1
2
3
4Àwọn wọ̀nyí ni ẹranko tí ẹ lè máa jẹ: màlúù, àgùntàn àti ewúrẹ́,
5àgbọ̀nrín, èsúó, ẹtu, àgóró, ẹfọ̀n, ìgalà àti àgùntàn igbó
6Ẹ lè jẹ gbogbo ẹranko tí pátakò ẹṣẹ̀ rẹ̀ kì í se méjì tí ó sì tún jẹ àpọ̀jẹ.
7Ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀ nínú gbogbo ẹran tí ń jẹ àpọ̀jẹ tí ó sì tún ya pátakò ẹṣẹ̀ tí ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ni: ràkunmí, ehoro, àti ẹranko tí ó dàbí ehoro tí ń gbé inú àpáta. Bí ó tílẹ̀ jẹ́ pé wọ́n jẹ àpọ̀jẹ, ṣùgbọ́n wọn kò la pátakò, ẹṣẹ̀ a kà wọ́n sí àìmọ́ fún un yín.
8Ẹlẹ́dẹ̀ jẹ́ àìmọ́; bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ya pátakò ẹṣẹ̀, kì í jẹ àpọ̀jẹ, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹran rẹ̀, ẹ kò sì gbọdọ̀ fọwọ́ kan òkú rẹ̀.
9Nínú gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ń gbé inú omi, ẹ lè jẹ èyíkéyí tí ó ní lẹbẹ àti ìpẹ́.
10Ṣùgbọ́n èyíkéyí tí kò bá ní lẹbẹ àti ìpẹ́, ẹ má ṣe jẹ ẹ́, nítorí pé àìmọ́ ni wọ́n jẹ́ fún un yín.
11Ẹ lè jẹ ẹyẹ tí ó bá mọ́.
12Ṣùgbọ́n ìwọ̀nyí ní ẹ kò gbọdọ̀ jẹ: idì, igún, àkàlà,
13onírúurú àṣá àti àṣá alátagbà,
14onírúurú ẹyẹ ìwò,
15ògòǹgò, òyo, pẹ́pẹ́yẹdò àti onírúurú àwòdì,
16onírúurú òwìwí,
17òwìwí-ọ̀dàn, idì-okùn, ẹyẹ-àkọ̀,
18òòdẹ̀, onírúurú ẹyẹ odò mìíràn, atọ́ka àti àdán.
19Àti gbogbo kòkòrò tí ń fò tí wọ́n ń kọ́wọ̀ọ́ rín jẹ́ aláìmọ́ fun un yín, ẹ má ṣe jẹ wọ́n.
20Ṣùgbọ́n ẹ lè jẹ èyíkéyí ẹ̀dá abìyẹ́ tí ó bá mọ́.
21
22
23Ẹ jẹ ìdámẹ́wàá, oúnjẹ yín, wáìnì tuntun, òróró, àti àkọ́bí àwọn màlúù yín àti ewúrẹ́ ẹ yín, níwájú OLÚWA Ọlọ́run yín, ní ibi tí yóò yàn bí ibùgbé orúkọ rẹ̀. Kí ẹ lè kọ́ bí a ṣé ń bọlá fún OLÚWA Ọlọ́run yín nígbà gbogbo.
24Bí ibẹ̀ bá jìn tí OLÚWA Ọlọ́run rẹ sì ti bùkún fún ọ, tí o kò sì le ru àwọn ìdámẹ́wàá rẹ (nítorí pé ibi tí OLÚWA yóò yàn láti fi orúkọ rẹ̀ sí jìnnà jù).
25Ẹ pààrọ̀ àwọn ìdámẹ́wàá yín sówó, ẹ mú owó náà lọ sí ibi tí OLÚWA yóò yàn.
26Fi owó náà ra ohunkóhun tí o bá fẹ́, màlúù, àgùntàn, wáìnì, tàbí ọtí líle, tàbí ohunkóhun tí o bá fẹ́. Kí ìwọ àti ìdílé rẹ sì jẹ ẹ́ níwájú OLÚWA níbẹ̀ kí ẹ sì máa yọ̀.
27Ẹ má ṣe gbàgbé àwọn Léfì tí ó ń gbé nì ilú yín, nítorí pé wọn kò ní ìpín kan tàbí ogún kan tí í se tiwọn.
28Ní òpin ọdún mẹ́tamẹ́ta, ẹ mú gbogbo ìdámẹ́wàá irè oko àwọn ọdún náà, kí ẹ kó wọn jọ ní ìlú yín.
29Kí àwọn Léfì (tí kò ní ìpín tàbí ogún ti wọn) àti àwọn àlejò, àwọn aláìní baba, àti àwọn opó tí ń gbé ìlú yín lè wá, kí wọn sì jẹ kí wọn sì yó, kí OLÚWA Ọlọ́run rẹ leè bùkún fún ọ, nínú gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.