1Nígbà tí o bá lọ sí ogun pẹ̀lú ọ̀ta rẹ, tí o sì rí ẹṣin àti àwọn kẹ̀kẹ́ ogun àti ológun tí ó jù ọ́ lọ, má ṣe bẹ̀rù u wọn, nítorí OLÚWA Ọlọ́run rẹ tí ń mú ọ jáde wá láti ilẹ̀ Éjíbítì, yóò wà pẹ̀lú rẹ.
2Nígbà tí o bá fẹ́ lọ jagun, àlùfáà yóò wá ṣíwájú, yóò sì bá ọmọ ogun sọ̀rọ̀,
3yóò sì wí pé, “Gbọ́, ìwọ Ísírẹ́lì, lónìí ò ń jáde lọ sójú ogun sí ọ̀ta rẹ. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọkàn yín ṣojo tàbí bẹ̀rù; ẹ má ṣe jáyà tàbí kí ẹ fi àyè fún ìjayà níwájú u wọn.
4Nítorí OLÚWA Ọlọ́run rẹ ni ẹni tí ó ń lọ pẹ̀lú rẹ láti jà fún ọ kí ó sì fún ọ ní ìṣẹgun.”
5Àwọn olórí ogun yóò sì wí fún àwọn ènìyàn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó kọ́ ilé túntún tí kò sì tì ì yà á sọ́tọ̀? Jẹ́ kí ó lọ ilé, tàbí ó lè kú ṣójú ogun kí elòmìíràn sì gbà á.
6Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni tí ó gbin ọgbà àjàrà kan tí kò sì tí ì bẹ̀rẹ̀ sí ń gbádùn rẹ̀? Jẹ́ kí ó lọ ilé, tàbí kí ó kú sójú ogun kí ẹlòmìíràn sì gbádùn rẹ̀.
7Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni tí ó wá ògo obìnrin kan tí kò ì tí ì fẹẹ? Jẹ́ kí ó lọ ilé, tàbí kí ó kú sójú ogun kí ẹlòmíràn sì fẹẹ́.”
8Nígbà náà ni olórí yóò tún fi kún un pé “Ǹjẹ́ ọkùnrin kankan ń bẹ̀rù tàbí páyà? Jẹ́ kí ó lọ ilé nítorí kí arákùnrin rẹ̀ má baà wá tún dáyà fò ó.”
9Nígbà tí olórí ogun bá ti dákẹ́ ọ̀rọ̀ sísọ sí àwọn ènìyàn, wọn yóò yan olórí ogun lórí i rẹ̀.
10Nígbà tí ó bá sún mọ́ iwájú láti dojú kọ ìlú kan láti bá a jà, nígbà náà ni kí ó fi àlàáfíà lọ̀ ọ́.
11Tí wọ́n bá gbà tí wọ́n sì sí ìlẹ̀kùn, gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀ yóò máa jẹ́ olùsìn fún ọ, wọn ó sì máa sìn ọ́.
12Tí wọ́n bá kọ̀ láti bá ọ ṣe àlàáfíà ṣùgbọ́n tí wọ́n bá gbógun tì ọ́, nígbà náà ni kí ìwọ gbà á.
13Nígbà tí OLÚWA Ọlọ́run rẹ bá fi lé ọ lọ́wọ́, ẹ pa gbogbo àwọn ọkùnrin tí ó wà níbẹ̀.
14Ní ti obìnrin, àwọn ọmọdé, ohun ọ̀sìn àti gbogbo ohun tí ó kù nínú ìlú náà, o lè mú ìwọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí ìkógún fún ara rẹ. O sì lè lo ìkógún tí OLÚWA Ọlọ́run rẹ fi fún ọ láti ọ̀dọ̀ àwọn ọ̀ta rẹ.
15Báyìí ni ìwọ yóò ṣe sí gbogbo ìlú tí wọ́n wà ní ọ̀nà jínjìn sí ọ tí wọn kò sì tara àwọn orílẹ̀ èdè tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹ̀ rẹ.
16Ṣùgbọ́n, nínú àwọn ìlú ti àwọn orílẹ̀ èdè tí OLÚWA Ọlọ́run rẹ ń fún ọ gẹ́gẹ́ bí ogún, má ṣe dá ohun ẹlẹ́mìí kankan sí.
17Pa wọ́n run pátapáta, àwọn ọmọ Hítì, ọmọ Ámórì, ọmọ Kénánì, ọmọ Pérísì, ọmọ Hífì, ọmọ Jébúsì gẹ́gẹ́ bí OLÚWA Ọlọ́run rẹ ti pa á láṣẹ fún ọ.
18Bí kò ṣe bẹ́ẹ̀, wọn yóò kọ́ ọ láti tẹ̀lé gbogbo ohun ìríra tí wọ́n ń ṣe nínú sísin àwọn ọlọ́run wọn, ìwọ yóò sì sẹ̀ sí OLÚWA Ọlọ́run rẹ.
19Nígbà tí o bá dóti ìlú kan láti ọjọ́ pípẹ́, ẹ bá wọn jà láti gbà á, má ṣe pa àwọn igi ibẹ̀ run nípa gbígbé àáké lé wọn, nítorí o lè jẹ èso wọn. Má se gé wọn lulẹ̀. Nítorí igi ìgbẹ́ ha á ṣe ènìyàn bí, tí ìwọ ó máa dọ̀tí rẹ̀.
20Ṣùgbọ́n o lè gé àwọn igi tí o mọ̀ pé wọn kì í ṣe igi eléṣo lulẹ̀ kí o sì lò wọ́n láti kọ́ ìṣọ́ sí ìlú tí ó ń bá ọ jagun, títí tí yóò fi ṣubú.