1ⓐ Wàyí o, wọ̀nyí ni àwọn ènìyàn agbègbè Júdà tí ó gòkè wá láti ìgbèkùn láàrin àwọn tí a kó lọ, ẹni tí Nebukadinésárì ọba Bábílónì ti fi agbára mú ní ìgbèkùn lọ sí Bábílónì (wọ́n padà sí Jérúsálẹ́mù àti Júdà. Olúkúlùkù sí ìlú rẹ̀,
2Àwọn wọ̀nyí bá Ṣérúbábélì, Jéṣúà, Nehemáyà, Ṣéráíyà, Réláéyà, Modekáyì, Bílíṣánì, Mísífárì, Bígífáyì, Réhúmì àti Báánà wá): —
2Iye àwọn ọkùnrin àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì:
3Àwọn ìran Páróṣì jẹ́ ẹgbọ̀kànlá ó dín méjìdínlọ́gbọ̀n — (2,172)
3—
4Ìran Ṣéfátíyà jẹ́ irinwó ó dín méjìdínlọ́gbọ̀n — (372)
4—
5Ìran Árà jẹ́ ẹgbẹ̀rin ó-dín-mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n — (775)
5—
6Ìran Páhátì-Móábù (nípaṣẹ̀ àwọn ọmọ Jéṣúà àti Jóábù) jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjì àti ẹgbẹ̀rin-ó-le-méjìlá — (2,812)
6—
7Ìran Élámì jẹ́ àádọ́tàlélẹ́gbẹ̀fà-ó-lé-mẹ́rin — (1,254)
7—
8Ìran Ṣátù jẹ́ ọ̀tàdínlẹ́gbẹ̀rún — (945)
8—
9Ìran Ṣákáì jẹ́ òjìdínlẹ́gbẹ̀rin — (760)
9—
10Ìran Bánì jẹ́ òjìlélẹ́gbẹ̀ta-ó-lé méjì — (642)
10—
11Ìran Bébáì jẹ́ ẹgbẹ̀ta ó-lé-mẹ́talélógún — (623)
11—
12Ìran Áṣígádì jẹ́ ẹgbẹ̀fa-ó-lé méjìlélógún — (1,222)
12—
13Ìran Ádóníkámù jẹ́ ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀tà-ó-lé mẹ́fà — (666)
13—
14Ìran Bígífáyì jẹ́ ẹgbàá-ó-lé mẹ́rìndínlọ́gọ́ta — (2,056)
14—
15Ìran Ádínì jẹ́ Àádọ́talénírínwó-ólé mẹ́rin — (454)
15—
16Ìran Átérì nípaṣẹ̀ Heṣekáyà jẹ́ méjìdínlọ́gọ́rin — (78)
16—
17Ìran Bésáì jẹ́ Ọ̀rùndínnírínwó-ólé-mẹ́ta — (323)
17—
18Ìran Jórà jẹ́ méjìléláàdọ́fà — (112)
18—
19Ìran Hásúmì jẹ́ igba ólé mẹ́talélógún — (223)
19—
20Ìran Gíbárì jẹ́ márùndínlọ́gọ́run — (95)
21Àwọn ọkùnrin Bétílẹ́hẹ́mù jẹ́ mẹ́talélọ́gọ́fà — (123) —
22Ìran Nétófà jẹ́ mẹ́rìndínlọ́gọ́tà — (56)
22—
23Ìran Ánátótì jẹ́ méjìdínládóje — (128)
23—
24Ìran Áṣímáfétì jẹ́ méjìlélógójì — (42)
24—
25Ìran Kíríátì Jéárímù, Éfírà àti Bérótì jẹ́ ọ̀tàdínlẹ́gbẹ̀rin-ólé-mẹ́ta — (743)
25—
26Ìran Rámà àti Gébà jẹ́ ẹgbẹ̀ta-ó-lé mọ́kànlélógún — (621)
26—
27Ìran Míkímásì jẹ́ méjìlélọ́gọ́fà — (122)
27—
28Ìran Bétélì àti Áì jẹ́ igba-ólé mẹ́talélógún — (223)
28—
29Ìran Nébò jẹ́ méjìléláàdọ́ta — (52)
29—
30Ìran Mágíbísì jẹ́ mẹ́rìndínlọ́gọ́jọ — (156)
30—
31Ìran Élámù jẹ́ àádọ́ta lé-lẹ́gbẹ̀fà-ó-lé-mẹ́rin — (1,254)
31—
32Ìran Hárímù jẹ́ ọ̀rìndínnírínwó — (320)
32—
33Ìran Lódì, Hádídì àti Ónò jẹ́ ọ̀rìndínlẹ́gbẹ̀rin ó-lé-márùn-ún — (725)
33—
34Ìran Jẹ́ríkò jẹ́ ọ̀tàdínnírínwó-ó-lé márùn-ún — (345)
34—
35Ìran Ṣénà jẹ́ egbéjìdínlógún-ó-lé-ọgbọ̀n — (3,630)
36Àwọn Àlùfáà: — Àwọn Ìran Jédáíyà (nípaṣẹ̀ ìdílé Jéṣúà) jẹ́ ogúndínlẹ́gbẹ̀rún ó-dín-méje — (973) —
37Ìran Ímérì jẹ́ àádọ́ta lélẹ́gbẹ̀rún-ó-lé méjì — (1,052)
37—
38Ìran Páṣúrì jẹ́ òjìlélẹ́gbẹ̀fà ó-lé-méje — (1,247)
38—
39Ìran Hárímù jẹ́ ẹgbẹ̀rin-ó-lé mẹ́tadínlógún — (1,017)
40Àwọn ará Léfì: — Àwọn Ìran Jésúà àti Kádíméì (ti ìdílé Hódáfíà) jẹ́ mẹ́rìnléláàdọ́rin — (74)
41Àwọn akọrin: — Àwọn Ìran Áṣáfì jẹ́ méjìdínláádóje — (128)
42Àwọn aṣọ́bodè: — Áwọn ara Ṣálúmì, Átérì, Tánímónì, Ákúbù, Hátítà àti Ṣóbíà jẹ́ mọ́kàndínlógóje — (139)
55Àwọn Ìran tí ìránṣẹ́ Sólómónì: — Ṣótaì, Hásóférétì, Pérúdà, —
55— Àwọn ìránṣẹ́
56Jálà, Dáríkónì, Gídè,
56—
57Ṣépátíà, Hátílì,
57— Pókérì-Háṣébáímì àti Ámì
58Àwọn ìrańṣẹ́ tẹ́ḿpìlì àti àwọn ìran àwọn ìranṣẹ́ Ṣólómónì jẹ́ irinwó-ó-dín-mẹ́jọ — (392)
59Àwọn wọ̀nyí gòkè wá láti àwọn ìlú ti Télì-Mélà, Télì-Háríṣà, Kérúbù, Ádónì àti Ímérì, ṣùgbọ́n wọn kò le fihàn pé àwọn ìdílé wọn ṣèẹ̀wá láti ìran Ísírẹ́lì: —
60Àwọn ìran
60— Déláyà, Tóbíyà àti Nékódà jẹ́ àádọ́tàlélẹ́gbẹ̀ta-ó-lé-méjì — (652)
61Pẹ̀lú láti àárin àwọn àlùfáà: — Àwọn ìránṣẹ — Hóbátà, Hákósì àti Báríṣíláì (ọkùnrin tí ó fẹ́ ọmọbìnrin Báríṣíláì ará Gílíádì a sì ń fi orúkọ náà pè é). —
62Àwọn wọ̀nyí wá ìwé ìrántí ìdílé wọn, ṣùgbọ́n wọn kò rí i, bẹ́ẹ̀ ni a kò kà wọ́n kún ara àlùfáà nítorí, a kà wọ́n sí aláìmọ́.
63Baálẹ̀ pa á láṣẹ fún wọn pé wọn kò gbọdọ̀ jẹ nínú oúnjẹ mímọ́ jùlọ títí tí àlùfáà kan yóò fi ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ pẹ̀lú Úrímù àti Túmímù.
64Gbogbo ìjọ ènìyàn náà jẹ́ (42,360) ẹgbàá mọ́kànlélógún-ó-lé-òjìdínnírinwó.
65Yàtọ̀ sí ẹgbẹ̀ríndínlẹ́gbàárin-ó-dín mẹ́talélọ́gọ́ta (7,337) ìránṣẹ́ ọkùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin; wọ́n ní igba (200) akọrin ọkùnrin àti obìnrin.
66Wọ́n ní ọ̀tàdínlẹ́gbẹ̀rin-ó-dín mẹ́rin ẹṣin (736); ìbaka òjìlélúgba-ó-lé-márùn-ún (245)
67Ràkúnmí jẹ́ irinwó-ó-lé-márùndínlógójì; (435) àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ẹgbẹ̀rínlélọ́gbọ̀n-ó-dín-ọgọ́rin (6,720).
68Ní ìgbà tí wọ́n dé ilé OLÚWA ní Jérúsálẹ́mù, díẹ̀ nínú àwọn olórí àwọn ìdílé fi ọrẹ àtinúwá silẹ̀ fún ṣíṣe àtúnkọ́ ilé Ọlọ́run ní ààyè rẹ̀.
69Gẹ́gẹ́ bí agbára wọn, wọ́n fún ilé ìṣúra fún iṣẹ́ yìí ní ọ̀kẹ́ mẹ́ta (61,000) ìwọ̀n dírámà wúrà, ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n fàdákà (5,000) àti ọgọ́rùn-ún (100) ẹ̀wù àlùfáà.
70Àwọn àlùfáà, àwọn ará Léfì, àwọn akọrin, àwọn aṣọ́bodè àti àwọn ìránṣẹ́ ilé OLÚWA ṣe àtìpó sínú àwọn ìlú wọn, pẹ̀lú àwọn ènìyàn mìíràn, àti ìyókù àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe àtìpó sínú ìlú u wọn.