Ìwé Deutarónómì 19:1-21 BYB2014 - Bible AI

1ⓐ Nígbà tí OLÚWA Ọlọ́run rẹ bá ti pa àwọn orílẹ̀ èdè tí yóò fi ilẹ̀ wọn fún ọ run, àti nígbà tí ìwọ bá ti lé wọn jáde tí o sì dó sí àwọn ilẹ̀ àti ilé wọn gbogbo.

2Ìwọ yóò ya ìlú mẹ́ta sọ́tọ̀ fún ara à rẹ láàrin ilẹ̀ rẹ tí OLÚWA Ọlọ́run fún ọ láti ni.

3Ṣe àwọn ọ̀nà sí wọn àti kí o pín ilẹ̀ tí OLÚWA Ọlọ́run fún ọ gẹ́gẹ́ bí ogún sí ọ̀nà mẹ́ta nítorí kí apànìyàn lè sá níbẹ̀.

4Èyí ni òfin nípa ẹni tí ó pa ẹlòmíràn tí ó sì sá ṣíbẹ̀ láti pa ẹ̀mí rẹ̀ mọ́. Ẹni tí ó pa aládùúgbò láìmọ̀ọ́mọ̀ṣeé láì jẹ́ pé ó ti ní àrankàn pẹ̀lú u rẹ̀ láti ọjọ́ pípẹ́.

5Bí àpẹẹrẹ, ọkùnrin kan lè lọ sínú igbó pẹ̀lú aládùúgbò rẹ̀ láti gé igi, bí ó sì ti gbé àáké e rẹ̀ láti gé igi náà lulẹ̀, bí àáké náà bá yọ tí ó sì bà aládùúgbò rẹ̀, tí òun sì kú. Ọkùnrin yìí lè sálọ sí ọ̀kan nínú àwọn ìlú yìí láti gba ẹ̀mí rẹ̀ là.

6Bí kò ṣe bẹ́ẹ̀, agbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ lè máa lépa rẹ̀ nínú ìbínú, kí ó sì lée bá nítorí pé ọ̀nà jìn, kí ó sì paá bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò yẹ sí ikú, nígbà tí ó ṣeé sí aládùúgbò rẹ̀ láì jẹ́ pé ó ti ní àrankàn pẹ̀lú u rẹ̀ láti ọjọ́ pípẹ́.

7Ìdí nìyìí tí mo fi pa á láṣẹ fún ọ láti ya ìlú mẹ́ta sọ́tọ̀ fún ara rẹ.

8Tí OLÚWA Ọlọ́run rẹ bá sì fẹ́ agbègbè rẹ, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ìbúra fún àwọn baba ńlá a yín, tí ó sì fún ọ ní gbogbo ilẹ̀ tí ó ti ṣe ìlérí fún wọn,

9nítorí tí ìwọ fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ tẹ̀lé gbogbo òfin yìí tí mo pa láṣẹ fún ọ lónìí yìí, kí o fẹ́ OLÚWA Ọlọ́run rẹ, kí o sì rìn ní ọ̀nà an rẹ̀ ní gbogbo ìgbà náà, kí o ya ìlú mẹ́ta ṣọ́tọ̀.

10Ṣe èyí kí a má ṣe ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ ni ilẹ̀ rẹ, èyí tí OLÚWA Ọlọ́run rẹ yóò fún ọ gẹ́gẹ́ bí ogún, kí ìwọ kí ó má bàá jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ títa.

11Ṣùgbọ́n tí ọkùnrin kan bá kórìíra arákùnrin rẹ̀, tí ó sì lúgọ dè é, tí ó mú u tí o lù ú pa, tí ọkùnrin náà sì sálọ sí ọ̀kan nínú àwọn ìlú wọ̀nyí,

12àwọn olórí ìlú rẹ yóò sì ránṣẹ́ pè é ìwọ, yóò sì mú un padà láti ìlú náà, wọn yóò sì fi í lé àwọn agbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ lọ́wọ́ kí ó lè kú.

13Má ṣe ṣàánú fún un. O ní láti fọ ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ kúrò ni Isírẹ́lì, kí ó báà lè dára fún ọ.

14Má ṣe pa òkúta ààlà aládúgbò rẹ dà tí aṣíwájú rẹ fi lélẹ̀ nínú ogún tí ó gbà nínú ilẹ̀ tí OLÚWA Ọlọ́run rẹ fi fún ọ láti ni ní ìní.

15ⓑ Ẹlẹ́rìí kan ṣoṣo kò tó láti dájọ́ ọkùnrin kan tí o fi ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ yóò wù kí ó lè ṣẹ̀ lẹ́bi. A ó fi ìdí ọ̀rọ̀ múlẹ̀ láti orí ẹ̀rí ẹni méjì tàbí mẹ́ta.

16ⓒ Tí alárankàn ẹlẹ́rìí èké bá dúró láti fi ẹ̀ṣùn ẹ̀ṣẹ̀ kan ọkùnrin kan,

17àwọn méjèèjì tí àríyànjiyàn wà láàrin wọn gbọdọ̀ dúró níwájú OLÚWA níwájú àwọn àlùfáà àti àwọn adájọ́ tí ó wà ní ibi iṣẹ́ ní ìgbà náà.

18Àwọn adájọ́ gbọ́dọ̀ ṣe ìwádìí fínnífínní bí ẹ̀rí bá sì jẹ́ irọ́, tí ó fi ẹ̀rí èké sun arákùnrin rẹ̀,

19ⓓ nígbà náà ni kí ó ṣe sí i gẹ́gẹ́ bí ó ṣe fẹ́ ṣe sí arákùnrin rẹ̀. O ní láti wẹ búburú kúrò láàrin rẹ.

20Àwọn ènìyàn tókù yóò gbọ́ nípa èyí, wọn yóò sì bẹ̀rù, kí irú nǹkan búburú bẹ́ẹ̀ máa tún sẹ̀ mọ́ láàrin yín.

21ⓔ Má ṣe fi àánú hàn, ẹ̀mí fún ẹ̀mi, ojú fún ojú, eyín fún eyín, apá fún apá, ẹṣẹ̀ fún ẹṣẹ̀.

e>