Ìwé Ẹ́sítà 10:1-3 BYB2014 - Bible AI

1Ọba Ṣéríṣésì sì fi owó ọba lélẹ̀ jákèjádò ilẹ̀ ọba, dé erékùṣù òkun

2Àti gbogbo ìṣe agbára àti títóbi rẹ̀, papọ̀ pẹ̀lú ìròyìn títóbi Módékáì ní èyí tí ọba ti gbé e ga, kò ha wà nínú àkọsílẹ̀ ìwé ọdọọdún ọba ti Médíà àti ti Páṣíà?

3Módékáì ará Júù ni ó jẹ́ igbá kejì ọba Ṣéríṣésì, ó tóbi láàrin àwọn Júù, ó sì jẹ́ ẹni iyì lọ́dọ̀ àwọn Júù ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀, nítorí tí ó ń ṣiṣẹ́ fún ire àwọn ènìyàn an rẹ̀, ó sì ń sọ̀rọ̀ fún àlàáfíà gbogbo àwọn Júù.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
v>