Ìwé Ẹkún Jeremáyà 5:1-22 BYB2014 - Bible AI

1Rántí, OLÚWA, ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí wa; wò ó, kí o sì rí ìtìjú wa.

2Àwọn ohun ìní wa ti di ti àlejò, ilé wa ti di ti àjèjì.

3Àwa ti di aláìní òbí àti aláìní baba, àwọn ìyá wa ti di opó.

4A gbọdọ̀ ra omi tí à ń mu; igi wa di títà fún wa.

5Àwọn tí ó ń lé wa sún mọ́ wa; àárẹ̀ mú wa àwa kò sì rí ìsinmi.

6Àwa jọ̀wọ́ ara wa fún Éjíbítì àti Ásíríà láti rí oúnjẹ tótó jẹ.

7Àwọn baba wa ti ṣẹ̀, wọn kò sì sí mọ́, àwa sì ń ru ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

8Àwọn ẹrú ń jọba lórí wa, kò sì sí ẹni tí yóò gbà wá lọ́wọ́ wọn.

9Àwa ń rí oúnjẹ wa nínú ewu ẹ̀mí wa nítorí idà tí ó wà ní ihà.

10Ẹran ara wa gbóná bí ààrò, ebi sì yó wa bí àárẹ̀.

11Wọ́n ti fipá bá àwọn obìnrin wa lò pọ̀ ní Síónì, àti àwọn wúndíá wa ní ìlú Júdà.

12Àwọn ọmọ ọbakùnrin ti di ṣíṣo sókè ní ọwọ́ wọn; kò sí ìbọ̀wọ̀ fágbà mọ́.

13Àwọn ọdọ́mọkùnrin wa ru òkúta; àwọn ọmọkùnrin sì ńṣsàárẹ̀ lábẹ́ ẹrù igi.

14Àwọn àgbààgbà ti lọ kúrò ní ẹnu bodè ìlú; àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin sì dákẹ́ orin wọn

15Ayọ̀ ti ṣáko ní ọkàn wa; ọ̀fọ̀ sì ti dúró bí ijó fún wa.

16Adé ti sí kúrò ní orí wa Ègbé ni fún wa, nítorí a ti ṣẹ̀.

17Nítorí èyí, àárẹ̀ mú ọkàn wa, nítorí èyí, ojú wa sì ṣú.

18Fún òkè Síónì tí ó ti di ahoro lórí rẹ̀ àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ sì ń rìn kiri.

19Ìwọ, OLÚWA, jọba títí láé; ìjọba rẹ dúró láti ìran kan dé ìran mìíràn.

20Kí ló dé tí o n gbàgbé wa ní gbogbo ìgbà? Kí ló dé tí o fi kọ̀ wá sílẹ̀ fún ọjọ́ pípẹ́?

21Mú wa padà sí ọ̀dọ̀ rẹ, OLÚWA, kí àwa kí ó le padà; mú ọjọ́ wa di tuntun bí ìgbà a nì

22Àyàfi tí o bá ti kọ̀ wá sílẹ̀ pátápátá tí ìbínú rẹ sí wa sì kọjá ìwọ̀n.

le>