1Ní òru ọjọ́ náà ọba kò le è ṣùn; nítorí náà, ó pàṣẹ kí wọn mú ìwé ìrántí wá, àkọsílẹ̀ ìjọba rẹ̀, wọ́n mú un wá wọ́n sì kàá síi létí.
2Wọ́n rí àkọsílẹ̀ níbẹ̀ pé Módékáì tí sọ àṣírí Bígítanà àti Térésì, àwọn ìjòyè ọba méjì tí wọ́n ń ṣọ́ ẹnu ọ̀nà, tí wọ́n ń gbérò láti pa ọba Ṣérísésì.
3Ọba béèrè pé, “Kí ni ọlá àti iyì tí Módékáì ti gbà fún èyí?”
4Ọba wí pé, “Taa ni ó wà nínú àgbàlá?” Nísinsin yìí Hámánì ṣẹ̀ṣẹ̀ wọ àgbàlá ìta ààfin ni láti sọ fún ọba nípa ṣíṣo Módékáì lórí igi tí ó ti rì fún-un.
5Àwọn ìránṣẹ́ẹ rẹ̀ sì dáhùn pé, “Hámánì ni ó wà níbẹ̀ ó dúró sí inú àgbàlá.”
6Nígbà tí Hámánì wọlé, ọba béèrè lọ́wọ́ọ rẹ̀ pé, “Kí ni kí a ṣe fún ọkùnrin tí inú ọba dùn sí láti bu ọlá fún?”
7Nítorí náà ó dá ọba lóhùn pé, “Fún ọkùnrin tí inú ọba dùn sí láti dá lọ́lá,
8jẹ́ kí wọn kí ó mú aṣọ ọba èyí tí ọba ń wọ̀ àti ẹṣin tí ọba má a ń gùn, pẹ̀lú ọ̀kan lára adé ọba kí a fi dé e ní orí.
9Jẹ́ kí a fí aṣọ àti ẹṣin lé ọ̀kan lára àwọn ìjòyè ọba tí ó ga jùlọ lọ́wọ́, kí wọn wọ aṣọ náà fún ọkùnrin tí inú ọba dùn sí láti dá lọ́lá, kí wọn sì sìn-ín gun ẹṣin jákèjádò gbogbo ìgboro ìlú, kí wọn má a kéde níwájúu rẹ̀ pé, ‘Èyí ni a ṣe fún ọkùnrin náà ẹni tí inú ọba dùn sí láti dá lọ́lá!’ ”
10Ọba pàṣẹ fún Hámánì pé, “Lọ lẹ́ṣẹ̀ kan náà. Mú aṣọ náà àti ẹṣin kí o sì ṣe gẹ́gẹ́ bí o ṣe sọ fún Módékáì araa Júù, ẹni tí ó jókòó sí ẹnu ọ̀nà ọba. Má ṣe fi ohunkóhun sílẹ̀ nínú ohun tí o ti yàn.”
11Bẹ́ẹ̀ ni Hámánì ṣe mú aṣọ àti ẹṣin náà. Ó fi wọ Módékáì, Módékáì sì wà lórí ẹṣin jákèjádò gbogbo ìgboro ìlú, ó sì ń kéde níwájúu rẹ̀ pé, “Èyí ni a ó ṣe fún ọkùnrin náà ẹni tí inú ọba dùn sí láti dá lọ́lá!”
12Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí Módékáì padà sí ẹnu ọ̀nà ọba. Ṣùgbọ́n Hámánì ṣáré lọ ilé, ó sì bo oríi rẹ̀ pẹ̀lú ìbànújẹ́,
13Ó sì sọ ohun gbogbo tí ó ṣẹlẹ̀ síi fún Ṣérésì ìyàwóo rẹ̀ àti àwọn ọ̀rẹ́ẹ rẹ̀.
14Bí wọ́n ṣe ń báa sọ̀rọ̀, àwọn ìwẹ̀fà ọba wọlé, wọ́n sì kán Hámánì lójú láti lọ sí ibi àṣè tí Ẹ́sítà ti pèsè.