1Èmi ni ọkùnrin tí ó rí ìpọ́njú pẹ̀lú ọ̀pá ìbínú.
2Ó ti lémi jáde ó sì mú mi rìn nínú òkùnkùn ju ti ìmọ́lẹ̀;
3Nítòótọ́, ó ti yí ọwọ́ padà sí mi síwájú àti síwájú sí i ní gbogbo ọjọ́.
3
4Ó jẹ́ kí àwọ̀ mi àti ẹran ara mi gbó ó sì tún ṣẹ́ egungun mi.
5Ó ti fi mí sí ìgbèkùn ó sì ti yí mi ká pẹ̀lú ìkorò àti làálàá.
6Ó mú mi gbé nínú òkùnkùn bí ti àwọn tó ti kú fún ìgbà pípẹ́.
6
7Ó ti tì mí mọ́lé nítorí náà n kò le è sálọ; ó ti fi ẹ̀wọ̀n mú mi mọ́lẹ̀
8Pàápàá nígbà tí mo ké fún ìrànlọ́wọ́, ó kọ àdúrà mi.
9Ó fi búlọ́kù òkúta dí ọ̀nà mi; ó sì mú ọ̀nà mi wọ́
9
10Bí i béárì tí ó dùbúlẹ̀, bí i kìnnìún tí ó sá pamọ́.
11Ó wọ́ mi kúrò ní ọ̀nà, ó tẹ̀ mí mọ́lẹ̀ ó fi mi sílẹ̀ láì sí ìrànlọ́wọ́.
12Ó fa ọfà rẹ̀ yọ ó sì fi mí sohun ìtafàsí.
12
13Ó fa ọkàn mí ya pẹ̀lú ọfà nínú àkọ̀ rẹ̀.
14Mo di ẹni yẹ̀yẹ́ láàrin àwọn ènìyàn mi; wọn yẹ̀yẹ́ mi pẹ̀lú orin ní gbogbo ọjọ́.
15Ó ti kún mi pẹ̀lú ewé kíkorò àti ìdààmú bí omi.
15
16Ó ti fi òkúta kán ẹyín mi; ó ti tẹ̀ mí mọ́lẹ̀ nínú eruku.
17Mo ti jìnnà sí àlàáfíà; Mo ti gbàgbé ohun tí àṣeyege ń ṣe.
18Nítorí náà mo wí pé, “Ògo mi ti lọ àti ìrètí mi nínú OLÚWA.”
18
19Mo ṣe ìrántí ìpọ́njú àti ìdààmú mi, ìkorò àti ìbànújẹ́.
20Mo ṣèrántí wọn, ọkàn mi sì gbọgbẹ́ nínú mi.
21Síbẹ̀, èyí ni mo ní ní ọkàn àti nítorí náà ní mo nírètí.
21
22Nítorí ìfẹ́ OLÚWA tí ó lágbára ni àwa kò fi ṣègbé, nítorí àánú rẹ kì í kùnà.
23Wọ́n jẹ́ ọ̀tún ní àárọ̀; títóbi ni òdodo rẹ̀.
24Mo wí fún ara mi, ìpín mi ni OLÚWA; nítorí náà èmi yóò dúró dè ọ́
24
25Dídára ni OLÚWA fún àwọn tí ó ní ìrètí nínú rẹ̀, sí àwọn tí ó ń wá a.
26Ó dára kí a ní ṣùúrù fún ìgbàlà OLÚWA.
27Ó dára fún ènìyàn láti gbé àjàgà nígbà tí ó wà ní èwe.
27
28Jẹ́ kí ó jókòó ní ìdákẹ́jẹ́, nítorí OLÚWA ti fi fún un.
29Jẹ́ kí ó bò ojú rẹ̀ sínú eruku— ìrètí sì lè wà.
30Jẹ́ kí ó fi ẹ̀rẹ̀kẹ́ fún àwọn tí yóò gbá a, sì jẹ́ kí ó wà ní ìdójútì.
30
31Ènìyàn kò di ìtanù lọ́dọ̀ OLÚWA títí láé.
32Lóòtọ́ ó mú ìbànújẹ́ wá, yóò fi àánú hàn, nítorí náà títóbi ni ìfẹ́ rẹ̀.
33Nítorí kò mọ̀ọ́mọ̀ mú ìpọ́njú wá tàbí ìrora wá fún ọmọ ènìyàn.
33
34Kí ó tẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀ gbogbo àwọn ẹlẹ́wọ̀n ní ilẹ̀ náà.
35Láti ṣẹ́ ọmọ ènìyàn fún ẹ̀tọ́ rẹ̀ níwájú ẹni ńlá.
36Láti yí ìdájọ́ ènìyàn po, Ǹjẹ́ OLÚWA kò rí ohun bẹ́ẹ̀.
36
37Ta ni yóò sọ̀rọ̀ tí yóò rí bẹ́ẹ̀ tí OLÚWA kò bá fàṣẹ sí i.
38Ǹjẹ́ kì í ṣe láti ẹnu ẹni ńlá ni dídára àti búburú tí ń wá?
39Kí ló dé tí ẹ̀dá alàyè ṣe ń kùn nígbà tí ó bá ń jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.
39
40Ẹ jẹ́ kí a yẹ ọ̀nà wa kí a sì dán an wò, kí a sì tọ OLÚWA lọ.
41Ẹ jẹ́ kí a gbé ọkàn àti ọwọ́ wa sókè sí Ọlọ́run ní ọ̀run, kí a wí pé:
42Àwa ti ṣẹ̀ a sì ti ṣọ̀tẹ̀ ìwọ kò sì fi ẹ̀ṣẹ̀ wa jìn wá.
42
43“Ìwọ fi ìbínú bo ara rẹ ìwọ sì ń lépa wa; ìwọ ń parun láì sí àánú.
44Ìwọ ti fi ìkuukù bo ara rẹ pé kí àdúrà wa má ba à dé ọ̀dọ̀ rẹ.
45Ó ti sọ wá di èérí àti ààtàn láàrin orílẹ̀ èdè gbogbo.
45
46“Gbogbo àwọn ọ̀tá wa ti la ẹnu wọn gbòòrò sí wa.
47Àwa ti jìyà àti ìparun, nínú ìbẹ̀rù àti ewu.”
48Omijé ń ṣàn ní ojú mi bí odò nítorí a pa àwọn ènìyàn mi run.
48
49Ojú mi kò dá fún omijé, láì sinmi,
50títí ìgbà tí OLÚWA síjú wolẹ̀ láti òkè ọ̀run tí yóò sì rí i.
51Ohun tí mo rí mú ìbẹ̀rù wá ọkàn mi nítorí gbogbo àwọn obìnrin ìlú mi.
51
52Àwọn tí ó jẹ́ ọ̀tá mi láìnídìí dẹ mí bí ẹyẹ.
53Wọ́n gbìyànjú láti mú òpin dé bá ayé mi nínú ihò wọ́n sì ju òkúta lù mí.
54Orí mi kún fún omi, mo sì rò pé ìgbẹ̀yìn dé.
54
55Mo pe orúkọ rẹ, OLÚWA, láti ọ̀gbun ìsàlẹ̀ ihò.
56Ìwọ gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi: “Má ṣe di etí rẹ sí igbe ẹ̀bẹ̀ mi fún ìtura.”
57O wá tòsí nígbà tí mo ké pè ọ́, o sì wí pé, “Má se bẹ̀rù.”
57
58OLÚWA, ìwọ gba ẹjọ́ mi rò, o ra ẹ̀mí mi padà.
59O ti rí i, OLÚWA, búburú tí a ṣe sí mi Gbé ẹjọ́ mi ró!
60Ìwọ ti rí ọ̀gbun ẹ̀san wọn, gbogbo ìmọ̀ wọn sí mi.
60
61OLÚWA ìwọ ti gbọ́ ẹ̀gàn wọn àti ìmọ̀ búburú wọn sí mi—
62Ohun tí àwọn ọ̀tá mi ń sọ sí mi ní gbogbo ọjọ́.
63Wò wọ́n! Ní jíjòkòó tàbí ní dídìde, wọ́n ń ṣẹlẹ́yà mi nínú orin wọn.
63
64OLÚWA san wọ́n lẹ́san ohun tí ó tọ́ sí wọn fún ohun tí ọwọ́ wọn ti ṣe.
65Fi ìbòjú bò wọ́n ní ọkàn, kí o sì fi wọ́n ré.
66Ni wọ́n lára kí o sì pa wọ́n run pẹ̀lú ìbínú, lábẹ́ ọ̀run OLÚWA.