Ìwé Ẹkún Jeremáyà 4:1-22 BYB2014 - Bible AI

1Báwo ni wúrà ṣe sọ ògo dídán rẹ̀ nù, wúrà dídára di àìdán! Òkúta ibi mímọ́ wá túká sí oríta gbogbo òpópó.

2Báwo ni àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin Síónì tí ó ṣe iyebíye, tí wọ́n wọn iye wúrà ṣe wá dàbí ìkòkò amọ̀ lásán iṣẹ́ ọwọ́ amọ̀kòkò!

2

3Àwọn ọ̀wàwà pèsè ọmú wọn fún ìtọ́jú àwọn ọmọ wọn, ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn mi wá láì lọ́kàn bí ògòǹgò ní aṣálẹ̀.

3

4Nítorí òùngbẹ, ahọ́n àwọn ọmọ ọwọ́ lẹ̀ mọ́ òkè ẹnu wọn; àwọn ọmọdé bẹ̀bẹ̀ fún oúnjẹ Ṣùgbọ́n kòsí ẹni tí ó fi fún wọn.

4

5Àwọn tí ó ń jẹ ohun dáradára di òtòsì ní òpópó. Àwọn tí a fi aṣọ dáradára wọ̀ ni wọ́n sùn ní orí òkítì eérú.

5

6Ìjìyà àwọn ènìyàn mi tóbi ju ti Sódómù lọ, tí a sí nípò ní òjijì láì sí ọwọ́ láti ràn án lọ́wọ́.

6

7Ọmọ ọba ọkùnrin wọn mọ́ ju òjò dídì, wọ́n sì funfun ju wàrà lọ lára, wọ́n ni ìtọ́jú bí iyùn pupa, ìrísí wọn dàbí sáfírè.

7

8Ṣùgbọ́n nísinsìn yìí wọ́n dúdú ju èédú; wọn kò sì dá wọn mọ̀ ní òpópó. Ara wọn hun mọ́ egungun; ó sì gbẹ bí igi gbígbẹ.

8

9Àwọn tí ó kù nípasẹ̀ idà sàn ju àwọn tí ìyàn pa; tí ó wọ àkísà ebi, tí ó ń ṣòfò fún àìní oúnjẹ láti inú pápá.

9

10Pẹ̀lú ọwọ́ àwọn obìnrin aláàánú ni wọ́n ṣe ọmọ wọn tí ó di oúnjẹ fún wọn nígbà tí a pa àwọn ènìyàn mi run.

10

11OLÚWA ti fi ihò kíkún fún ìbínú rẹ̀; ó sì tú ìbínú gbígbóná rẹ̀ jáde. Ó da iná ní Síónì tí ó jó ìpìlẹ̀ rẹ̀ run.

11

12Àwọn ọba ayé kò gbàgbọ́, tàbí àwọn ènìyàn ayé, wí pé àwọn ọ̀tá àti aninilára le wọ odi ìlú Jérúsálẹ́mù.

12

13Èyí ṣẹlẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn wòlíì àti àìṣedédé àwọn olórí àlùfáà, tí ó ta ẹ̀jẹ̀ àwọn olódodo sílẹ̀ láàrin rẹ̀.

13

14Nísinsìnyí wọ́n ń rìn kiri ní òpópó bí ọkùnrin tí ó fọ́jú. Ẹ̀jẹ̀ ara wọn sọ wọ́n di àbàwọ́n tí kò sẹ́ni tó láyà láti fọwọ́ kan aṣọ wọn.

14

15“Lọ kúrò! Ẹ̀yin di aláìmọ́!” ni àwọn ènìyàn ń kígbe sí wọn. “Ẹlọ! Ẹlọ! Ẹ má se fọwọ́ kàn wá!” Àwọn ènìyàn láàrin orílẹ̀ èdè wí pé, “Wọn kì yóò tẹ̀dó síbí mọ́.”

15

16OLÚWA ti tú wọn ká fún-ra-ra-rẹ̀; kò sí bojú tó wọn mọ́. Kò sí ọ̀wọ̀ fún olórí àlùfáà mọ́, àti àánú fún àwọn àgbà.

16

17Síwájú sí i, ojú wa kùnà fún wíwo ìrànlọ́wọ́ asán; láti orí ìṣọ́ wa ni à ń wò fún orílẹ̀-èdè tí kò le gbà wá là.

17

18Wọ́n ń ṣọ́ wa kiri, àwa kò sì le rìn ní òpópó wa mọ́. Òpin wa ti súnmọ́, ọjọ́ wa sì níye nítorí òpin wa ti dé.

18

19Àwọn tí ń lé wa yára ju idì ojú ọ̀run lọ; wọ́n lé wa ní gbogbo orí òkè wọ́n sì gẹ̀gùn dè wá ní ihà.

19

20Ẹni àmì òróró OLÚWA, èémí ìyè wa, ni wọ́n fi tàkúté wọn mú. Àwa rò pé lábẹ́ òjìji rẹ̀ ni àwa yóò máa gbé láàrin orílẹ̀-èdè gbogbo.

20

21Ẹ yọ̀ kí inú yín sì dùn, ẹ̀yin ọmọbìnrin Édómù, ẹ̀yin tó ń gbé ní ilẹ̀ Húsì. Ṣùgbọ́n, a ó gbé aago náà kọjá sọ́dọ̀ rẹ pẹ̀lú; ìwọ yóò yó bí ọ̀mùtí, ìwọ yóò sì rìn ní ìhòòhò.

21

22Ìwọ ọmọbìnrin Síónì, ìjìyà rẹ yóò dópin; kò ní mú ìgbékùn rẹ pẹ́ mọ́. Ṣùgbọ́n, ìwọ ọmọbìnrin Édómù, yóò jẹ ẹ̀sẹ̀ rẹ níyà yóò sì fi àìṣedédé rẹ hàn kedere.

le>