1Nígbà náà ni OLÚWA wí fún mi pé, “Gbé síléètì òkúta méjì bí i ti àkọ́kọ́ kí o sì gòkè tọ̀ mí wá. Kí o sì tún figi kan àpótí kan.
2Èmi yóò sì tún ọ̀rọ̀ tí ó wà lórí síléètì àkọ́kọ́ tí o fọ́ kọ sórí rẹ̀. Kí o sì fi wọ́n sínú àpótí náà.”
3Mo sì kan àpótí náà pẹ̀lú igi kaṣíà, mo sì gbẹ́ síléètì òkúta méjì náà jáde bí i ti ìṣáájú. Mo sì gòkè lọ pẹ̀lú síléètì méjèèjì lọ́wọ́ mí.
4OLÚWA tún ohun tí ó ti kọ tẹ́lẹ̀ kọ sórí síléétì wọ̀nyí. Àwọn òfin mẹ́wẹ̀ẹ̀wá tí ó ti sọ fún un yín lórí òkè, láàrin iná, ní ọjọ́ ìpéjọpọ̀. OLÚWA sì fi wọ́n fún mi.
5Mo sì sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè náà, mo sì ki àwọn síléètì òkúta náà sínú àpótí tí mo ti kàn, bí OLÚWA ti pàṣẹ fún mi, wọ́n sì wà níbẹ̀ di ìsinsin yìí.
6(Àwọn ará Ísírẹ́lì sì gbéra láti kàǹga àwọn ará a Jákánì dé Mósérà. Níbí ni Árónì kú sí, tí a sì sin ín, Élíásárì ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ bí i àlùfáà.
7Láti ibẹ̀ ni wọ́n ti rìn lọ sí Gúdígódà, títí dé Jótíbárà, ilẹ̀ tí o kún fún odò tí ó ń sàn.
8Ní ìgbà yí ni OLÚWA yan àwọn ọmọ Léfì láti máa ru àpótí májẹ̀mú OLÚWA, láti máa dúró níwájú OLÚWA láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́, àti láti fi orúkọ OLÚWA súre bí wọ́n ti ń ṣe títí di òní yìí.
9Ìdí nìyí tí àwọn ẹ̀yà Léfì kò fi ní ìpín tàbí ogún kan láàrin àwọn arákùnrin wọn. OLÚWA ni ogún wọn gẹ́gẹ́ bí OLÚWA Ọlọ́run ti sọ fún un yín.)
10Mo tún dúró ní orí òkè náà fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru, bí mo ti ṣe ní ìgbà àkọ́kọ́, OLÚWA sì gbọ́ tèmi ní àkókò yìí bákan náà. Kì í ṣe ìfẹ́ rẹ̀ láti run yín.
11OLÚWA sọ fún mi pé, “Lọ darí àwọn ènìyàn wọ̀nyí ní ọ̀nà wọn, kí wọn báà lè wọ ilẹ̀ náà, kí wọn sì gba ilẹ̀ tí mo ti búra fún àwọn baba wọn láti fún wọn.”
12Nísinsin yìí ìwọ Ísírẹ́lì, kín ni ohun tí OLÚWA Ọlọ́run rẹ béèrè lọ́wọ́ rẹ? Bí kò ṣe kí ìwọ bẹ̀rù OLÚWA Ọlọ́run rẹ àti láti máa rìn ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀, láti fẹ́ràn rẹ̀, láti fi gbogbo ọkàn rẹ sin OLÚWA Ọlọ́run rẹ ọkan àti àyà rẹ,
13àti láti máa kíyèsí àṣẹ àti ìlànà OLÚWA tí mo ń fún ọ lónìí, fún ire ara à rẹ.
14Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé OLÚWA Ọlọ́run yín ni ó ni ọ̀run àní àwọn ọ̀run tó ga ju ayé àti ohun gbogbo tí ó wà nínú rẹ̀.
15Ṣíbẹ̀ OLÚWA sì tún fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn fún àwọn baba ńlá a yín, Ó sì fẹ́ wọn Ó sì yan ẹ̀yin ọmọ wọn láti borí gbogbo orílẹ̀ èdè títí di òní.
16Ẹ kọ ọkàn yín ní ilà, (Ẹ wẹ ọkàn ẹ̀ṣẹ̀ yín mọ́) kí ẹ má sì se jẹ́ olóríkunkun mọ́ láti òní lọ.
17
18Ó máa ń gbẹjọ́ aláìní baba àti opó rò, Ó fẹ́ràn àlejò, Óun fi aṣọ àti oúnjẹ fún wọn.
19
20Ẹ bẹ̀rù OLÚWA Ọlọ́run yín, ẹ sì máa sìn ín. Ẹ dì í mú ṣinṣin, kí ẹ sì búra ní orúkọ rẹ̀.
21Òun ni ìyìn in yín, Òun sì ni Ọlọ́run yín, tí ó ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu ńlá àti ohun ẹ̀rù, tí ẹ fojú ara yín rí.
22