Ìwé Deutarónómì 21:1-23 BYB2014 - Bible AI

1Tí a bá rí ọkùnrin tí a pa, ní ìdùbúlẹ̀ ní pápá nínú ilẹ̀ tí OLÚWA Ọlọ́run rẹ ń fún ọ láti jogún, tí a kò sì mọ ẹni tí ó pa á,

2àwọn àgbààgbà yín yóò jáde lọ láti wọn jíjìnnà ibi òkú sí ìlú tí ó wà nítòòsí.

3Nígbà náà ni àwọn àgbààgbà ìlú tí ó wà nítòòsí òkú yóò mú ẹgbọ̀rọ̀ abo màlúù tí kò ì siṣẹ́ àti tí kò ì tíì fà sí àmì ìsìn ẹrú,

4kí wọn sìn ín wá sí àfonífojì tí a kò ì tíì ro tàbí gbìn àti ibi tí odò ṣíṣàn wà. Níbẹ̀ ní àfonífojì wọn yóò kán ọrùn ẹgbọ̀rọ̀ màlúù.

5Àwọn àlùfáà, ọmọ Léfì yóò wá ṣíwájú, nítorí OLÚWA Ọlọ́run rẹ ti yàn wọ́n láti ṣe ìránṣẹ́ fún un àti láti bùkún ní orúkọ OLÚWA àti láti parí gbogbo ẹjọ́ àríyànjiyàn àti ọ̀rọ̀ ìlú.

6Nígbà náà ni gbogbo àwọn àgbààgbà ìlú tí ó wà nítòsí yóò wẹ ọwọ́ wọn lórí ẹgbọrọ abo màlúù tí a ti kan ọrùn rẹ̀ ní àfonífojì,

7wọn yóò sì sọ pé, “ọwọ́ wa kò ta ẹ̀jẹ̀ yìí sílẹ̀, tàbí kí ojú wa rí i ní títa sílẹ̀.”

8Dáríjìn, OLÚWA, àwọn ènìyàn rẹ ni Ísírẹ́lì, tí ìwọ ti dá sílẹ̀, àti kí ìwọ má ṣe gba ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ aláìsẹ̀ ní àárin àwọn ènìyàn rẹ ní Ísírẹ́lì. Ṣùgbọ́n kí a dárí ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ yìí jìn.

9Nígbà náà ni ìwọ wẹ̀ kúró láàrin rẹ ẹ̀bi títa ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀, níwọ̀n ìgbà tí o ti ṣe èyí tí ó tọ́ níwájú OLÚWA.

10Nígbà tí o bá lọ sí ogun sí àwọn ọ̀ta rẹ tí OLÚWA Ọlọ́run rẹ sì fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́ tí o sì mú àwọn ìgbékùn,

11tí o sì rí obìnrin tí ó dára lára àwọn ìgbékùn, tí o sì ní ìfẹ́ síi, o lè mu u gẹ́gẹ́ bí aya à rẹ.

12Mú u wá sí ilé e rẹ kí o sì jẹ́ kí ó fá irun orí i rẹ̀, gé èékánná an rẹ̀,

13kí o sì mú aṣọ tí ó wọ̀ nígbà tí ó di ìgbékùn sí ẹ̀gbẹ́ kan. Lẹ́yìn ìgbà tí ó ti ń gbé ilé rẹ tí ó sì ti sọ̀fọ̀ baba àti ìyá rẹ̀ fún odidi osù kan, nígbà náà ni o lè tọ̀ ọ́ lọ kí o sì ṣe ọkọ rẹ̀ kí ó jẹ́ aya rẹ.

14Bí inú rẹ̀ kò bá sì dùn si i, jẹ́ kí ó lọ sí ibikíbi tí ó bá fẹ́. O kò gbọdọ̀ tà á tàbí lò ó bí ẹrú, lẹ́yìn ìgbà tí o ti dójú tì í.

15Bí ọkùnrin kan bá ní ìyàwó méjì, tí ó sì fẹ́ ọ̀kan ṣùgbọ́n tí kò fẹ́ èkejì, tí àwọn méjèèjì sì bí àwọn ọmọkùnrin fún un ṣùgbọ́n tí àkọ́bí jẹ́ ọmọ ìyàwó rẹ̀ tí kò fẹ́ràn.

16Nígbà tí ó bá ń pín ohun ìní rẹ̀ fún àwọn ọmọ rẹ̀, kò gbọdọ̀ fi ẹ̀tọ́ àkọ́bí fún ọmọ ìyàwó tí kò fẹ́ràn.

17Ó ní láti fi ipò ọmọ ìyàwó rẹ̀ tí kò fẹ́ràn fun un gẹ́gẹ́ bí àkọ́bí i rẹ̀ nípa fífún un ní ìlọ́po ìpín gbogbo ohun tí ó ní. Ọmọ yẹn ni àmì àkọ́kọ́ agbára baba rẹ̀. Ẹ̀tọ́ àkọ́bí jẹ́ tirẹ̀.

18ⓐ Bí ọkùnrin kan bá ní aláìgbọ́ràn tàbí ọlọ̀tẹ̀ ọmọ tí kò gbọ́rọ̀ sí baba àti ìyá rẹ̀ tí kò sì ní í gbà tí wọ́n bá ń bá a wí,

19baba àti ìyá rẹ̀ yóò gbá a mú, wọn yóò mu wá fún àwọn àgbààgbà ní ẹnu bodè ìlú u rẹ̀.

20Wọn yóò sì wí fún àwọn àgbààgbà pé, “Ọmọ wa yìí jẹ́ aláìgbọ́ràn àti ọlọ̀tẹ̀. Kò ní gbọ́rọ̀ sí wa. Ó jẹ́ oníwà búburú àti ọ̀mùtí-para.”

21Nígbà náà ni gbogbo ọkùnrin ìlú rẹ̀ yóò sọ ọ́ ní òkúta pa. Ìwọ yóò sì mú ìwà ibi kúrò láàrin yín, gbogbo Ísírẹ́lì yóò gbọ́ ẹ̀rù yóò sì bà wọ́n.

22ⓑ Bí ọkùnrin kan tí ó jẹ̀bi ẹ̀sùn bá ní láti kú tí ó sì kú, tí a sì gbé òkú rẹ̀ kọ́ sára igi,

23ⓒ o kò gbọdọ̀ fi òkú rẹ̀ sílẹ̀ sára igi ní gbogbo òru. Gbìyànjú láti sin ín ní ọjọ́ náà gan an, nítorí ẹni tí a bá gbékọ́ sórí igi wà lábẹ́ ègún Ọlọ́run. O kò gbọdọ̀ ba ilẹ̀ tí OLÚWA Ọlọ́run rẹ fún ọ gẹ́gẹ́ bí ogún jẹ́.

e>