Ìwé Deutarónómì 1:1-46 BYB2014 - Bible AI

1Wọ̀nyí ni àwọn ọ̀rọ̀ tí Mósè sọ fún gbogbo Ísírẹ́lì ní ihà ìlà oòrùn Jọ́dánì, aginjù: ní òdì kejì Súfì, ní àárin Páránì àti Tófẹ́lì, Lábánì, Hásérótì àti Dísáhábì.

2(Ọjọ́ mọ́kànlá ni ó gbà láti rin ìrìnàjò láti Hórébù dé Kadesi-Báníyà, bí a bá gba ọ̀nà òkè Ṣéírì.)

3Ní ìgbà tí ó pé ogójì ọdún, ní ọjọ́ kìn-ín-ní osù kọ́kànlá, Mósè sọ ohun gbogbo tí Ọlọ́run pa láṣẹ nípa àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fún wọn.

4Èyí sẹlẹ̀ lẹ́yìn ìgbà tí ó ti ṣẹ́gun Síhónì ọba àwọn Ámórì, tí ó jọba ní Hésíbónì, àti Ógù ọba Básánì ni ó ṣẹ́gun ní Édírénì, ẹni tí ó jọba ní Ásítarótù.

5Ní ìhà ìlà oòrùn Jọ́dánì tí ó wà nínú ilẹ̀ Móábù ni Mósè ti bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣàlàyé àwọn òfin wọ̀nyí wí pé:

6OLÚWA Ọlọ́run wa bá wa sọ̀rọ̀ ní Hórébù pé, “Ẹ ti dúró ní orí òkè yìí pẹ́ tó.

7Ẹ yípadà kí ẹ sì tẹ̀ṣíwájú ní ìrìnàjò yín lọ sí ilẹ̀ òkè àwọn ará Ámórì: Ẹ tọ gbogbo àwọn ènìyàn tí ó ń gbé agbégbé lọ ní aginjù, ní àwọn orí òkè àti pẹ̀tẹ́lẹ̀, ní Nágéfì àti ní etí òkun, lọ sí ilẹ̀ àwọn ará Kénánì àti lọ sí Lẹ́bánónì, títí fi dé odò ńlá Éfúrétì.

8Wò ó, èmi tí fi ilẹ̀ yí fún un yín: Ẹ wọ inú rẹ̀ lọ kí ẹ sì gba ilẹ̀ náà tí OLÚWA ti wí pé òun yóò fún àwọn baba yín: fún Ábúráhámù, Ísáákì, àti Jákọ́bù, àti fún àwọn àrọ́mọdọ́mọ wọn.”

9ⓐ Mo wí fún-un yín nígbà náà pé, “Èmi nìkan kò lè dá ẹrù u yín gbé mọ́.

10OLÚWA Ọlọ́run yín ti sọ yín di púpọ̀ lónìí, ẹ̀yin sì ti pọ̀ bí ìràwọ̀ ní ojú ọ̀run.

11Kí OLÚWA Ọlọ́run àwọn baba yín sọ yín di púpọ̀ ní ọ̀nà ẹgbẹ̀rún sí i, kí ó sì bùkún un yín gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí.

12Báwo ni èmi nìkan ṣe lè má a ru àjàgà àti ìsòro yín àti èdè àìyedè yín?

13Ẹ yan àwọn ọlọgbọ́n, olóye àti àwọn ẹni àpọ́nlé, láti inú ẹ̀yà yín kọ̀ọ̀kan, èmi yóò sì fi wọ́n ṣe olórí yín.”

14Ẹ̀yin sì dá mi lóhùn wí pé, “Ohun tí ìwọ ti gbérò láti ṣe n nì dára.”

15Bẹ́ẹ̀ ni mo yan àwọn aṣáájú ẹ̀yà yín, àwọn ọlọgbọ́n àti ẹni àpọ́nlé láti ṣe àkóso lórí yín: gẹ́gẹ́ bí olùdarí ẹgbẹgbẹ̀rún, ọgọgọ́rùn-ún, àràádọ́ta, ẹ̀wẹ̀ẹ̀wá àti gẹ́gẹ́ bí olórí àwọn ẹ̀yà.

16ⓑ Mo sì kìlọ̀ fún àwọn onídàájọ́ yín nígbà náà pé: Ẹ gbọ́ èdè àìyedè tí ó wà láàrin àwọn ènìyàn an yín kí ẹ sì ṣe ìdájọ́ òdodo, bóyá ẹjọ́ tí ó ṣẹlẹ̀ láàrin Ísírẹ́lì sí Ísírẹ́lì ni tàbí láàrin Ísírẹ́lì kan sí àlejò.

17Ẹ má sì se ojúṣàájú ní ìdájọ́: Ẹ ṣe ìdájọ́ ẹni ńlá àti kékeré bákan náà. Ẹ má ṣe bẹ̀rù ẹnikẹ́ni torí pé ti Ọlọ́run ni ìdájọ́. Ẹjọ́ tí ó bá le jù fún un yín ni kí ẹ mú wá fún mi. Èmi yóò sì gbọ́ ọ.

18Nígbà náà ni èmi yóò ṣọ ohun tí ẹ ó ṣe fún un yín.

19Nígbà náà ní a gbé ra láti Horebu, bí OLÚWA Ọlọ́run wa ti pàṣẹ fún wá, a sì la àwọn ilẹ̀ lókè Ámórì kọjá lọ dé gbogbo aṣálẹ̀ ńlá tí ó ba ni lẹ́rù nì tí ẹ̀yin ti rí, bẹ́ẹ̀ ni a sì dé Kádésì Báníyà.

20Nígbà náà ni mo sọ fún un yín pé, “Ẹ ti dé ilẹ̀ òkè àwọn ará Ámórì, èyí tí OLÚWA Ọlọ́run wa fún wa.

21Ẹ kíyèsìí, OLÚWA Ọlọ́run yín ló ní ilẹ̀ náà. Ẹ lọ kí ẹ sì gba ilẹ̀ náà bí OLÚWA Ọlọ́run àwọn baba yín tí sọ fún un yín. Ẹ má bẹ̀rù, Ẹ má sì ṣe fòyà.”

22ⓒ Nígbà náà ni gbogbo yín tọ̀ mí wá wí pé, “Jẹ́ kí a yan àwọn ayọ́lẹ̀wò láti yọ́ ilẹ̀ náà wò fún wa, kí wọn sì fún wa ní ìròyìn àwọn ọ̀nà tí a ó gbà àti àwọn ìlú tí a ó bá pàdé.”

23Èrò náà sì dára lójú mi, torí èyí ni mo ṣe yan àwọn ènìyàn méjìlá nínú yín, ẹnìkan láti inú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan.

24Wọ́n sì gòkè lọ sí ilẹ̀ òkè náà, wọ́n sì wá sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ Ésíkónì, wọ́n sì yẹ̀ ẹ́ wò.

25Wọ́n sì mú lára èso ilẹ̀ náà wá fún wa pé, “Ilẹ̀ tí ó dára ni OLÚWA Ọlọ́run wa fún wa.”

26Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò fẹ́ gòkè lọ; ẹ ṣọ̀tẹ̀ sí àṣẹ OLÚWA Ọlọ́run yín.

27Ẹ kùn nínú àgọ́ ọ yín, ẹ sì wí pé, “OLÚWA kórìíra wa, torí èyí ló fi mú wa jáde láti Éjíbítì láti fi wá lé àwọn ará Ámórì lọ́wọ́ láti pa wá run.

28Níbo la ó lọ? Àwọn arákùnrin wa ti kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wa nípa sísọ pé, ‘Àwọn ènìyàn náà lágbára wọ́n sì ga jù wá lọ; àwọn ìlú náà tóbi jọjọ bẹ́ẹ̀ ni odi wọn ga kan ọ̀run. A tilẹ̀ rí àwọn òmìrán (Ará Ánákì) níbẹ̀.’ ”

29Nígbà náà ni mo sọ fún un yín pé, “Ẹ má ṣojo, ẹ kò sì gbọdọ̀ bẹ̀rù wọn.

30OLÚWA Ọlọ́run yín, tí ń ṣáájú yín yóò jà fún un yín; bí ó ti ṣe fún un yín ní Éjíbítì lójú ẹ̀yin tìkárayín

31ⓓ àti ní ihà. Níbẹ̀ ni ẹ ti rí i bí OLÚWA Ọlọ́run yín ti gbé yín, bí baba ti í gbé ọmọ rẹ̀, ní gbogbo ọ̀nà tí ẹ lọ títí ẹ fi padà dé ibí yìí.”

32Pẹ̀lú gbogbo èyí tí mo wí, ẹ kò gbẹ́kẹ̀lé OLÚWA Ọlọ́run yín,

33tí ń ṣáájú u yín lọ ní gbogbo ọ̀nà an yín, nípa fífi iná ṣe amọ̀nà an yín ní òru àti ìkùukù ní ọ̀sán, láti fi àwọn ibi tí ẹ lè tẹ̀dó sí hàn yín àti àwọn ọ̀nà tí ẹ ó rìn.

34Nígbà tí OLÚWA gbọ́ ohun tí ẹ sọ, inú bí i, ó sì búra wí pé:

35“Kò sí ọ̀kan nínú ìran búburú yìí tí yóò dé ilẹ̀ rere tí mo ti búra láti fún àwọn baba ńlá a yín.

36Bí kò ṣe Kálẹ́bù ọmọ Jéfúnì. Òun ni yóò wọ̀ ọ́. Èmi yóò sì fún òun àti àwọn ìran rẹ̀ ní ilẹ̀ náà tí ó ti fi ẹṣẹ̀ rẹ̀ tẹ̀; torí pé ó fi gbogbo ọkàn rẹ̀ tẹ̀lé OLÚWA.”

37Torí i ti yín ni OLÚWA fi bínú sí mi wí pé, “Ìwọ náà kì yóò wọ ibẹ̀ bákan náà,

38ṣùgbọ́n Jósúà ọmọ Núnì tí ń ṣe olùrànlọ́wọ́ rẹ ni yóò wọ ibẹ̀. Mú un, ní ọkàn le torí pé, òun yóò ṣáájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti gba ilẹ̀ náà.

39Àwọn èwe yín tí ẹ ṣọ pé wọn yóò kó lẹ́rú. Àwọn ọmọ yín tí ko tí ì mọ rere yàtọ̀ sí búburú ni yóò wọ ilẹ̀ náà.

40Ṣùgbọ́n ẹ̀yin, ẹ yí pada sí aṣálẹ̀ tí ó wà ní ọ̀nà tí ó lọ sí òkun pupa.”

41Nígbà náà ni ẹ fèsì wí pé, “Àwa ti ṣẹ̀ sí OLÚWA. A ó sì gòkè lọ láti jà, gẹ́gẹ́ bí OLÚWA Ọlọ́run wa ti pàṣẹ fún wa.” Torí náà gbogbo yín ẹ mú ohun ìjà a yín, ẹ rò pé ó rọrùn láti gòkè lọ sí àwọn orílẹ̀ èdè olókè náà.

42Ṣùgbọ́n OLÚWA sọ fún mi pé, “Sọ fún wọn, ‘Ẹ má se gòkè lọ láti jà torí pé èmi kì yóò wà pẹ̀lú u yín. Àwọn ọ̀ta a yín yóò sì sẹ́gun yín.’ ”

43Bẹ́ẹ̀ ni mo sọ fún un yín, ẹ kò sì gbọ́, ẹ sọ̀tẹ̀ sí òfin OLÚWA, pẹ̀lú ìgbéraga yín ẹ gòkè lọ sí ìlú olókè náà.

44Àwọn ará Ámórì tí ń gbé ní àwọn òkè náà, dojú kọ yín bí àgbájọpọ̀ oyin. Wọ́n sì lù yín bolẹ̀ látí Séírì títí dé Hómà.

45Ẹ padà, ẹ sì sunkún níwájú OLÚWA, òun kò sì fetí sí igbe ẹkún yín, Ó sì kọ etí dídi sí i yín.

46Báyìí ni ẹ sì dúró ní Kádésì fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin ti ṣe.

>