Ìwé Ẹkún Jeremáyà 2:1-22 BYB2014 - Bible AI

1Báwo ni OLÚWA ṣe bo ọmọbìnrin Síónì pẹ̀lú ìkúùkù ìbínú rẹ̀! Ó sọ ògo Ísírẹ́lì kalẹ̀ Láti ọ̀run sí ayé; kò rántí àpótí-ìtìṣẹ̀ rẹ̀ ní ọjọ́ ìbínú rẹ̀.

2Làìní àánú ni OLÚWA gbé ibùgbé Jákọ́bù mì; nínú ìrunú rẹ̀ ni ó wó ibi gíga ọmọbìnrin Júdà lulẹ̀. Ó ti mú ìjọba àti àwọn ọmọ aládé ọkùnrin lọ sínú ilẹ̀ ní àìlọ́wọ̀.

2

3Ní ìbínú gbígbóná rẹ̀ ni ó ké gbogbo ìwo Ísírẹ́lì. Ó ti mú ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ kúrò nígbà tí àwọn ọ̀tá dé. Ó run ní Jákọ́bù bí ọ̀wọ́ iná ní àgọ́ àwọn ọmọbìnrin Síónì.

3

4Ó na ọfà rẹ̀ bí ọtá; ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ sì múra Bí ti ọ̀ta tí ó ti parun ó tú ìbínú rẹ̀ jáde bí iná sórí àgọ́ ọmọbìnrin Síónì.

4

5OLÚWA dà bí ọ̀tá; ó gbé Ísírẹ́lì mì. Ó ti gbé gbogbo ààfin rẹ̀ mì ó pa ibi gíga rẹ̀ run. Ó sọ ìmí ẹ̀dùn àti ìbànújẹ́ di púpọ̀ fún àwọn ọmọbìnrin Júdà.

5

6Ó mú ìparun bá ibimímọ́, ó pa ibi ìpàdé rẹ̀ run. OLÚWA ti mú Síónì gbàgbé ọjọ́ àṣè àti ọ̀ṣẹ̀ tí ó yàn; nínú ìbínú gbígbóná rẹ̀ ni ó run ọba àti olórí àlùfáà.

6

7OLÚWA ti kọ̀ pẹpẹ rẹ̀ sílẹ̀ ó sì ti kọ̀ ibi mímọ́ rẹ̀. Ó sì fi lé ọ̀ta lọ́wọ́ àwọn odi ààfin rẹ̀; wọ́n sì kígbe ní ilé OLÚWA gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ ìpèjẹ tí a yàn.

7

8OLÚWA pinnu láti fa ògiri tí ó yí ọmọbìnrin Síónì ya. Ó gbé wọn sórí òṣùnwọ̀n, kò sì fa ọwọ́ rẹ̀ padà kúrò nínú ìparun wọn. Ó mú kí ilé-ìsọ́ àti odi rẹ̀ sọ̀fọ̀ wọ́n ṣòfò papọ̀.

8

9Ẹnu ọ̀nà rẹ̀ ti wọ inú ilẹ̀; òpó rẹ̀ ni ó wó tí ó sì ti bàjẹ́. Ọba àti ọmọ ọbakùnrin rẹ̀ wà ní ìgbèkùn láàrin àwọn orílẹ̀ èdè, kò sí òfin mọ́, àwọn wòlíì rẹ̀ kò rí ìran láti ọ̀dọ̀ OLÚWA mọ́.

9

10Àwọn àgbààgbà ọmọbìnrin Síónì jókòó sílẹ̀ ní ìdákẹ́rọ́rọ́; wọ́n da eruku sí orí wọn wọ́n sì wọ aṣọ àkísà. Àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin Jérúsálẹ́mù ti tẹrí wọn ba sí ilẹ̀.

10

11Ojú mi kọ̀ láti sunkún, mo ń jẹ ìrora nínú mi, mo tú ọkàn mi jáde sí ilẹ̀ nítorí a pa àwọn ènìyàn mí run, nítorí àwọn ọmọdé àti ọmọ ọwọ́ ń kú ní òpópó ìlú.

11

12Wọ́n wí fún àwọn ìyá wọn, “Níbo ni àkàrà àti wáìnì wà?” Wò ó bí wọ́n ṣe ń kú lọ bí àwọn ọkùnrin tí a ṣe léṣe ní àwọn òpópónà ìlú, bí ayé wọn ṣe ń ṣòfò láti ọwọ́ ìyá wọn.

12

13Kí ni mo le sọ fún ọ? Pẹ̀lú u kí ni mo lè fi ọ́ wé, Ìwọ ọmọbìnrin Jérúsálẹ́mù? Kí sì ni mo lè fi ọ́ wé, kí n lè tù ọ́ nínú, Ìwọ wúndíá bìnrin Síónì? Ọgbẹ́ rẹ jìn bí òkun. Ta ni yóò wò ọ́ sàn?

13

14Ìran àwọn wòlíì rẹ jẹ́ kìkì ẹ̀tàn láìní ìwọ̀n; wọn kò sì fi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ hàn tí yóò mú ìgbèkùn kúrò fún ọ. Àwọn òrìṣà tí wọ́n fún ọ jẹ́ èké àti ìsìnà.

14

15Àwọn tí ó gba ọ̀nà ọ̀dọ̀ rẹ pàtẹ́wọ́ lé ọ lórí; wọ́n kẹ́gàn wọ́n ju orí wọn sí ọmọbìnrin Jérúsálẹ́mù: “Èyí ha ni ìlú tí à ń pè ní àṣepé ẹwà, ìdùnnú gbogbo ayé?”

15

16Gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ la ẹnu wọn gbòòrò sí ọ; wọ́n kẹ́gàn, wọ́n sì payín keke wọ́n wí pé, “A ti gbé e mì tán. Èyí ni ọjọ́ tí a ti ń retí; tí a sì wá láti rí.”

16

17OLÚWA ti ṣe ohun tí ó pinnu; ó ti mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ, tí ó sì pàṣẹ ní ọjọ́ pípẹ́. Ó ti sí ọ nípò láì láàánú, ó fún ọ̀tá ní ìsẹ́gun lórí rẹ, ó ti gbé ìwo àwọn ọ̀tá rẹ̀ ga.

17

18Ọkàn àwọn ènìyàn kígbe jáde sí OLÚWA. Odi ọmọbìnrin Síónì, jẹ́ kí ẹkún rẹ̀ ṣàn bí odò ní ọ̀sán àti òru; má ṣe fi ara rẹ fún ìtura, ojú rẹ fún ìsinmi.

18

19Dìde, kígbe sókè ní àsálẹ́, bí ìṣọ́ òru ti bẹ̀rẹ̀ tú ọkàn rẹ̀ jáde bí omi níwájú OLÚWA. Gbé ọwọ́ yín sókè sí i nítorí ẹ̀mí àwọn èwe rẹ̀ tí ó ń kú lọ nítorí ebi ní gbogbo oríta òpópó.

19

20“Wòó, OLÚWA, kí o sì rò ó: Ta ni ìwọ ti fìyà jẹ bí èyí Ǹjẹ́ àwọn obìnrin yóò ha jẹ ọmọ wọn, àwọn ọmọ tí wọn ń se ìtọ́jú fún? Ǹjẹ́ kí a pa olórí àlùfáà àti àwọn wòlíì ní ibi mímọ́ OLÚWA?

20

21“Ọmọdé àti àgbà ń sùn papọ̀ sínú eruku àwọn òpópó; àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin mi ti ṣègbé nípa idà. Ìwọ pa wọ́n run ní ọjọ́ ìbínú rẹ; Ìwọ pa wọ́n láìní àánú.

21

22“Bí ó ti ṣe ní ọjọ́ àṣè, bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe fi ẹ̀rù sí ẹ̀gbẹ́ mi. Ní ọjọ́ ìbínú OLÚWA kòsí ẹni tí ó sálà tí ó sì yè; àwọn tí mo ti tọ́jú tí mo sì fẹ́ràn, ni ọ̀ta mi parun.”

le>