣù kẹ́sàn án, gbogbo àwọn ènìyàn jókòó sí ìta gbangba iwájú ilé Ọlọ́run, wọ́n wà nínú ìbànújẹ́ ńlá nítorí ọ̀ran yìí, àti nítorí òjò púpọ̀ tó tì rọ̀.

10Nígbà náà ni àlùfáà Ẹ́sírà dìde, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ti ṣe àìsòótọ́, ẹ ti fẹ́ obìnrin àjèjì, ẹ ti dá kún ẹ̀bi Ísírẹ́lì.

11Nísinsìnyìí, ẹ jẹ́wọ́ níwájú OLÚWA, Ọlọ́run àwọn baba yín, kí ẹ sì ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Ẹ ya ara yín sọ́tọ̀ kúrò láàrin àwọn ènìyàn tí ó yí i yín ká àti láàrin àwọn ìyàwó àjèjì yín.”

12Àpéjọpọ̀ ènìyàn náà sì dáhùn lóhùn rara pé: ohun tí ó sọ dára! A gbọdọ̀ ṣe bí o ti wí.

13Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ni ó wà ni ibi yìí ṣíbẹ̀ àkókò òjò ni; àwa kò sì lè dúró níta. Yàtọ̀ sí èyí, a kò le è yanjú ọ̀rọ̀ yìí láàrin ọjọ́ kan tàbí ọjọ́ méjì, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa pọ̀ jọjọ lórí awọn nǹkan wọ̀nyí.

14Jẹ́ kí àwọn ìjòyè wa ṣojú fún gbogbo ìjọ ènìyàn, lẹ́yìn náà, jẹ́ kí ẹnìkọ̀ọ̀kan nínú àwọn ìlú wa tí ó ti fẹ obìnrin àjèjì wá ní àsìkò tí a yàn, pẹ̀lú àwọn àgbààgbà àti àwọn onídàájọ́ ìlú kọ̀ọ̀kan, títí ìbínú gíga Ọlọ́run wa lórí ọ̀rọ̀ yìí yóò fi kúrò ní orí wa.

15Jónátanì ọmọ Ásáhélì àti Jáhéséáyà ọmọ Jíkífà nìkan pẹ̀lú àtìlẹyìn Mésísúlámù àti Ṣíábétaì ará Léfì, ni wọ́n tako àbá yìí.

16Nígbà náà ni àwọn ìgbèkùn ṣe gẹ́gẹ́ bí wọ́n se fi ẹnu kò sí. Àlùfáà Ẹ́sírà yan àwọn ọkùnrin tí wọ́n jẹ́ olórí àwọn ìdílé, ẹnìkọ̀ọ̀kan láti ìdílé kọ̀ọ̀kan, gbogbo wọn ni a sì mọ̀ pẹ̀lú orúkọ wọn. Ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kẹwàá, wọ́n jòkóó láti ṣe àyẹ̀wò àwọn ẹjọ́ náà,

17Ní ọjọ́ kìn-ní-ní oṣù kìn-ní-ní ni wọn parí pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí wọ́n fẹ́ àwọn obìnrin àjèjì.

18Lára ìran àwọn àlùfáà àwọn wọ̀nyí fẹ́ àwọn obìnrin àjèjì: Nínú ìran Jésíúà ọmọ Jósádákì, àti àwọn arákùnrin rẹ: Mááséáyà, Élíásérì, Járíbù àti Gédáláyà.

19Gbogbo wọn ni wọ́n Ṣe ìpinnu láti lé àwọn ìyàwó wọn lọ, wọ́n sì fi àgbò kan láàrin agbo ẹran lé lẹ̀ fún ẹ̀bi wọn gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹ̀ṣẹ̀

19

20Nínú ìran Ímérì:

20Hánánì àti Ṣébádáyà.

21Nínú ìran Hárímù:

21Mááséáyà, Élíjà, Ṣíhémáyà, Jébíélì àti Úsáyà.

22Nínú ìran Pásíhúrì:

22Élíónáì, Mááséáyà, Ísímáílì, Nétaníẹ́lì, Jósábádì àti Élásáì.

23Lára àwọn ọmọ Léfì:

23Jósábádì, Ṣíhíméì, Kéláéáyà (èyí tí í se Kélítà), Pétíáíyà, Júdà àti Élíásérì.

24Nínú àwọn akọrin: Nínú àwọn asọ́nà: Sálúmù, Télémù àti Úrì.

24Élíásíbù.

25Àti lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tókù: Rámíáyà, Ísíáyà, Málíkíjà, Míjámínì, Éléásánì, Málíkíjà àti Bénáíyà.

25Nínú ìran Párósì:

26Nínú ìran Élámù:

26Mátaníáyà, Ṣékáríáyà, Jéhíélì, Ábídì, Jérémótì àti Élíjà.

27Nínú àwọn ìran Ṣátítù:

27Élíóénáì, Élísíbù, Mátaníáyà, Jérémótì, Ṣábádì àti Ásísà.

28Nínú àwọn ìran Bébáì:

28Jéhóánánì, Hánánáyà, Ṣábábáì àti Átaláì.

29Nínú àwọn ìran Bánì:

29Mésúlámì, Málúkì, Ádáyà, Jásílíbù, Ṣéálì àti Jérémótì.

30Nínú àwọn Páhátì Móábù:

30Ádínà, Kélálì, Bénáíáyà, Mááséíáyà, Mátítaníáyà, Bésálélì, Bínúì ati Mánásè.

31Nínú àwọn ìran Hárímù:

31Élíásérì, Ísíjà, Málíkíjà àti Ṣémáíáyà, Ṣíméínì,

32Bénjámínì, Málílúkì àti Ṣémáríà.

32

33Nínú àwọn ìran Hásíúmù:

33Mátíténáì, Mátítatítayà, Ṣábádì, Élífélétì, Jérémáì, Mánásè àti Ṣíméhì.

34Nínú àwọn ìran Bánì:

34Máádáì, Ámírámù, Úélì,

35Bénáíáyà, Bédéíáyà, Kélúhì,

36Fáníyà, Mérémótì, Élíásíbù,

37Mátítamáyà, Mátíténáì àti Jáásù.

37

38Nínú àwọn ìran Bínúì:

38Ṣíméhì,

39Ṣélémíáyà, Nátanì, Ádáyà,

40Mákánádébáì, Ṣásíáì, Ṣáráì,

41Ásárélì, Ṣélémíáyà, Ṣémáríàyà,

42Ṣálílúmì, Ámáríyà àti Jóṣẹ́fù.

42

43Nínú àwọn ìran Nébò:

43Jérélì, Mátítaíyà, Ṣábádì, Ṣábínà, Jádáì, Jóélì àti Bénáíáyà.

44Gbogbo àwọn wọ̀nyí ló fẹ́ obìnrin àjèjì, àwọn mìíràn nínú wọn sì bi ọmọ ní ipaṣẹ̀ àwọn ìyàwó wọ̀nyí.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
iv>